Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 7:1-25

7  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Áhásì+ ọmọkùnrin Jótámù ọmọkùnrin Ùsáyà, ọba Júdà, pé Résínì+ ọba Síríà àti Pékà+ ọmọkùnrin Remaláyà, ọba Ísírẹ́lì, gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù láti bá a jagun, kò sì lè bá a jagun.+  A sì ròyìn fún ilé Dáfídì, pé: “Síríà ti gbára lé Éfúráímù.”+ Ọkàn-àyà rẹ̀ àti ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, bí ìgbọ̀npẹ̀pẹ̀ àwọn igi igbó nítorí ẹ̀fúùfù.+  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Aísáyà pé: “Jọ̀wọ́, jáde lọ pàdé Áhásì, ìwọ àti Ṣeari-jáṣúbù+ ọmọkùnrin rẹ, ní ìpẹ̀kun ọ̀nà omi+ adágún òkè, lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpópó pápá alágbàfọ̀.+  Kí o sì sọ fún un pé, ‘Ṣọ́ ara rẹ, kí o má sì yọ ara rẹ lẹ́nu.+ Má fòyà, má sì jẹ́ kí ojora mú ọkàn-àyà rẹ+ nítorí ibi orí méjèèjì ti àwọn ìtì igi wọ̀nyí tí ń rú èéfín, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Síríà àti ọmọkùnrin Remaláyà,+  nítorí ìdí náà pé Síríà pẹ̀lú Éfúráímù àti ọmọkùnrin Remaláyà ti pète ohun tí ó burú sí ọ, pé:  “Ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ bá Júdà kí a sì ya á sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kí a sì gbà á fún ara wa nípasẹ̀ ìyawọlé; kí a sì fi ọba mìíràn jẹ nínú rẹ̀, ọmọkùnrin Tábéélì.”+  “‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kì yóò dúró, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣẹ.+  Nítorí pé orí Síríà ni Damásíkù, orí Damásíkù sì ni Résínì; àti pé ní kìkì ọdún márùn-dín-láàádọ́rin, Éfúráímù ni a óò fọ́ túútúú kí ó má bàa jẹ́ àwọn ènìyàn kan.+  Orí Éfúráímù sì ni Samáríà,+ orí Samáríà sì ni ọmọkùnrin Remaláyà.+ Àyàfi bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kì yóò wà pẹ́.”’”+ 10  Jèhófà sì ń bá Áhásì sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé: 11  “Béèrè àmì kan lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ara rẹ,+ ní mímú kí ó jìn bí Ṣìọ́ọ̀lù tàbí mímú kí ó ga bí àwọn ẹkùn ilẹ̀ ìhà òkè.” 12  Ṣùgbọ́n Áhásì sọ pé: “Èmi kì yóò béèrè, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dán Jèhófà wò.” 13  Ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀ ìwọ ilé Dáfídì. Ohun kékeré bẹ́ẹ̀ ha ni fún yín láti kó àárẹ̀ bá àwọn ènìyàn, kí ẹ tún kó àárẹ̀ bá Ọlọ́run mi?+ 14  Nítorí náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò fún yín ní àmì kan: Wò ó! Omidan+ náà yóò lóyún+ ní tòótọ́, yóò sì bí ọmọkùnrin kan,+ dájúdájú, yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì. 15  Bọ́tà àti oyin ni yóò máa jẹ nígbà tí ó bá fi máa mọ bí a ti ń kọ ohun búburú sílẹ̀, tí a sì ń yan ohun rere.+ 16  Nítorí kí ọmọdékùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ohun búburú sílẹ̀, tí a sì ń yan ohun rere,+ ilẹ̀ ọba méjèèjì tí ìwọ ní ìbẹ̀rùbojo amúniṣàìsàn fún ni a ó fi sílẹ̀ pátápátá.+ 17  Jèhófà yóò mú wá sórí ìwọ+ àti sórí àwọn ènìyàn rẹ àti sórí ilé baba rẹ irúfẹ́ àwọn ọjọ́ tí kò tíì sí láti ọjọ́ tí Éfúráímù ti yí padà kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ Júdà,+ èyíinì ni, ọba Ásíríà.+ 18  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò súfèé sí àwọn eṣinṣin tí ó wà ní ìkángun àwọn ipa odò Náílì ti Íjíbítì àti sí àwọn oyin+ tí ó wà ní ilẹ̀ Ásíríà,+ 19  dájúdájú, wọn yóò wọlé wá, wọn yóò sì bà, gbogbo wọn, sí àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní bèbè ọ̀gbun àti sí pàlàpálá àwọn àpáta gàǹgà àti sórí gbogbo ìgbòrò ẹlẹ́gùn-ún àti sórí gbogbo ibi olómi.+ 20  “Ní ọjọ́ yẹn, nípasẹ̀ abẹ fẹ́lẹ́ tí a háyà ní ẹkùn ilẹ̀ Odò,+ àní nípasẹ̀ ọba Ásíríà,+ Jèhófà yóò fá orí àti irun ẹsẹ̀, yóò sì gbá irùngbọ̀n pàápàá lọ.+ 21  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé ẹnì kan yóò pa ẹgbọrọ abo màlúù kan nínú ọ̀wọ́ ẹran àti àgùntàn méjì mọ́ láàyè.+ 22  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu wàrà tí a ń mú jáde, òun yóò máa jẹ bọ́tà; nítorí pé bọ́tà àti oyin+ ni olúkúlùkù ẹni tí a ṣẹ́ kù sí àárín ilẹ̀ náà yóò máa jẹ. 23  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé gbogbo ibi tí ẹgbẹ̀rún àjàrà ti máa ń wà tẹ́lẹ̀ rí, tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà,+ yóò wá wà—àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò ni yóò wá wà fún.+ 24  Tòun ti àwọn ọfà àti ọrun ni yóò wá síbẹ̀,+ nítorí pé gbogbo ilẹ̀ náà yóò di àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò lásán-làsàn. 25  Àti gbogbo òkè ńláńlá tí ó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí, a máa ń fi ọkọ́ tu àwọn ọ̀gbìn rẹ̀ adaniláàmú—ìwọ kì yóò wá síbẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò; dájúdájú, yóò di ibi tí a ti ń tú àwọn akọ màlúù sílẹ̀ àti ilẹ̀ tí àwọn àgùntàn ń tẹ̀ mọ́lẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé