Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 62:1-12

62  Nítorí ti Síónì, èmi kì yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́,+ àti nítorí ti Jerúsálẹ́mù,+ èmi kì yóò dúró jẹ́ẹ́ títí òdodo rẹ̀ yóò fi jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ìtànyòò,+ àti ìgbàlà rẹ̀ bí ògùṣọ̀ tí ń jó.+  “Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì rí òdodo rẹ,+ ìwọ obìnrin,+ gbogbo àwọn ọba yóò sì rí ògo rẹ.+ Ní ti tòótọ́, a ó sì máa fi orúkọ tuntun pè ọ́,+ èyí tí ẹnu Jèhófà gan-an yóò dárúkọ.  Ìwọ yóò sì di adé ẹwà ní ọwọ́ Jèhófà,+ àti láwàní ọba ní àtẹ́lẹwọ́ Ọlọ́run rẹ.  A kì yóò sọ mọ́ pé ìwọ jẹ́ obìnrin tí a fi sílẹ̀ pátápátá;+ a kì yóò sì sọ mọ́ pé ilẹ̀ rẹ wà ní ahoro;+ ṣùgbọ́n a óò máa pe ìwọ alára ní Inú Dídùn Mi Wà Nínú Rẹ̀,+ a ó sì máa pe ilẹ̀ rẹ ní Èyí Tí A Mú Ṣe Aya. Nítorí pé Jèhófà yóò ti ní inú dídùn sí ọ, ilẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ èyí tí a mú ṣe aya.+  Nítorí pé gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin ti ń mú wúńdíá ṣe aya, àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò mú ọ ṣe aya.+ Àti pẹ̀lú ayọ̀ ńláǹlà tí ọkọ ìyàwó máa ń ní nítorí ìyàwó,+ Ọlọ́run rẹ yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà àní nítorí rẹ.+  Èmi ti fàṣẹ yan àwọn olùṣọ́ sórí àwọn ògiri rẹ,+ ìwọ Jerúsálẹ́mù. Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ àti láti òru mọ́jú, nígbà gbogbo, kí wọ́n má ṣe dákẹ́ jẹ́ẹ́.+ “Ẹ̀yin tí ń mẹ́nu kan Jèhófà,+ kí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ má ṣe sí níhà ọ̀dọ̀ yín,+  kí ẹ má sì fún un ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ títí yóò fi fìdí Jerúsálẹ́mù sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, bẹ́ẹ̀ ni, títí yóò fi gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyìn ní ilẹ̀ ayé.”+  Jèhófà ti fi ọwọ́ ọ̀tún+ rẹ̀ àti apá rẹ̀ lílágbára+ búra pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọkà rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ+ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kì yóò mu wáìnì rẹ tuntun+ mọ́, èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá lé lórí.  Ṣùgbọ́n àwọn tí ń kó o jọ gan-an ni yóò jẹ ẹ́, ó sì dájú pé wọn yóò yin Jèhófà; àní àwọn tí ń gbá a jọ ni yóò mu ún ní àwọn àgbàlá mímọ́ mi.”+ 10  Ẹ kọjá síta, ẹ gba àwọn ẹnubodè kọjá síta. Ẹ tún ọ̀nà àwọn ènìyàn ṣe.+ Ẹ kọ bèbè, ẹ kọ bèbè òpópó. Ẹ ṣa àwọn òkúta rẹ̀ kúrò.+ Ẹ gbé àmì àfiyèsí sókè fún àwọn ènìyàn.+ 11  Wò ó! Jèhófà tìkára rẹ̀ ti mú kí a gbọ́ ọ títí dé ibi jíjìnnà jù lọ lórí ilẹ̀ ayé+ pé: “Ẹ wí fún ọmọbìnrin Síónì+ pé, ‘Wò ó! Ìgbàlà rẹ ń bọ̀.+ Wò ó! Ẹ̀san tí ó ń san ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀,+ owó ọ̀yà tí ó ń san sì wà níwájú rẹ̀.’”+ 12  Ṣe ni àwọn ènìyàn yóò sì máa pè wọ́n ní ẹni mímọ́,+ àwọn tí Jèhófà tún rà;+ a ó sì máa pe ìwọ alára ní Ẹni Tí A Wá Kiri, Ìlú Ńlá Tí A Kò Fi Sílẹ̀ Pátápátá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé