Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 8:1-22

8  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún mi pé: “Mú wàláà+ ńlá kan fún ara rẹ, kí o sì fi kálàmù ẹni kíkú kọ ‘Maheri-ṣalali-háṣí-básì’ sára rẹ̀.  Sì jẹ́ kí n ní ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀+ fún ara mi nípasẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́,+ Ùráyà àlùfáà+ àti Sekaráyà ọmọkùnrin Jeberekáyà.”  Nígbà náà ni mo sún mọ́ wòlíì obìnrin náà, ó sì wá lóyún, nígbà tí ó ṣe, ó bí ọmọkùnrin kan.+ Jèhófà sọ fún mi wàyí pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maheri-ṣalali-háṣí-básì,  nítorí pé kí ọmọdékùnrin náà tó mọ bí a ti ń pe,+ ‘Baba mi!’ àti ‘Ìyá mi!’ ẹnì kan yóò kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ Damásíkù àti ohun ìfiṣèjẹ Samáríà lọ níwájú ọba Ásíríà.”+  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá mi sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:  “Nítorí ìdí náà pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ+ omi Ṣílóà+ tí ó rọra ń ṣàn jẹ́ẹ́, tí ayọ̀ ńláǹlà+ sì wà nítorí Résínì àti ọmọkùnrin Remaláyà;+  àní nítorí náà, wò ó! Jèhófà yóò gbé omi tí ó ní agbára ńlá tí ó sì pọ̀, tí ó jẹ́ ti Odò+ náà dìde sí wọn,+ èyíinì ni ọba Ásíríà+ àti gbogbo ògo rẹ̀.+ Dájúdájú, òun yóò sì gòkè wá sórí gbogbo ojú ìṣàn omi rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,  yóò sì la Júdà já. Ní ti tòótọ́, òun yóò kún bò ó.+ Yóò kan ọrùn.+ Ìnàjáde ìyẹ́ apá+ rẹ̀ yóò sì ṣẹlẹ̀ láti lè kún ìbú ilẹ̀ rẹ, ìwọ Ìmánúẹ́lì!”+  Ẹ jẹ́ aṣeniléṣe, ẹ̀yin ènìyàn, kí a sì fọ́ yín túútúú; ẹ sì fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní àwọn apá ibi jíjìnnà ilẹ̀ ayé!+ Ẹ di ara yín lámùrè,+ kí a sì fọ́ yín túútúú!+ Ẹ di ara yín lámùrè, kí a sì fọ́ yín túútúú! 10  Ẹ wéwèé ìpètepèrò, a ó sì fọ́ ọ túútúú!+ Ẹ sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, kì yóò sì dúró, nítorí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!+ 11  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà fi líle ọwọ́ sọ fún mi, kí ó lè mú mi yà kúrò nínú rírìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn yìí, ó wí pé: 12  “Ẹ kò gbọ́dọ̀ sọ pé, ‘Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun!’ ní ti gbogbo èyí tí àwọn ènìyàn yìí ń sọ pé, ‘Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun!’+ àti pé ẹ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù ohun ẹ̀rù wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ wárìrì nítorí rẹ̀.+ 13  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—òun ni Ẹni tí ó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́,+ òun sì ni ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ẹ̀rù yín,+ òun sì ni Ẹni tí ó yẹ kí ó máa mú yín wárìrì.”+ 14  Òun yóò sì dà bí ibi ọlọ́wọ̀;+ ṣùgbọ́n bí òkúta tí a kọlù àti àpáta tí a kọsẹ̀ lára rẹ̀+ sí àwọn ilé Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí pańpẹ́ àti gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn sí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.+ 15  Ó sì dájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú, a ó sì ṣẹ́ wọn, a ó sì dẹkùn mú wọn.+ 16  Wíwé ni kí o wé ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀,+ fi èdìdì di òfin yí ká láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi!+ 17  Ṣe ni èmi yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún Jèhófà,+ ẹni tí ń fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún ilé Jékọ́bù,+ èmi yóò sì ní ìrètí nínú rẹ̀.+ 18  Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ tí Jèhófà ti fi fún mi+ dà bí àmì+ àti bí iṣẹ́ ìyanu ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ẹni tí ń gbé ní Òkè Ńlá Síónì.+ 19  Bí ó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n sọ fún yín pé: “Ẹ béèrè fún nǹkan lọ́wọ́ àwọn abẹ́mìílò+ tàbí lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ẹ̀mí ìsàsọtẹ́lẹ̀, àwọn tí ń ké ṣíoṣío,+ tí wọ́n sì ń sọ àwọn àsọjáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,” kì í ha ṣe ọwọ́ Ọlọ́run rẹ̀ ni ó yẹ kí ènìyàn ti máa béèrè fún nǹkan?+ [Ó ha yẹ kí ìbéèrè fún nǹkan] lọ́wọ́ àwọn òkú nítorí àwọn alààyè [ṣẹlẹ̀] bí?+ 20  Sí òfin àti sí ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀!+ Dájúdájú, wọn yóò máa sọ gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn yìí+ tí kì yóò ní ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀.+ 21  Dájúdájú, olúkúlùkù yóò gba ilẹ̀ náà kọjá nínú ìnilára dé góńgó àti nínú ebi;+ yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí tí ebi ń pa á, tí ó sì ti mú kí ìkannú rẹ̀ ru, ní ti tòótọ́ òun yóò pe ibi wá sórí ọba rẹ̀ àti sórí Ọlọ́run rẹ̀,+ yóò sì gbójú sókè dájúdájú. 22  Yóò sì wo ilẹ̀, sá wò ó! wàhálà àti òkùnkùn,+ ìríran bàìbàì, àwọn àkókò ìnira àti ìṣúdùdù láìsí ìtànyòò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé