Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 61:1-11

61  Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ń bẹ lára mi,+ nítorí ìdí náà pé Jèhófà ti fòróró yàn mí+ láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù.+ Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn,+ láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè+ àti ìlajúsílẹ̀ rekete àní fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n;+  láti pòkìkí ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà+ àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa;+ láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú;+  láti yàn fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ fún Síónì, láti fún wọn ní ìwérí dípò eérú,+ òróró ayọ̀ ńláǹlà dípò ọ̀fọ̀,+ aṣọ àlàbora ìyìn dípò ẹ̀mí ìsoríkodò;+ a ó sì máa pè wọ́n ní igi ńlá òdodo,+ ọ̀gbìn Jèhófà,+ kí a lè ṣe é lẹ́wà.+  Wọn yóò sì tún àwọn ibi ìparundahoro tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́ kọ́;+ wọn yóò gbé àwọn ibi ahoro ti ìgbà àtijọ́ dìde,+ wọn yóò sì sọ àwọn ìlú ńlá tí a ti pa run dahoro di àkọ̀tun,+ àwọn ibi tí ó ti wà ní ahoro láti ìran dé ìran.  “Àwọn àjèjì yóò sì dúró ní ti tòótọ́, wọn yóò sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn agbo ẹran yín,+ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè+ sì ni yóò jẹ́ àgbẹ̀ yín àti olùrẹ́wọ́ àjàrà yín.+  Àti pé ní ti ẹ̀yin, àlùfáà Jèhófà ni a óò máa pè yín;+ òjíṣẹ́+ Ọlọ́run wa ni a ó sọ pé ẹ̀yin jẹ́.+ Ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni ẹ ó jẹ,+ inú ògo wọn sì ni ẹ ó ti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó kún fún ayọ̀ nípa ara yín.+  Dípò ìtìjú yín, ìpín ìlọ́po méjì ni yóò wà,+ àti pé dípò ìtẹ́lógo, wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde nítorí ìpín wọn.+ Nítorí náà, ní ilẹ̀ wọn, wọn yóò gba ìpín ìlọ́po méjì.+ Ayọ̀ yíyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni yóò wá jẹ́ tiwọn.+  Nítorí pé èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo,+ mo kórìíra ìjanilólè pa pọ̀ pẹ̀lú àìṣòdodo.+ Dájúdájú, èmi yóò sì fi owó ọ̀yà wọn fún wọn ní òótọ́,+ májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò sì bá wọn dá.+  Ní ti tòótọ́, a ó mọ àwọn ọmọ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá,+ àti àwọn ọmọ ìran wọn láàárín àwọn ènìyàn. Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò dá wọn mọ̀,+ pé àwọn ni ọmọ tí Jèhófà bù kún.”+ 10  Láìkùnà, èmi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà.+ Ọkàn mi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run mi.+ Nítorí pé ó ti fi ẹ̀wù ìgbàlà wọ̀ mí;+ ó ti fi aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó jẹ́ ti òdodo bò mí,+ bí ọkọ ìyàwó tí ó wé ìwérí,+ bí ti àlùfáà, àti bí ìyàwó tí ó fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.+ 11  Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ayé ti ń mú ìrújáde rẹ̀ wá, àti gẹ́gẹ́ bí ọgbà ti ń mú kí àwọn nǹkan tí a fúnrúgbìn sínú rẹ̀ rú jáde,+ ní irú ọ̀nà kan náà ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò mú kí òdodo+ àti ìyìn rú jáde ní iwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé