Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dáníẹ́lì 2:1-49

2  Àti ní ọdún kejì ìgbà àkóso Nebukadinésárì, Nebukadinésárì lá àwọn àlá;+ ṣìbáṣìbo+ sì bá ẹ̀mí rẹ̀, oorun rẹ̀ sì di èyí tí ó fò lọ.  Nítorí èyí, ọba sọ pé kí wọ́n pe àwọn àlùfáà+ pidánpidán àti àwọn alálùpàyídà àti àwọn oníṣẹ́ oṣó àti àwọn ará Kálídíà láti rọ́ àwọn àlá+ ọba fún un. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wọlé, wọ́n sì dúró níwájú ọba.  Nígbà náà ni ọba wí fún wọn pé: “Mo lá àlá kan, ṣìbáṣìbo sì bá ẹ̀mí mi láti mọ àlá náà.”  Látàrí ìyẹn, àwọn ará Kálídíà bá ọba sọ̀rọ̀ ní èdè+ Árámáíkì pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Rọ́ àlá náà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwa yóò sì fi ìtumọ̀+ rẹ̀ gan-an hàn.”  Ọba dáhùn, ó sì wí fún àwọn ará Kálídíà pé: “Mo ń ṣe ìkéde ọ̀rọ̀ náà pé: Bí ẹ kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ di mímọ̀ fún mi, a óò gé yín sí wẹ́wẹ́,+ a ó sì sọ ilé yín di+ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ gbogbo ènìyàn.  Ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ hàn, ẹ̀bùn àti ọrẹ àti iyì púpọ̀ ni ẹ ó gbà lọ́dọ̀ mi.+ Nítorí náà, ẹ fi àlá náà gan-an àti ìtumọ̀ rẹ̀ hàn mí.”  Wọ́n dáhùn ní ìgbà kejì, pé: “Kí ọba rọ́ àlá náà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì fi ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an hàn.”  Ọba dáhùn, pé: “Ní ti tòótọ́, mo mọ̀ pé àkókò ni ẹ ń gbìyànjú láti jèrè, níwọ̀n bí ẹ ti róye pé mo ń ṣe ìkéde ọ̀rọ̀ náà.  Nítorí bí ẹ kò bá sọ àlá náà gan-an di mímọ̀ fún mi, àní ìdájọ́+ kan ṣoṣo yìí wà lórí yín. Ṣùgbọ́n irọ́ àti ọ̀rọ̀ àìtọ́ ni ẹ ti fohùn ṣọ̀kan láti sọ níwájú mi,+ títí di ìgbà tí àkókò náà yóò fi yí padà. Nítorí náà, ẹ rọ́ àlá náà gan-an fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè fi ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an hàn.” 10  Àwọn ará Kálídíà dáhùn níwájú ọba, wọ́n sì wí pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ń gbé lórí ilẹ̀ gbígbẹ tí ó lè fi ọ̀ràn ọba hàn án, níwọ̀n bí kò ti sí ọba títóbi lọ́lá, tàbí gómìnà kankan tí ó tíì béèrè ohun bí èyí lọ́wọ́ àlùfáà pidánpidán, tàbí alálùpàyídà, tàbí ará Kálídíà èyíkéyìí. 11  Ṣùgbọ́n ohun tí ọba ń béèrè ṣòro, kò sì sí ẹnì kan tí ń bẹ láàyè tí ó lè fi í hàn níwájú ọba, bí kò ṣe àwọn ọlọ́run,+ tí ibùgbé wọn kò sí pẹ̀lú ẹlẹ́ran ara rárá.”+ 12  Nítorí èyí, ọba bínú, inú rẹ̀ sì ru gidigidi,+ ó sì sọ pé kí wọ́n pa gbogbo ọlọ́gbọ́n Bábílónì+ run. 13  Àṣẹ ìtọ́ni náà sì jáde lọ, a sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn ọlọ́gbọ́n náà; wọ́n sì wá Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, láti pa wọ́n. 14  Ní àkókò yẹn, Dáníẹ́lì ní tirẹ̀, fi ìmọ̀ràn àti òye inú+ bá Áríókù, olórí ẹ̀ṣọ́ ọba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó ti jáde lọ láti pa àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì. 15  Ó dáhùn, ó sì wí fún Áríókù onípò àṣẹ lọ́dọ̀ ọba pé: “Fún ìdí wo ni ọba fi pa irú àṣẹ ìtọ́ni lílekoko bẹ́ẹ̀?” Ìgbà náà ni Áríókù sọ ọ̀ràn náà di mímọ̀ fún Dáníẹ́lì.+ 16  Bẹ́ẹ̀ ni Dáníẹ́lì wọlé, ó sì béèrè pé kí ọba fún òun ní àkókò kan ní pàtó láti fi ìtumọ̀ náà gan-an han ọba.+ 17  Lẹ́yìn ìyẹn, Dáníẹ́lì lọ sí ilé tirẹ̀; ó sì sọ ọ̀ràn náà di mímọ̀ fún Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, 18  àní kí wọ́n lè béèrè fún àánú+ lọ́wọ́ Ọlọ́run ọ̀run+ nípa àṣírí yìí,+ kí wọ́n má bàa pa Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ run pẹ̀lú ìyókù àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì.+ 19  Ìgbà náà ni a ṣí àṣírí náà payá+ fún Dáníẹ́lì nínú ìran òru. Nítorí náà, Dáníẹ́lì fi ìbùkún fún+ Ọlọ́run ọ̀run. 20  Dáníẹ́lì dáhùn, pé: “Kí a fi ìbùkún fún+ orúkọ Ọlọ́run láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí ọgbọ́n àti agbára ńlá—wọ́n jẹ́ tirẹ̀.+ 21  Ó sì ń yí ìgbà àti àsìkò+ padà, ó ń mú àwọn ọba kúrò, ó sì ń fi àwọn ọba+ jẹ, ó ń fi ọgbọ́n fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó mọ ìfòyemọ̀.+ 22  Ó ń ṣí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ àti àwọn ohun tí ó pa mọ́ payá,+ ó mọ ohun tí ó wà nínú òkùnkùn;+ ìmọ́lẹ̀+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 23  Ìwọ, Ọlọ́run àwọn baba ńlá mi, ni mo ń fi ìyìn fún tí mo sì ń gbóríyìn fún,+ nítorí o fi ọgbọ́n+ àti agbára ńlá fún mi. Wàyí o, o ti sọ ohun tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ di mímọ̀ fún mi, nítorí o ti sọ ọ̀ràn ọba+ di mímọ̀ fún wa.” 24  Nítorí èyí, Dáníẹ́lì wọlé lọ bá Áríókù,+ ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì+ run. Ó lọ, ohun tí ó sì sọ fún un nìyí: “Má ṣe pa ọlọ́gbọ́n Bábílónì kankan run. Mú mi wọlé lọ síwájú ọba,+ kí èmi lè fi ìtumọ̀ náà han ọba.” 25  Ìgbà náà ni Áríókù, ní kánjúkánjú, mú Dáníẹ́lì wọlé síwájú ọba, ohun tí ó sì wí fún un nìyí: “Mo ti rí abarapá ọkùnrin kan lára àwọn ìgbèkùn+ Júdà tí ó lè sọ ìtumọ̀ náà di mímọ̀ fún ọba.” 26  Ọba dáhùn, ó sì sọ fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹlitéṣásárì+ pé: “O ha kúnjú ìwọ̀n láti sọ àlá tí mo rí di mímọ̀ fún mi, àti ìtumọ̀ rẹ̀?”+ 27  Dáníẹ́lì dáhùn níwájú ọba, ó sì wí pé: “Àṣírí tí ọba ń béèrè, ni àwọn ọlọ́gbọ́n, àwọn alálùpàyídà, àwọn àlùfáà pidánpidán àti àwọn awòràwọ̀ pàápàá kò lè fi han ọba.+ 28  Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá,+ ó sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́+ di mímọ̀ fún Ọba Nebukadinésárì. Àlá rẹ àti ìran orí rẹ lórí ibùsùn+ rẹ—òun nìyí: 29  “Ní tìrẹ, ọba, ìrònú rẹ jẹ yọ lórí ibùsùn rẹ ní ti ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí, Ẹni tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ di mímọ̀ fún ọ.+ 30  Ní ti èmi, kì í ṣe nípasẹ̀ ọgbọ́n èyíkéyìí tí ó wà nínú mi tí ó ju ti inú àwọn mìíràn tí ó wà láàyè lọ ni a fi ṣí àṣírí yìí payá fún mi,+ bí kò ṣe pẹ̀lú ète pé kí a lè sọ ìtumọ̀ náà di mímọ̀ fún ọba kí o sì lè mọ ìrònú ọkàn-àyà rẹ.+ 31  “Ìwọ ọba, ó ṣẹlẹ̀ pé o rí i, sì kíyè sí i! ère arabarìbì kan. Ère yẹn, tí ó tóbi, tí ìtànyòò rẹ̀ sì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, dúró ní iwájú rẹ, ìrísí rẹ̀ sì múni kún fún ìbẹ̀rùbojo. 32  Ní ti ère yẹn, orí rẹ̀ jẹ́ wúrà+ dáradára, igẹ̀ àti apá rẹ̀ jẹ́ fàdákà,+ ikùn àti itan rẹ̀ sì jẹ́ bàbà,+ 33  ojúgun rẹ̀ jẹ́ irin,+ ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin, apá kan amọ̀ tí a ṣù.+ 34  Ìwọ wò ó títí a fi gé òkúta kan jáde tí kì í ṣe nípasẹ̀ ọwọ́,+ ó sì kọlu ère náà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ irin àti amọ̀ tí a ṣù, ó sì fọ́ wọn túútúú.+ 35  Ní àkókò yẹn, irin, amọ̀ tí a ṣù, bàbà, fàdákà àti wúrà, lápapọ̀, ni a fọ́ túútúú bí ìyàngbò láti ilẹ̀ ìpakà ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,+ ẹ̀fúùfù sì gbé wọn lọ tí ó fi jẹ́ pé a kò rí ipasẹ̀ wọn rárá.+ Àti ní ti òkúta tí ó kọlu ère náà, ó di òkè ńlá tí ó tóbi, ó sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 36  “Èyí ni àlá náà, a ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ níwájú ọba.+ 37  Ìwọ ọba, ọba àwọn ọba, ìwọ ẹni tí Ọlọ́run ọ̀run ti fún ní ìjọba,+ agbára ńlá, okun àti iyì, 38  tí ó sì fi àwọn ẹranko inú pápá àti àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá ojú ọ̀run lé lọ́wọ́,+ tí ó sì ti fi ṣe olùṣàkóso lórí gbogbo wọn ní ibikíbi tí ọmọ aráyé ń gbé, ìwọ alára ni orí wúrà náà.+ 39  “Lẹ́yìn rẹ, ìjọba mìíràn yóò dìde,+ èyí tí ó rẹlẹ̀ sí ọ;+ àti ìjọba mìíràn, ẹ̀kẹta, tí ó jẹ́ ti bàbà, tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.+ 40  “Ní ti ìjọba kẹrin,+ yóò le bí irin.+ Nítorí bí irin ti ń fọ́ ohun gbogbo mìíràn túútúú tí ó sì ń lọ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ ni, bí irin tí ń rún nǹkan wómúwómú, yóò fọ́ àní gbogbo ìwọ̀nyí túútúú, yóò sì rún wọn wómúwómú.+ 41  “Níwọ̀n bí ìwọ sì ti rí ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ apá kan amọ̀ tí a ṣù ti amọ̀kòkò àti apá kan irin,+ ìjọba náà yóò pínyà,+ ṣùgbọ́n ohun kan bí líle ti irin yóò wà nínú rẹ̀, níwọ̀n bí ìwọ ti rí irin tí ó dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírin.+ 42  Ní ti ọmọ ìka ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀ tí a ṣù, ìjọba náà yóò ní agbára lápá kan, yóò sì jẹ́ èyí tí ó gbẹgẹ́ lápá kan. 43  Níwọ̀n bí ìwọ ti rí irin tí ó dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírin, wọn yóò wá dà pọ̀ mọ́ ọmọ aráyé; ṣùgbọ́n wọn kì yóò lẹ̀ mọ́ra, èyí pẹ̀lú ìyẹn, gan-an gẹ́gẹ́ bí irin kò ti lè dà pọ̀ mọ́ amọ̀ tí a ṣù. 44  “Àti pé ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn,+ Ọlọ́run ọ̀run+ yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀+ èyí tí a kì yóò run láé.+ Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn.+ Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn,+ òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ 45  níwọ̀n bí ìwọ sì ti rí i tí òkúta kan gé kúrò lára òkè ńlá náà tí kì í ṣe nípasẹ̀ ọwọ́,+ tí ó sì fọ́ irin, bàbà, amọ̀ tí a ṣù, fàdákà àti wúrà+ túútúú. Ọlọ́run Atóbilọ́lá+ fúnra rẹ̀ ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí+ di mímọ̀ fún ọba. Àlá náà ṣeé fọkàn tẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.”+ 46  Ní àkókò yẹn, Nebukadinésárì Ọba dojú bolẹ̀, ó sì júbà Dáníẹ́lì, ó sì sọ pé kí wọ́n fún un ní ẹ̀bùn, kí wọ́n sì sun tùràrí fún un+ pàápàá. 47  Ọba dá Dáníẹ́lì lóhùn, pé: “Lóòótọ́, Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn ọba,+ ó sì jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá, nítorí pé ìwọ lè ṣí àṣírí yìí payá.”+ 48  Nítorí náà, ọba sọ Dáníẹ́lì di ẹni ńlá,+ ó sì fún un ní ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn ńláǹlà, ó sì fi í ṣe olùṣàkóso lórí gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì+ àti olórí pátápátá lórí gbogbo ọlọ́gbọ́n Bábílónì. 49  Dáníẹ́lì, ní tirẹ̀, béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò+ sípò lórí iṣẹ́ àbójútó ti àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì, ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì wà ní ààfin+ ọba.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé