Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 9:1-21

9  Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣókùnkùn bàìbàì náà kì yóò rí bí ìgbà tí ilẹ̀ náà ní másùnmáwo, bí ti ìgbà àtijọ́ nígbà tí ènìyàn fojú tín-ín-rín ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì,+ tí ènìyàn sì wá mú kí a bọlá fún un+ ní ẹ̀yìn ìgbà náà—ọ̀nà òkun, ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.+  Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá.+ Ní ti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ibú òjìji,+ àní ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.+  Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè náà di púpọ̀ sí i;+ o ti sọ ayọ̀ yíyọ̀ di púpọ̀ fún un.+ Wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí a ti ń yọ̀ ní àkókò ìkórè,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó kún fún ìdùnnú nígbà tí wọ́n ń pín ohun ìfiṣèjẹ.+  Nítorí àjàgà ẹrù wọn+ àti ọ̀pá tí ó wà ní èjìká wọn, ọ̀gọ ẹni tí ń kó wọn ṣiṣẹ́,+ ni ìwọ ti ṣẹ́ sí wẹ́wẹ́ bí ti ọjọ́ Mídíánì.+  Nítorí gbogbo bàtà abokókósẹ̀ ti ẹni tí ń fi ìmìjìgìjìgì fẹsẹ̀ kilẹ̀+ àti aṣọ àlàbora tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀ ti wá wà fún sísun gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún iná.+  Nítorí a ti bí ọmọ kan fún wa,+ a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa;+ ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.+ Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára Ńlá,+ Baba Ayérayé,+ Ọmọ Aládé Àlàáfíà.+  Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé+ àti àlàáfíà kì yóò lópin,+ lórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in+ àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo+ àti nípasẹ̀ òdodo,+ láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.+  Ọ̀rọ̀ kan wà tí Jèhófà fi ránṣẹ́ sí Jékọ́bù, ó sì bọ́ sórí Ísírẹ́lì.+  Àwọn ènìyàn náà yóò sì mọ̀ ọ́n dájúdájú,+ àní gbogbo wọn, Éfúráímù àti olùgbé Samáríà,+ nítorí ìrera wọn àti nítorí àfojúdi ọkàn-àyà wọn ní wíwí pé:+ 10  “Bíríkì ni ó ṣubú, ṣùgbọ́n òkúta gbígbẹ́+ ni a ó fi kọ́ ọ. Igi síkámórè+ ni a gé lulẹ̀, ṣùgbọ́n kédárì ni a ó fi ṣe àfirọ́pò rẹ̀.” 11  Jèhófà yóò sì gbé àwọn elénìní Résínì dìde sókè sí i, àwọn ọ̀tá ẹni yẹn sì ni òun yóò gún ní kẹ́sẹ́,+ 12  Síríà láti ìlà-oòrùn+ àti àwọn Filísínì láti ẹ̀yìn,+ wọn yóò sì fi gbogbo ẹnu jẹ Ísírẹ́lì tán.+ Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.+ 13  Àwọn ènìyàn náà kò tíì padà sọ́dọ̀ Ẹni tí ń lù wọ́n,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni wọn kò sì tíì wá.+ 14  Jèhófà yóò sì ké orí+ àti ìrù,+ ọ̀mùnú àti koríko etídò kúrò ní Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+ 15  Àgbàlagbà àti ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi ni orí,+ wòlíì tí ń fúnni ní ìtọ́ni èké sì ni ìrù.+ 16  Àwọn tí ń ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn yìí sì ni àwọn tí ń mú wọn rìn gbéregbère;+ àwọn tí a sì ń ṣamọ̀nà lára wọn, àwọn ni a ń kó ìdàrúdàpọ̀ bá.+ 17  Ìdí nìyẹn tí Jèhófà kì yóò fi yọ̀ lórí àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn pàápàá,+ kì yóò sì ṣàánú fún àwọn ọmọdékùnrin wọn aláìníbaba àti fún àwọn opó wọn; nítorí pé gbogbo wọ́n jẹ́ apẹ̀yìndà+ àti aṣebi, olúkúlùkù ẹnu sì ń sọ ọ̀rọ̀ òpònú. Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.+ 18  Nítorí pé ìwà burúkú ti di ajólala gẹ́gẹ́ bí iná;+ yóò jẹ àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò run.+ Yóò sì gbiná nínú àwọn ìgbòrò igbó,+ a ó sì gbé wọn lọ sókè gẹ́gẹ́ bí ìrútùù èéfín.+ 19  A ti sọ iná sí ilẹ̀ náà nínú ìbínú kíkan Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àwọn ènìyàn náà yóò sì dà bí oúnjẹ fún iná náà.+ Ẹnì kankan kì yóò fi ìyọ́nú hàn sí arákùnrin rẹ̀ pàápàá.+ 20  Ẹnì kan yóò sì ṣe kíkélulẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún, ebi yóò sì máa pa á dájúdájú; ẹnì kan yóò sì jẹun ní ọwọ́ òsì, dájúdájú, wọn kì yóò yó.+ Olúkúlùkù wọn yóò sì jẹ ẹran ara apá tirẹ̀,+ 21  Mánásè yóò jẹ ti Éfúráímù, Éfúráímù yóò sì jẹ ti Mánásè. Wọn yóò para pọ̀ gbéjà ko Júdà.+ Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé