Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dáníẹ́lì 5:1-31

5  Ní ti Bẹliṣásárì+ Ọba, ó se àsè ńlá kan fún ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, ó sì ń mu wáìnì+ ní iwájú àwọn ẹgbẹ̀rún náà.  Bẹliṣásárì tí wáìnì ń pa,+ sọ pé kí wọ́n mú àwọn ohun èlò wúrà àti ti fàdákà+ tí Nebukadinésárì baba rẹ̀ kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù wá, kí ọba àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, àwọn wáhàrì rẹ̀ àti àwọn aya rẹ̀ onípò kejì lè fi wọ́n mutí.+  Ní àkókò yẹn, wọ́n mú àwọn ohun èlò wúrà tí wọ́n ti kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì ilé Ọlọ́run tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù wá, ìwọ̀nyí sì ni ọba àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, àwọn wáhàrì rẹ̀ àti àwọn aya rẹ̀ onípò kejì fi mutí.  Wọ́n mu wáìnì, wọ́n sì yin àwọn ọlọ́run wúrà àti ti fàdákà, bàbà, irin, igi àti òkúta.+  Ní ìṣẹ́jú yẹn, àwọn ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé ní iwájú ọ̀pá fìtílà sára ibi tí a rẹ́ lára ògiri ààfin ọba,+ ọba sì rí ẹ̀yìn ọwọ́ tí ó ń kọ̀wé.  Ní àkókò yẹn, ní ti ọba, àwọ̀ ara rẹ̀ yí padà, ìrònú òun fúnra rẹ̀ sì kó jìnnìjìnnì bá a,+ àwọn oríkèé ìgbáròkó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí yẹ̀,+ àwọn eékún rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá ara wọn.+  Ọba sì ń ké kíkankíkan pé kí wọ́n mú àwọn alálùpàyídà, àwọn ará Kálídíà àti àwọn awòràwọ̀ wá.+ Ọba dáhùn, ó sì wí fún àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì pé: “Ènìyàn èyíkéyìí tí ó bá ka ìkọ̀wé yìí, tí ó sì fi ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an hàn mí, a ó fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́,+ a ó sì fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà yí ọrùn rẹ̀ ká, yóò sì ṣàkóso bí igbá-kẹta nínú ìjọba.”+  Ní àkókò yẹn, gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn lọ́dọ̀ ọba wọlé wá, ṣùgbọ́n wọn kò kúnjú ìwọ̀n láti ka ìkọ̀wé náà tàbí láti sọ ìtumọ̀ rẹ̀ di mímọ̀ fún ọba.+  Nítorí náà, jìnnìjìnnì bá Ọba Bẹliṣásárì gidigidi, àwọ̀ ara rẹ̀ sì yí padà nínú rẹ̀; ọkàn àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn sì dà rú.+ 10  Ní ti ayaba, nítorí ọ̀rọ̀ ọba àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, ó wọ inú gbọ̀ngàn àkànṣe àsè lọ. Ayaba sì dáhùn pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Má ṣe jẹ́ kí ìrònú rẹ kó jìnnìjìnnì bá ọ, má sì jẹ́ kí àwọ̀ ara rẹ yí padà. 11  Ọkùnrin kan tí ó dáńgájíá wà nínú ìjọba rẹ nínú ẹni tí ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà;+ ní ọjọ́ baba rẹ, a rí ìtànmọ́lẹ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n bí ọgbọ́n àwọn ọlọ́run nínú rẹ̀, Ọba Nebukadinésárì, baba rẹ sì fi í ṣe olórí+ àwọn àlùfáà pidánpidán, àwọn alálùpàyídà, àwọn ará Kálídíà àti àwọn awòràwọ̀, àní baba rẹ, ìwọ ọba; 12  níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹ̀mí àrà ọ̀tọ̀ àti ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye láti túmọ̀ àwọn àlá+ àti àlàyé àwọn àlọ́ àti títú àwọn ìdè títakókó ni a ti rí nínú rẹ̀,+ nínú Dáníẹ́lì, ẹni tí ọba fúnra rẹ̀ pè ní Bẹlitéṣásárì.+ Wàyí o, jẹ́ kí a pe Dáníẹ́lì, kí ó lè fi ìtumọ̀ náà gan-an hàn.” 13  Nítorí náà, wọn mú Dáníẹ́lì wá síwájú ọba. Ọba sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Ìwọ ha ni Dáníẹ́lì, tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìgbèkùn Júdà,+ tí baba mi ọba mú wá láti Júdà?+ 14  Mo ti gbọ́ nípa rẹ pẹ̀lú pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run wà nínú rẹ,+ a sì ti rí ìtànmọ́lẹ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n+ àrà ọ̀tọ̀ nínú rẹ. 15  Wàyí o, a ti mú àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn alálùpàyídà wá síwájú mi, kí wọ́n lè ka ìkọ̀wé yìí, àní láti sọ ìtumọ̀ rẹ̀ di mímọ̀ fún mi; ṣùgbọ́n wọn kò kúnjú ìwọ̀n láti fi ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà+ gan-an hàn. 16  Èmi fúnra mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, pé o lè ṣe ìtumọ̀,+ kí o sì tú àwọn ìdè títakókó. Wàyí o, bí o bá lè ka ìkọ̀wé náà, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an di mímọ̀ fún mi, a ó fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, a ó sì fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà yí ọrùn rẹ ká, ìwọ yóò sì ṣàkóso bí igbá-kẹta nínú ìjọba.”+ 17  Ní àkókò yẹn, Dáníẹ́lì dáhùn, ó sì sọ níwájú ọba pé: “Kí ẹ̀bùn rẹ jẹ́ tìrẹ, sì fi ọrẹ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn.+ Àmọ́ ṣá o, èmi yóò ka ìkọ̀wé náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ náà di mímọ̀ fún un.+ 18  Ní tìrẹ, ọba, Ọlọ́run Gíga Jù Lọ+ fún Nebukadinésárì baba rẹ+ ní ìjọba àti ìtóbi àti iyì àti ọlá ọba.+ 19  Àti nítorí ìtóbi tí Ó fún un, gbogbo ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè ń wárìrì, wọ́n sì ń fi ìbẹ̀rù hàn níwájú rẹ̀.+ Ẹni tí ó bá fẹ́, ni ó ń pa; ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń kọlù; ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń gbé ga; ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń tẹ́ lógo.+ 20  Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera, tí ẹ̀mí rẹ̀ sì le, kí ó lè gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ìkùgbù,+ a rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ láti orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, a sì gba iyì rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 21  A sì lé e lọ kúrò láàárín àwọn ọmọ aráyé, a sì ṣe ọkàn-àyà rẹ̀ bí ti ẹranko, ibùgbé rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́.+ Wọ́n fún un ní ewéko jẹ gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ìrì ọ̀run sì rin ín,+ títí ó fi mọ̀ pé Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń gbé ka orí rẹ̀.+ 22  “Ní tìrẹ, Bẹliṣásárì ọmọkùnrin rẹ̀,+ ìwọ kò rẹ ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ gbogbo èyí.+ 23  Ṣùgbọ́n o gbé ara rẹ ga sí Olúwa ọ̀run,+ wọ́n sì mú ohun èlò ilé rẹ̀ pàápàá wá síwájú rẹ;+ ìwọ fúnra rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ jàǹkàn-jàǹkàn, àwọn wáhàrì rẹ àti àwọn aya rẹ onípò kejì sì ti ń fi wọ́n mu wáìnì, o sì ti yin àwọn ọlọ́run lásán-làsàn tí ó jẹ́ ti fàdákà àti ti wúrà, bàbà, irin, igi àti òkúta,+ tí kò rí nǹkan kan tàbí gbọ́ nǹkan kan tàbí mọ nǹkan kan;+ ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí èémí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀,+ àti ẹni tí gbogbo ọ̀nà rẹ jẹ́ tirẹ̀+ ni ìwọ kò fi ògo fún.+ 24  Nítorí náà, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a ti rán ẹ̀yìn ọwọ́ kan, ìkọ̀wé yìí gan-an ni a sì kọ.+ 25  Ìkọ̀wé tí a sì kọ nìyí: MÉNÈ, MÉNÈ, TÉKÉLÍ, PÁRÁSÍNÌ. 26  “Èyí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà: MÉNÈ, Ọlọ́run ti ka iye ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀.+ 27  “TÉKÉLÌ, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò kájú ìwọ̀n.+ 28  “PÉRÉSÌ, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mídíà àti Pá ṣíà.”+ 29  Ní àkókò yẹn, Bẹliṣásárì pàṣẹ, wọ́n sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ Dáníẹ́lì, wọ́n sì fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà yí ọrùn rẹ̀ ká; wọ́n sì kéde ní gbangba nípa rẹ̀ pé yóò di igbá-kẹta olùṣàkóso nínú ìjọba.+ 30  Ní òru ọjọ́ yẹn gan-an, a pa Bẹliṣásárì, ọba àwọn ará Kálídíà,+ 31  Dáríúsì+ ará Mídíà sì gba ìjọba, ó jẹ́ ẹni nǹkan bí ọdún méjì-lé-lọ́gọ́ta.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé