Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 60:1-22

60  “Dìde,+ ìwọ obìnrin, tan ìmọ́lẹ̀ jáde,+ nítorí pé ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,+ àní ògo Jèhófà sì ti tàn sára rẹ.+  Nítorí, wò ó! òkùnkùn+ pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò tàn sára rẹ, a ó sì rí ògo rẹ̀ lára rẹ.+  Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ,+ àwọn ọba+ yóò sì lọ sínú ìtànyòò tí ó wá láti inú ìtànjáde rẹ.+  “Gbé ojú rẹ sókè yí ká, kí o sì wò! A ti kó gbogbo wọn jọpọ̀;+ wọ́n ti wá sọ́dọ̀ rẹ.+ Ibi jíjìnnàréré ni àwọn ọmọkùnrin rẹ ti ń bọ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ tí a óò tọ́jú ní ìhà rẹ.+  Ní àkókò yẹn, ìwọ yóò wò, ìwọ yóò sì wá tàn yinrin dájúdájú,+ ọkàn-àyà rẹ yóò sì gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní tòótọ́, yóò sì gbòòrò, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni ọlà òkun yóò darí sí; àní ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sọ́dọ̀ rẹ.+  Ìrọ́-sókè-sódò àgbájọ ràkúnmí pàápàá yóò bò ọ́, àwọn ẹgbọrọ akọ ràkúnmí Mídíánì àti ti Eéfà.+ Gbogbo àwọn tí ó wá láti Ṣébà+—wọn yóò wá. Wúrà àti oje igi tùràrí ni wọn yóò rù. Ìyìn Jèhófà sì ni wọn yóò máa kéde.+  Gbogbo agbo ẹran Kídárì+—a óò kó wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ. Àwọn àgbò Nébáótì+—wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ.+ Pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà ni wọ́n yóò fi gòkè wá sórí pẹpẹ mi,+ èmi yóò sì bu ẹwà kún ilé ẹwà mi.+  “Ta ni ìwọ̀nyí tí ń fò bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà,+ àti bí àdàbà sí ihò ilé ẹyẹ wọn?  Nítorí pé èmi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò máa retí,+ àti àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́, láti lè kó àwọn ọmọ rẹ láti ibi jíjìnnàréré wá,+ bí fàdákà wọn àti wúrà wọn ti ń bẹ pẹ̀lú wọn,+ fún orúkọ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti fún Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ nítorí pé yóò ti ṣe ọ́ lẹ́wà.+ 10  Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yóò sì mọ àwọn ògiri rẹ+ ní ti tòótọ́, àwọn ọba wọn yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ;+ nítorí pé nínú ìkannú mi ni èmi yóò ti kọlù ọ́,+ ṣùgbọ́n nínú ìfẹ́ rere mi ni èmi yóò ti ṣàánú fún ọ dájúdájú.+ 11  “Ní ti tòótọ́, a óò ṣí àwọn ẹnubodè rẹ sílẹ̀ nígbà gbogbo;+ a kì yóò tì wọ́n àní ní ọ̀sán tàbí ní òru, láti lè mú ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá sọ́dọ̀ rẹ,+ àwọn ọba wọn yóò sì mú ipò iwájú.+ 12  Nítorí pé orílẹ̀-èdè èyíkéyìí àti ìjọba èyíkéyìí tí kò bá sìn ọ́ yóò ṣègbé; àwọn orílẹ̀-èdè náà alára yóò sì wá sínú ìparundahoro dájúdájú.+ 13  “Ọ̀dọ̀ rẹ ni ògo Lẹ́bánónì gan-an yóò wá, igi júnípà, igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì lẹ́ẹ̀kan náà,+ láti lè ṣe ibùjọsìn mi lẹ́wà;+ èmi yóò sì ṣe àyè ẹsẹ̀ mi gan-an lógo.+ 14  “Ọ̀dọ̀ rẹ sì ni àwọn ọmọ àwọn tí ń ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́ yóò wá, ní títẹríba;+ gbogbo àwọn tí ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọ yóò sì tẹ̀ ba síbi àtẹ́lẹsẹ̀+ rẹ gan-an, dájúdájú, wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú ńlá Jèhófà, Síónì+ tí í ṣe ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. 15  “Dípò kí ìwọ já sí ẹni tí a fi sílẹ̀ pátápátá, tí a sì kórìíra, láìsí ẹnikẹ́ni tí ń gba inú rẹ kọjá,+ ṣe ni èmi yóò tilẹ̀ sọ ọ́ di ohun ìyangàn fún àkókò tí ó lọ kánrin, ayọ̀ ńláǹlà fún ìran dé ìran.+ 16  Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò sì fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu,+ ìwọ yóò sì mu ọmú àwọn ọba;+ dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi, Jèhófà,+ ni Olùgbàlà+ rẹ, Ẹni Alágbára+ Jékọ́bù sì ni Olùtúnnirà+ rẹ. 17  Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá,+ àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó+ rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.+ 18  “A kì yóò gbọ́ ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ, a kì yóò gbọ́ ìfiṣèjẹ tàbí ìwópalẹ̀ ní ààlà rẹ.+ Dájúdájú, ìwọ yóò sì pe àwọn ògiri rẹ ní Ìgbàlà+ àti àwọn ẹnubodè rẹ ní Ìyìn. 19  Oòrùn kì yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ mọ́ ní ọ̀sán, òṣùpá pàápàá kì yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ mọ́ fún ìtànyòò. Jèhófà yóò sì di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin+ fún ọ, Ọlọ́run rẹ yóò sì di ẹwà rẹ.+ 20  Oòrùn rẹ kì yóò wọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kì yóò wọ̀ọ̀kùn; nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin+ fún ọ, àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóò sì parí dájúdájú.+ 21  Àti ní ti àwọn ènìyàn rẹ, gbogbo wọn yóò jẹ́ olódodo;+ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò fi ilẹ̀ náà ṣe ìní,+ èéhù tí mo gbìn,+ iṣẹ́ ọwọ́ mi,+ kí a lè ṣe mí lẹ́wà.+ 22  Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.+ Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé