Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dáníẹ́lì 10:1-21

10  Ní ọdún kẹta Kírúsì,+ ọba Páṣíà, ọ̀ràn kan wà tí a ṣí payá fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹlitéṣásárì;+ òótọ́ sì ni ọ̀ràn náà, iṣẹ́ ìsìn ológun ńláǹlà+ sì wà. Ó sì lóye ọ̀ràn náà, ó sì ní òye ohun tí ó rí.+  Ní ọjọ́ wọnnì, ó ṣẹlẹ̀ pé èmi fúnra mi, Dáníẹ́lì, ń ṣọ̀fọ̀+ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko.  Èmi kò jẹ oúnjẹ aládìídùn, ẹran tàbí wáìnì kò sì wọ ẹnu mi, lọ́nàkọnà èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko fi pé.+  Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kìíní, ó ṣẹlẹ̀ pé èmi fúnra mi wà ní bèbè odò ńlá náà, èyíinì ni Hídẹ́kẹ́lì,+  mo sì ń bá a lọ láti gbé ojú mi sókè pẹ̀lú, mo sì rí, sì kíyè sí i, ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ ó sì fi wúrà Úfásì+ di ìgbáròkó rẹ̀+ ní àmùrè.  Ara rẹ̀ sì dà bí kírísóláítì,+ ojú rẹ̀ dà bí ìrísí mànàmáná,+ ẹyinjú rẹ̀ dà bí ògùṣọ̀ oníná,+ apá rẹ̀ àti ibi ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ojú bàbà tí a ha dán,+ ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí ìró ogunlọ́gọ̀.  Mo sì rí ìrísí náà, èmi Dáníẹ́lì ní èmi nìkan; ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi, wọn kò rí ìrísí náà.+ Bí ó ti wù kí ó rí, ìwárìrì ńláǹlà bò wọ́n, tí wọ́n fi fẹsẹ̀ fẹ láti fi ara wọn pa mọ́.  Èmi—èmi nìkan ni ó sì ṣẹ́ kù, tí mo fi rí ìrísí títóbi yìí. Agbára kankan kò sì ṣẹ́ kù sínú mi, iyì mi sì yí padà nínú mi di èyí tí ó bàjẹ́, èmi kò sì ní agbára mọ́.+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀; bí mo sì ti ń gbọ́ ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì ṣẹlẹ̀ pé èmi fúnra mi sùn lọ fọnfọn+ ní ìdojúbolẹ̀,+ tí mo dojú kọ ilẹ̀. 10  Sì wò ó! ọwọ́ kan kàn mí,+ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ru mí sókè láti dìde dúró lórí eékún mi àti àtẹ́lẹwọ́ mi. 11  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi,+ ní òye ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ fún ọ,+ sì dìde dúró níbi tí o ti dúró sí tẹ́lẹ̀, nítorí a ti rán mi sí ọ nísinsìnyí.” Nígbà tí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún mi, mo dìde dúró, mo ń gbọ̀n. 12  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Má fòyà,+ ìwọ Dáníẹ́lì, nítorí láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí o ti fi ọkàn-àyà rẹ fún òye,+ tí o sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ,+ a ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, èmi fúnra mi sì ti wá nítorí ọ̀rọ̀ rẹ.+ 13  Ṣùgbọ́n ọmọ aládé+ ilẹ̀ ọba Páṣíà+ dúró ní ìlòdìsí+ mi fún ọjọ́ mọ́kànlélógún, sì wò ó! Máíkẹ́lì,+ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá,+ wá láti ràn mí lọ́wọ́; ní tèmi, mo wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọba Páṣíà.+ 14  Mo sì ti wá láti mú kí o fi òye mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ+ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,+ nítorí ó jẹ́ ìran+ kan fún àwọn ọjọ́ tí ó ṣì ń bọ̀.”+ 15  Wàyí o, nígbà tí ó sọ irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún mi, mo gbé ojú mi sí ilẹ̀+ mo sì di aláìlèsọ̀rọ̀. 16  Sì wò ó! ẹnì kan tí ìrí rẹ̀ dà bí ti ọmọ aráyé fọwọ́ kan ètè mi,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí la ẹnu mi, mo sì sọ̀rọ̀,+ mo sì sọ fún ẹni tí ó dúró ní iwájú mi pé: “Olúwa mi,+ nítorí ìrísí náà, ìsúnkì iṣan mú mi, èmi kò sì ní agbára kankan.+ 17  Nítorí náà, báwo ni ìránṣẹ́ olúwa mi yìí ṣe lè bá olúwa mi yìí sọ̀rọ̀?+ Ní tèmi, títí di ìsinsìnyí, kò sí agbára kankan nínú mi, kò sì sí èémí kankan tí ó ṣẹ́ kù sínú mi.”+ 18  Ẹnì náà tí ó ní ìrísí ará ayé sì bẹ̀rẹ̀ sí tún fọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi lókun.+ 19  Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Má fòyà,+ ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.+ Kí o ní àlàáfíà.+ Jẹ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ alágbára.”+ Kété tí ó sì bá mi sọ̀rọ̀, mo sa okun mi, níkẹyìn mo wí pé: “Kí olúwa mi sọ̀rọ̀,+ nítorí ìwọ ti fún mi lókun.”+ 20  Nítorí náà, ó ń bá a lọ pé: “O ha mọ ìdí tí mo fi wá sọ́dọ̀ rẹ bí? Nísinsìnyí, èmi yóò padà lọ bá ọmọ aládé Páṣíà jà.+ Nígbà tí mo bá jáde lọ, wò ó! ọmọ aládé ilẹ̀ Gíríìsì yóò wá pẹ̀lú.+ 21  Bí ó ti wù kí ó rí, èmi yóò sọ àwọn nǹkan tí a ti kọ sínú ìwé òtítọ́+ fún ọ, kò sì sí ẹni tí ó tì mí lẹ́yìn gbágbáágbá nínú nǹkan wọ̀nyí bí kò ṣe Máíkẹ́lì,+ ọmọ aládé yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé