Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dáníẹ́lì 12:1-13

12  “Àti ní àkókò yẹn, Máíkẹ́lì+ yóò dìde dúró, ọmọ aládé ńlá+ tí ó dúró+ nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn rẹ.+ Dájúdájú, akókò wàhálà yóò wáyé irú èyí tí a kò tíì mú kí ó wáyé rí láti ìgbà tí orílẹ̀-èdè ti wà títí di àkókò yẹn.+ Àti ní àkókò yẹn, àwọn ènìyàn rẹ yóò sá àsálà,+ olúkúlùkù ẹni tí a rí tí a kọ sílẹ̀ nínú ìwé náà.+  Ọ̀pọ̀ yóò sì wà nínú àwọn tí ó sùn nínú ekuru ilẹ̀ tí yóò jí dìde,+ àwọn wọ̀nyí sí ìyè tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ àti àwọn wọ̀nyẹn sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  “Àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò sì máa tàn bí ìtànyòò òfuurufú;+ àwọn tí wọ́n sì ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo+ yóò máa tàn bí ìràwọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.  “Àti ní ti ìwọ, Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà,+ títí di àkókò òpin.+ Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.”+  Mo sì wò, èmi Dáníẹ́lì, sì kíyè sí i! àwọn méjì mìíràn dúró,+ ọ̀kan ní ìhín bèbè ìṣàn omi, èkejì ní ọ̀hún bèbè ìṣàn omi.+  Nígbà náà ni ọ̀kan sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ tí ó wà lórí ìṣàn omi pé: “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó kí a tó dé òpin àwọn ohun àgbàyanu yìí?”+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ti ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ẹni tí ó wà lórí ìṣàn omi, bí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀ sókè ọ̀run, tí ó sì fi Ẹni tí ó wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin+ búra+ pé: “Yóò jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti ààbọ̀.+ Àti ní kété tí fífọ́ agbára àwọn ènìyàn mímọ́ túútúú+ bá ti parí, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wá sí òpin.”  Wàyí o, ní tèmi, mo gbọ́, ṣùgbọ́n èmi kò lóye;+ bẹ́ẹ̀ ni mo wí pé: “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ apá ìgbẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí?”+  Ó sì ń bá a lọ wí pé: “Máa lọ, Dáníẹ́lì, nítorí pé a ṣe ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, a sì fi èdìdì dì í títí di àkókò òpin.+ 10  Ọ̀pọ̀ yóò wẹ ara wọn mọ́,+ wọn yóò sì sọ ara wọn di funfun,+ a ó sì yọ́ wọn mọ́.+ Dájúdájú, àwọn ẹni burúkú yóò máa gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà burúkú,+ àwọn ẹni burúkú kankan kì yóò sì lóye;+ ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò lóye.+ 11  “Àti láti ìgbà tí a ti mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo+ kúrò,+ tí a sì ti gbé ohun ìríra+ tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro kalẹ̀, yóò jẹ́ àádọ́rùn-ún lé ní ẹgbẹ̀fà ọjọ́. 12  “Aláyọ̀+ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà, tí ó sì dé ẹ̀ẹ́dégbèje ọjọ́ ó lé márùndínlógójì! 13  “Ní ti ìwọ fúnra rẹ, máa lọ síhà òpin;+ ìwọ yóò sì sinmi,+ ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé