Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 65:1-25

65  “Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò béèrè mi+ wá mi kiri.+ Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò wá mi rí mi.+ Mo ti wí pé, ‘Èmi rèé, èmi rèé!’+ fún orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi.+  “Mo ti tẹ́ ọwọ́ mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ sí àwọn alágídí,+ àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára,+ tọ ìrònú wọn lẹ́yìn;+  àwọn ènìyàn tí ó para pọ̀ jẹ́ àwọn tí ń mú mi bínú+ ní ojú mi gan-an nígbà gbogbo, àwọn tí ń rúbọ nínú àwọn ọgbà,+ tí wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ+ lórí àwọn bíríkì,  àwọn tí ń jókòó sáàárín àwọn ibi ìsìnkú,+ àní tí wọ́n tún ń sun inú àwọn ahéré ìṣọ́ mọ́jú, tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,+ àní omitoro àwọn ohun tí a sọ di àìmọ́+ wà nínú àwọn ohun èlò wọn;  àwọn tí ń sọ pé, ‘Dá dúró gedegbe. Má ṣe sún mọ́ mi, nítorí pé èmi yóò mú ìjẹ́mímọ́ wá fún ọ dájúdájú.’+ Àwọn wọ̀nyí jẹ́ èéfín nínú ihò imú mi,+ wọ́n jẹ́ iná tí ń jó láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+  “Wò ó! A kọ̀wé rẹ̀ síwájú mi.+ Èmi kì yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́,+ ṣùgbọ́n ó dájú pé èmi yóò san ẹ̀san;+ àní èmi yóò san ẹ̀san náà sí oókan àyà tiwọn+ dájúdájú,  fún àwọn ìṣìnà wọn àti fún àwọn ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn lẹ́ẹ̀kan náà,”+ ni Jèhófà wí. “Nítorí pé wọ́n ti rú èéfín ẹbọ lórí àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ti gàn mí+ lórí àwọn òkè kéékèèké,+ ṣe ni èmi yóò kọ́kọ́ díwọ̀n owó ọ̀yà wọn sí oókan àyà wọn.”+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Lọ́nà kan náà tí a gbà ń rí wáìnì tuntun+ nínú òṣùṣù, tí ẹnì kan yóò sì wá sọ pé, ‘Má bà á jẹ́,+ nítorí pé ìbùkún wà nínú rẹ̀,’+ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí àwọn ìránṣẹ́ mi, kí n má bàa run gbogbo wọn.+  Dájúdájú, èmi yóò sì mú ọmọ kan+ jáde wá láti Jékọ́bù àti láti Júdà olùni àwọn òkè ńlá mi gẹ́gẹ́ bí ohun ìní àjogúnbá;+ àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì gbà á,+ àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò sì máa gbé níbẹ̀.+ 10  Ṣárónì+ yóò sì di ilẹ̀ ìjẹko fún àwọn àgùntàn,+ pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Ákórì+ yóò sì di ibi ìsinmi fún àwọn màlúù, fún àwọn ènìyàn mi tí yóò ti wá mi.+ 11  “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ àwọn tí ń fi Jèhófà sílẹ̀,+ àwọn tí ń gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi,+ àwọn tí ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire,+ àti àwọn tí ń bu àdàlù wáìnì kún dẹ́nu fún ọlọ́run Ìpín.+ 12  Ṣe ni èmi yóò yàn yín sọ́tọ̀ fún idà,+ gbogbo yín yóò sì tẹrí ba fún ìfikúpa;+ nítorí ìdí náà pé mo pè,+ ṣùgbón ẹ kò dáhùn; mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀;+ ẹ sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi,+ ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni ẹ yàn.”+ 13  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò jẹun,+ ṣùgbọ́n ebi yóò pa ẹ̀yin.+ Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò mu,+ ṣùgbọ́n òùngbẹ yóò gbẹ ẹ̀yin.+ Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò yọ̀,+ ṣùgbọ́n ojú yóò ti ẹ̀yin.+ 14  Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe ẹkún nítorí ìrora ọkàn-àyà, ẹ ó sì hu nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó bùáyà.+ 15  Dájúdájú, ẹ ó sì to orúkọ yín jọ fún ìbúra nípasẹ̀ àwọn àyànfẹ́ mi, ṣe ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò sì fi ikú pa yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan,+ ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tirẹ̀ ni yóò fi orúkọ mìíràn pè;+ 16  tí yóò fi jẹ́ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń súre fún ara rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé yóò máa fi Ọlọ́run ìgbàgbọ́+ súre fún ara rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń sọ gbólóhùn ìbúra ní ilẹ̀ ayé yóò máa fi Ọlọ́run ìgbàgbọ́+ búra; nítorí pé àwọn wàhálà àtijọ́ ni a ó gbàgbé ní ti tòótọ́ àti nítorí pé a ó fi wọ́n pa mọ́ kúrò ní ojú mi+ ní ti tòótọ́. 17  “Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun+ àti ilẹ̀ ayé tuntun;+ àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.+ 18  Ṣùgbọ́n ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà,+ kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá.+ Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá Jerúsálẹ́mù ní ohun ti ń fa ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà.+ 19  Ó sì dájú pé èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Jerúsálẹ́mù, èmi yóò sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú àwọn ènìyàn mi;+ a kì yóò sì gbọ́ ìró ẹkún tàbí ìró igbe arò mọ́ nínú rẹ̀.”+ 20  “Kì yóò sí ọmọ ẹnu ọmú kan níbẹ̀ tí ọjọ́ rẹ̀ kéré níye,+ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí àgbàlagbà kan tí ọjọ́ rẹ̀ kò kún;+ nítorí pé ẹnì kan yóò kú ní ọmọdékùnrin lásán-làsàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún; àti ní ti ẹlẹ́ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, a ó pe ibi wá sórí rẹ̀.+ 21  Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn;+ dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.+ 22  Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;+ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.+ 23  Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu;+ nítorí pé àwọn ni ọmọ tí ó para pọ̀ jẹ́ alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà,+ àti àwọn ọmọ ìran wọn pẹ̀lú wọn.+ 24  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ti tòótọ́ pé, kí wọ́n tó pè, èmi fúnra mi yóò dáhùn;+ bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi fúnra mi yóò gbọ́.+ 25  “Ìkookò+ àti ọ̀dọ́ àgùntàn pàápàá yóò máa jùmọ̀ jẹun pọ̀,+ kìnnìún yóò sì máa jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù;+ àti ní ti ejò, oúnjẹ rẹ̀ yóò jẹ́ ekuru.+ Wọn kì yóò ṣe ìpalára kankan,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi,”+ ni Jèhófà wí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé