Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dáníẹ́lì 4:1-37

4  “Nebukadinésárì Ọba, sí gbogbo ènìyàn, àwùjọ orílẹ̀-èdè àti èdè tí ń gbé ní gbogbo ilẹ̀ ayé:+ Kí àlàáfíà yín di púpọ̀.+  Ó dára lójú mi láti polongo àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ ti ṣe fún mi.+  Ẹ wo bí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ ti tóbi lọ́lá tó, ẹ sì wo bí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ ti jẹ́ alágbára ńlá tó!+ Ìjọba rẹ̀ jẹ́ ìjọba tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ agbára ìṣàkóso rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+  “Ó ṣẹlẹ̀ pé, èmi Nebukadinésárì, wà ní ìdẹ̀rùn+ nínú ilé mi tí mo sì ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú ààfin mi.+  Mo lá àlá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú mi fòyà.+ Àwọn àwòrán èrò orí sì ń bẹ lórí ibùsùn mi àti àwọn ìran orí mi tí ó bẹ̀rẹ̀ sí kó jìnnìjìnnì bá mi.+  Láti ọ̀dọ̀ mi sì ni àṣẹ ìtọ́ni kan ti jáde lọ láti mú gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì wá síwájú mi, kí wọ́n lè sọ ìtumọ̀ àlá náà gan-an di mímọ̀ fún mi.+  “Ní àkókò yẹn, àwọn àlùfáà pidánpidán, àwọn alálùpàyídà, àwọn ará Kálídíà,+ àti àwọn awòràwọ̀+ wọlé; mo sì sọ ohun tí àlá náà jẹ́ níwájú wọn, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ di mímọ̀ fún mi.+  Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹlitéṣásárì+ gẹ́gẹ́ bí orúkọ ọlọ́run mi,+ ẹni tí ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́+ sì wà nínú rẹ̀; wọlé wá síwájú mi, níwájú rẹ̀ ni mo sì rọ́ àlá náà:  “‘Bẹlitéṣásárì, olórí àwọn àlùfáà pidánpidán,+ nítorí èmi alára mọ̀ dáadáa pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ+ àti pé kò sí àṣírí kankan rárá tí ń dà ọ́ láàmú,+ sọ ìran àlá mi tí mo rí fún mi àti ìtumọ̀ rẹ̀.+ 10  “‘Wàyí o, ìran orí mi lórí ibùsùn mi ni ó ṣẹlẹ̀ pé mo rí,+ sì wò ó! igi kan+ wà ní àárín ilẹ̀ ayé, tí gíga rẹ̀ jẹ́ arabarìbì.+ 11  Igi náà dàgbà, ó sì di alágbára, níkẹyìn gíga rẹ̀ dé ọ̀run, a sì lè rí i ní ìkángun gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 12  Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé rí gbẹ̀gẹ́gbẹ̀gẹ́, èso rẹ̀ sì pọ̀ yanturu, oúnjẹ sì wà fún gbogbo gbòò lórí rẹ̀. Lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko+ inú pápá ti ń wá ibòji,+ àti lórí ẹ̀tun rẹ̀ ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ń gbé,+ láti ara rẹ̀ sì ni olúkúlùkù ẹran ara ti ń bọ́ ara rẹ̀. 13  “‘Mo sì rí ní ìran orí mi lórí ibùsùn mi, sì wò ó! olùṣọ́ kan,+ àní ẹni mímọ́ kan,+ ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run gan-an. 14  Ó ń ké kíkankíkan, ohun tí ó sì ń sọ nìyí: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀,+ kí ẹ sì ké ẹ̀tun rẹ̀ kúrò. Ẹ gbọn àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé dànù, kí ẹ sì tú èso rẹ̀ ká. Kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, àti àwọn ẹyẹ kúrò lórí àwọn ẹ̀tun rẹ̀.+ 15  Àmọ́ ṣá o, ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀, àní tòun ti ọ̀já irin àti bàbà, láàárín koríko pápá; sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run rin ín, kí ìpín rẹ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko láàárín ewéko ilẹ̀ ayé.+ 16  Kí a yí ọkàn-àyà rẹ̀ padà kúrò ní ti aráyé, kí a sì fi ọkàn-àyà ẹranko fún un,+ kí ìgbà méje+ sì kọjá lórí rẹ̀. 17  Nípa àṣẹ àgbékalẹ̀ àwọn olùṣọ́+ ni ohun náà, nípa àsọjáde àwọn ẹni mímọ́ sì ni ìbéèrè náà, fún ète pé kí àwọn ènìyàn tí ó wà láàyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé,+ ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń fi í fún,+ ó sì ń gbé àní ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé+ ka orí rẹ̀.” 18  “‘Èyí ni àlá tí èmi fúnra mi, Nebukadinésárì Ọba lá; ìwọ fúnra rẹ Bẹlitéṣásárì, sọ ohun tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́, níwọ̀n bí gbogbo àwọn yòókù tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú ìjọba mi kò ti lè sọ ìtumọ̀ náà+ gan-an di mímọ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ kúnjú ìwọ̀n, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ ń bẹ nínú rẹ.’+ 19  “Ní àkókò yẹn, fún ìṣẹ́jú kan, ẹnu ya Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹlitéṣásárì,+ ìrònú òun fúnra rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí kó jìnnìjìnnì bá a.+ “Ọba dáhùn, pé, ‘Bẹlitéṣásárì, má ṣe jẹ́ kí àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ kó jìnnìjìnnì bá ọ.’+ “Bẹlitéṣásárì dáhùn pé, ‘Olúwa mi, kí àlá náà ṣẹ sí àwọn tí ó kórìíra rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ fún àwọn elénìní rẹ.+ 20  “‘Igi tí o rí, tí ó di ńlá tí ó sì di alágbára, tí gíga rẹ̀ dé ọ̀run níkẹyìn, tí a sì lè rí ní gbogbo ilẹ̀ ayé,+ 21  tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé rí gbẹ̀gẹ́gbẹ̀gẹ́, tí èso rẹ̀ pọ̀ yanturu, tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo gbòò lórí rẹ̀; lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko inú pápá ń gbé, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé lórí àwọn ẹ̀tun rẹ̀,+ 22  ìwọ ni, ọba,+ nítorí pé o ti di ẹni ńlá, o sì ti di alágbára, ìtóbilọ́lá rẹ ti di ńlá, ó sì ti dé ọ̀run,+ agbára ìṣàkóso rẹ sì ti dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.+ 23  “‘Àti nítorí pé ọba rí olùṣọ́ kan, àní ẹni mímọ́ kan,+ tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, tí ó sì wí pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀, kí ẹ sì run ún. Àmọ́ ṣá o, ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀, ṣùgbọ́n tòun ti ọ̀já irin àti ti bàbà, láàárín koríko pápá, sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run rin ín, sì jẹ́ kí ìpín rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí rẹ̀,”+ 24  ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí, ọba, àṣẹ àgbékalẹ̀+ Ẹni Gíga Jù Lọ+ sì ni èyí tí yóò ṣẹlẹ̀ sí olúwa mi ọba.+ 25  Ìwọ ni wọn yóò sì lé lọ kúrò láàárín àwọn ènìyàn, ibùgbé rẹ yóò sì wá wà pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá,+ ewéko ni wọn yóò sì fún ọ jẹ gan-an bí akọ màlúù;+ ìrì ọ̀run yóò sì máa rin ọ́, ìgbà méje+ yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé,+ ẹni tí ó bá sì fẹ́ ni ó ń fi í fún.+ 26  “‘Àti nítorí tí wọ́n sọ pé kí wọ́n fi gbòǹgbò ìdí igi náà sílẹ̀,+ ó dájú pé ìjọba rẹ yóò jẹ́ tìrẹ lẹ́yìn tí o bá ti mọ̀ pé ọ̀run ni ń ṣàkóso.+ 27  Nítorí náà, ọba, kí ìmọ̀ràn mi dára lójú rẹ,+ kí o sì mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò nípa òdodo,+ kí o sì mú àìṣẹ̀tọ́ rẹ kúrò nípa fífi àánú hàn sí àwọn òtòṣì.+ Bóyá a óò mú aásìkí rẹ gùn sí i.’”+ 28  Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì Ọba.+ 29  Ní òpin oṣù òṣùpá méjìlá, ó ṣẹlẹ̀ pé ó ń rìn lórí ààfin ọba Bábílónì. 30  Ọba dáhùn pé:+ “Bábílónì Ńlá kọ́ yìí, tí èmi fúnra mi fi okun agbára ńlá+ mi kọ́ fún ilé ọba àti fún iyì ọlá ọba tí ó jẹ́ tèmi?”+ 31  Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ṣì wà lẹ́nu ọba, ohùn kan wá láti ọ̀run pé: “Nebukadinésárì Ọba, ìwọ ni a sọ fún pé, ‘Ìjọba náà gan-an ti lọ kúrò lọ́wọ́ rẹ,+ 32  àní ìwọ ni wọn yóò lé kúrò láàárín àwọn ènìyàn, ibùgbé rẹ yóò sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá.+ Ewéko ni wọn yóò fún ọ jẹ gan-an bí akọ màlúù, ìgbà méje pàápàá yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́ ni ó ń fi í fún.’”+ 33  Ní ìṣẹ́jú yẹn,+ ọ̀rọ̀ náà gan-an ní ìmúṣẹ sí Nebukadinésárì lára, a sì lé e kúrò láàárín aráyé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ewéko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ìrì ọ̀run sì rin ara rẹ̀, títí irun rẹ̀ fi gùn bí ti ìyẹ́ idì àti èékánná rẹ̀ bí èékánná ẹyẹ.+ 34  “Ní òpin àwọn ọjọ́ náà,+ èmi Nebukadinésárì gbé ojú mi sókè ọ̀run,+ òye mi sì bẹ̀rẹ̀ sí padà sínú mi; mo sì fi ìbùkún fún Ẹni Gíga Jù Lọ fúnra rẹ̀,+ mo sì fi ìyìn àti ògo fún Ẹni tí ó wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ nítorí pé agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso fún àkókò tí ó lọ kánrin, ìjọba rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+ 35  Gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé kò sì jámọ́ nǹkan kan,+ ó sì ń ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ láàárín ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.+ Kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dá a lọ́wọ́ dúró+ tàbí tí ó lè sọ fún un pé, ‘Kí ni o ti ń ṣe?’+ 36  “Ní àkókò náà gan-an, òye mi bẹ̀rẹ̀ sí padà sínú mi,+ àti ní ti iyì ìjọba mi, ọlá ọba mi àti ìtànyòò mi, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí padà sára mi; àní àwọn olóyè mi onípò gíga àti àwọn ènìyàn mi jàǹkàn-jàǹkàn bẹ̀rẹ̀ sí fi ìháragàgà wá mi káàkiri, a sì fìdí mi múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i sórí ìjọba mi, a sì fi ìtóbi àrà ọ̀tọ̀ kún un fún mi.+ 37  “Nísinsìnyí, èmi Nebukadinésárì ń yin Ọba ọ̀run,+ mo ń gbé e ga, mo sì ń fi ògo fún un, nítorí òtítọ́ ni gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ìdájọ́ òdodo sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ àti nítorí pé gbogbo àwọn tí ń rìn nínú ìgbéraga ni òun lè tẹ́ lógo.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé