Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 64:1-12

64  Ìwọ ì bá jẹ́ gbọn ọ̀run ya, kí o sọ̀ kalẹ̀,+ kí àwọn òkè ńlá pàápàá mì tìtì ní tìtorí rẹ,+  bí ìgbà tí iná ran igbó igi wíwẹ́, tí iná sì mú kí omi gan-an hó yaya, kí o bàa lè sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn elénìní rẹ,+ kí ṣìbáṣìbo bá àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí rẹ!+  Nígbà tí o ṣe àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù,+ èyí tí àwa kò lè retí, ìwọ sọ̀ kalẹ̀. Ní tìtorí rẹ, àwọn òkè ńlá pàápàá mì tìtì.+  Àti láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ kò sí ẹni tí ó tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi etí sí i, bẹ́ẹ̀ ni ojú kò tíì rí Ọlọ́run kan, bí kò ṣe ìwọ,+ tí ń gbé ìgbésẹ̀ ní tìtorí ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.+  Ìwọ ti bá ẹni tí ń yọ ayọ̀ ńláǹlà pàdé tí ó sì ń ṣe òdodo,+ àwọn tí ń rántí rẹ ní àwọn ọ̀nà rẹ.+ Wò ó! Ìkannú tìrẹ ru,+ nígbà tí a ń dẹ́ṣẹ̀ ṣáá+—a sì pẹ́ gan-an nínú wọn, a ó ha sì gbà wá là?+  A sì wá dà bí aláìmọ́, gbogbo wa, gbogbo ìṣe òdodo wa sì dà bí aṣọ fún sáà ṣíṣe nǹkan oṣù;+ àwa yóò sì rẹ̀ dànù bí ewé,+ gbogbo wa, àwọn ìṣìnà wa ni yóò sì kó wa lọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀fúùfù.+  Kò sì sí ẹni tí ń ké pe orúkọ rẹ,+ kò sí ẹni tí ń ta ara rẹ̀ jí láti dì ọ́ mú; nítorí pé ìwọ ti fi ojú rẹ pa mọ́ fún wa,+ o sì mú kí a yọ́+ nípasẹ̀ agbára ìṣìnà wa.  Wàyí o, Jèhófà, ìwọ ni Baba wa.+ Àwa ni amọ̀,+ ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá;+ gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+  Jèhófà, má ṣe jẹ́ kí ìkannú rẹ ru dé góńgó,+ má sì rántí ìṣìnà wa+ títí láé. Jọ̀wọ́, wò ó, nísinsìnyí: ènìyàn rẹ ni gbogbo wa jẹ́.+ 10  Àwọn ìlú ńlá mímọ́ rẹ+ ti di aginjù. Síónì+ alára ti di kìkìdá aginjù, Jerúsálẹ́mù ti di ahoro.+ 11  Ilé wa ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà,+ inú èyí tí àwọn baba ńlá wa ti yìn ọ́,+ ti di ohun sísun nínú iná;+ gbogbo ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra+ wa ti di ìparundahoro. 12  Lójú nǹkan wọ̀nyí, ìwọ yóò ha máa bá a nìṣó ní kíkó ara rẹ níjàánu,+ Jèhófà? Ìwọ yóò ha dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì jẹ́ kí a ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́ dé góńgó?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé