Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 66:1-24

66  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,+ ilẹ̀ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.+ Ibo wá ni ilé tí ẹ lè kọ́ fún mi wà,+ ibo sì wá ni ibi tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún mi?”+  “Wàyí o, ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, tí gbogbo ìwọ̀nyí fi wá wà,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Ẹni yìí, nígbà náà, ni èmi yóò wò, ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ó sì ní ìròbìnújẹ́ nínú ẹ̀mí,+ tí ó sì ń wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.+  “Ẹni tí ń pa akọ màlúù dà bí ẹni tí ń ṣá ènìyàn balẹ̀.+ Ẹni tí ń fi àgùntàn rúbọ dà bí ẹni tí ń ṣẹ́ ọrùn ajá.+ Ẹni tí ń fi ẹ̀bùn rúbọ—bí ẹni tí ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀+ rúbọ! Ẹni tí ń mú ohun ìrántí olóje igi tùràrí+ wá dà bí ẹni tí ń fi àwọn abàmì ọ̀rọ̀+ súre. Àwọn pẹ̀lú jẹ́ àwọn ènìyàn tí ó ti yan ọ̀nà tiwọn, inú àwọn ohun ìríra wọn sì ni ọkàn wọn gan-an ní inú dídùn sí.+  Èmi alára, ẹ̀wẹ̀, yóò yan àwọn ọ̀nà ṣíṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́;+ àwọn ohun tí ń da jìnnìjìnnì bò wọ́n ni èmi yóò sì mú wá bá wọn;+ nítorí ìdí náà pé mo pè, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó dáhùn;+ mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fetí sílẹ̀; wọ́n sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi, ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni wọ́n yàn.”+  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin tí ń wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀:+ “Àwọn arákùnrin yín tí ó kórìíra yín,+ tí ó ta yín nù láwùjọ nítorí orúkọ mi,+ wí pé, ‘Kí a yin Jèhófà lógo!’+ Òun yóò sì fara hàn pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ níhà ọ̀dọ̀ yín,+ àwọn sì ni ìtìjú yóò bá.”+  Ìró ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ń bẹ láti inú ìlú ńlá náà, ìró kan láti inú tẹ́ńpìlì!+ Ó jẹ́ ìró Jèhófà tí ń san ohun tí ó yẹ padà fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.+  Kí ó tó wọnú ìrora ìrọbí, ó ti bímọ.+ Kí ìroragógó ìbímọ tó dé sí i lára, àní ó ti bí ọmọ kan tí ó jẹ́ akọ.+  Ta ni ó ti gbọ́ irú èyí rí?+ Ta ni ó ti rí irú nǹkan báwọ̀nyí rí?+ A ha lè bí ilẹ̀+ kan pẹ̀lú ìrora ìrọbí ní ọjọ́ kan?+ Tàbí kẹ̀, a ha lè bí orílẹ̀-èdè kan+ ní ìgbà kan?+ Nítorí pé Síónì ti wọnú ìrora ìrọbí, ó sì ti bí àwọn ọmọ rẹ̀.  “Ní tèmi, èmi yóò ha fa yíya, kí n má sì fa bíbímọ?”+ ni Jèhófà wí. “Tàbí kẹ̀, èmi yóò ha fa bíbímọ, kí n sì fa títìpa ní tòótọ́?” ni Ọlọ́run rẹ wí. 10  Ẹ bá Jerúsálẹ́mù yọ̀, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú pẹ̀lú rẹ̀,+ gbogbo ẹ̀yin olùfẹ́ rẹ̀.+ Ẹ bá a yọ ayọ̀ ńláǹlà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀;+ 11  nítorí ìdí náà pé ẹ ó mu, ẹ ó sì yó dájúdájú láti inú ọmú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtùnú nípasẹ̀ rẹ̀; nítorí ìdí náà pé ẹ óò sófèrè, ẹ ó sì ní inú dídùn kíkọyọyọ láti inú orí ọmú ògo rẹ̀.+ 12  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò nawọ́ àlàáfíà sí i gẹ́gẹ́ bí odò+ àti ògo àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àkúnya ọ̀gbàrá,+ ó sì dájú pé ẹ ó mu.+ Ìhà ni a óò gbé yín sí, orí eékún sì ni a ó ti máa ṣìkẹ́ yín.+ 13  Bí ènìyàn tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi fúnra mi yóò ṣe máa tù yín nínú;+ àti ní ti ọ̀ràn Jerúsálẹ́mù, a ó tù yín nínú.+ 14  Ẹ ó sì rí i, ọkàn-àyà yín yóò sì yọ ayọ̀ ńláǹlà dájúdájú,+ àní egungun+ yín yóò sì rú jáde gẹ́gẹ́ bí koríko tútù yọ̀yọ̀.+ Dájúdájú, a ó sì sọ ọwọ́ Jèhófà di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n òun yóò dá àwọn ọ̀tá rẹ̀ lẹ́bi+ ní ti tòótọ́.” 15  “Nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ rèé tí ń bọ̀ àní bí iná,+ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bí ẹ̀fúùfù oníjì,+ láti lè fi ìhónú tí ó bùáyà san ìbínú rẹ̀ padà, kí ó sì fi ọwọ́ iná san ìbáwí mímúná rẹ̀ padà.+ 16  Nítorí pé bí iná ni Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ìjà náà ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, pẹ̀lú idà rẹ̀,+ lòdì sí gbogbo ẹran ara; dájúdájú, àwọn tí Jèhófà pa yóò di púpọ̀.+ 17  Àwọn tí ń sọ ara wọn di mímọ́, tí wọ́n sì ń wẹ ara wọn mọ́ fún àwọn ọgbà+ lẹ́yìn èyí tí ó wà ní àárín, tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀+ àti ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin, títí kan eku+ pàápàá, gbogbo wọn lápapọ̀ yóò dé òpin wọn,” ni àsọjáde Jèhófà. 18  “Àti ní ti iṣẹ́+ wọn àti ìrònú+ wọn, mo ń bọ̀ wá kó gbogbo orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọpọ̀;+ dájúdájú, wọn yóò sì wá, wọn yóò sì rí ògo mi.”+ 19  “Ṣe ni èmi yóò sì gbé àmì+ kan kalẹ̀ sáàárín wọn, èmi yóò sì rán lára àwọn tí ó ti sá àsálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè,+ sí Táṣíṣì,+ Púlì, àti Lúdì,+ àwọn tí ń fa ọrun, Túbálì àti Jáfánì,+ àwọn erékùṣù jíjìnnàréré,+ àwọn tí kò tíì gbọ́ ìròyìn nípa mi tàbí kí wọ́n rí ògo mi;+ ó sì dájú pé wọn yóò sọ nípa ògo mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 20  Ní tòótọ́, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn arákùnrin yín jáde láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè+ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Jèhófà,+ lórí ẹṣin àti nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti nínú kẹ̀kẹ́ tí a bò lórí àti lórí ìbaaka àti lórí abo ràkúnmí ayárakánkán,+ gòkè wá sórí òkè ńlá mímọ́ mi,+ Jerúsálẹ́mù,” ni Jèhófà wí, “gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ohun èlò tí ó mọ́ gbé ẹ̀bùn wá sínú ilé Jèhófà.”+ 21  “Nínú wọn pẹ̀lú ni èmi yóò sì ti mú àwọn kan ṣe àlùfáà, àní ṣe àwọn ọmọ Léfì,” ni Jèhófà wí. 22  “Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀run tuntun+ àti ilẹ̀ ayé tuntun+ tí èmi yóò ṣe ti dúró níwájú mi,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ yín+ àti orúkọ yín yóò dúró.”+ 23  “Dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì, gbogbo ẹran ara yóò wọlé wá tẹrí ba níwájú mi,”+ ni Jèhófà wí. 24  “Wọn yóò sì jáde lọ ní tòótọ́, wọn yóò sì wo òkú àwọn ènìyàn tí ń rélànà mi kọjá;+ nítorí pé kòkòrò mùkúlú tí ó wà lára wọn kì yóò kú, iná wọn ni a kì yóò sì fẹ́ pa,+ wọn yóò sì di ohun tí ń kóni nírìíra fún gbogbo ẹran ara.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé