Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 59:1-21

59  Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù tí kò fi lè gbani là,+ bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò wúwo jù tí kò fi lè gbọ́.+  Rárá, ṣùgbọ́n àwọn ìṣìnà tiyín gan-an ti di ohun tí ń fa ìpínyà láàárín ẹ̀yin àti Ọlọ́run yín,+ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín sì ti ṣokùnfà fífi tí ó fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún yín kí ó má bàa máa gbọ́.+  Nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ti sọ àtẹ́lẹwọ́ yín di eléèérí,+ ìṣìnà sì ti sọ ìka yín di eléèérí. Ètè yín ti sọ èké.+ Ahọ́n yín ń sọ kìkìdá àìṣòdodo lábẹ́lẹ̀.+  Kò sí ẹni tí ń ké jáde nínú òdodo,+ kò sì sí ẹnì kankan tí ó lọ sí kóòtù nínú ìṣòtítọ́. Gbígbẹ́kẹ̀lé òtúbáńtẹ́+ ń ṣẹlẹ̀, àti sísọ ohun àìníláárí.+ Lílóyún ìjàngbọ̀n ń ṣẹlẹ̀, àti bíbí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́.+  Ẹyin ejò olóró ni wọ́n pa, wọ́n sì ń hun jàǹkárìwọ̀ aláǹtakùn+ lásán-làsàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ lára ẹyin wọn yóò kú, ẹyin tí a bá sì tẹ̀ fọ́ yóò pa paramọ́lẹ̀.+  Jàǹkárìwọ̀ wọn lásán-làsàn kì yóò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fi iṣẹ́ wọn bo ara wọn.+ Iṣẹ́ wọn jẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ìgbòkègbodò ìwà ipá sì ń bẹ ní àtẹ́lẹwọ́ wọn.+  Ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí kìkì ìwà búburú,+ wọ́n sì ń ṣe kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀.+ Ìrònú wọn jẹ́ ìrònú tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́;+ ìfiṣèjẹ àti ìwópalẹ̀ ń bẹ ní àwọn òpópó wọn.+  Wọ́n ti fi ọ̀nà àlàáfíà+ dá àgunlá, kò sì sí ìdájọ́ òdodo ní àwọn òpó ọ̀nà wọn.+ Àwọn òpópónà wọn ni wọ́n ti ṣe ní wíwọ́ fún ara wọn.+ Kò sí ẹnì kankan tí ń rìn nínú wọn tí yóò mọ àlàáfíà ní ti gidi.+  Ìdí nìyẹn tí ìdájọ́ òdodo fi wá jìnnà réré sí wa, tí òdodo kò sì bá wa. A ń retí ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, wò ó! òkùnkùn; a ń retí ìtànyòò, ṣùgbọ́n inú ìṣúdùdù ìgbà gbogbo ni a ń rìn.+ 10  A ń táràrà wá ògiri gẹ́gẹ́ bí àwọn afọ́jú, àti bí àwọn tí kò ní ojú ni àwa ń táràrà.+ A ti kọsẹ̀ ní ọ̀sán ganrínganrín gẹ́gẹ́ bí ẹni pé nínú òkùnkùn alẹ́; láàárín àwọn tí ó taagun, a kàn dà bí òkú.+ 11  Àwa ń kérora ṣáá, gbogbo wa, gẹ́gẹ́ bí béárì; àti bí àdàbà, ṣe ni a ń ké kúùkúù+ tọ̀fọ̀-tọ̀fọ̀. A ń retí ìdájọ́ òdodo ṣáá,+ ṣùgbọ́n kò sí ìkankan; a ń retí ìgbàlà, ṣùgbọ́n ó dúró ní ọ̀nà jíjìnréré sí wa.+ 12  Nítorí pé ìdìtẹ̀ wa ti di púpọ̀ ní iwájú rẹ;+ àti ní ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀kọ̀ọ̀kan ti jẹ́rìí lòdì sí wa.+ Nítorí pé àwọn ìdìtẹ̀ wa ń bẹ pẹ̀lú wa; àti ní ti àwọn ìṣìnà wa, a mọ̀ wọ́n dáadáa.+ 13  Ìrélànàkọjá àti sísẹ́ Jèhófà+ ti ṣẹlẹ̀; sísún sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, sísọ̀rọ̀ ìnilára àti ìdìtẹ̀,+ lílóyún èké àti sísọ ọ̀rọ̀ èké lábẹ́lẹ̀ láti inú ọkàn-àyà+ gan-an sì ti ṣẹlẹ̀. 14  A sì fipá sún ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,+ òdodo pàápàá sì wulẹ̀ dúró sí ibi jíjìnnàréré.+ Nítorí pé òtítọ́ ti kọsẹ̀ àní ní ojúde ìlú, ohun tí ó tọ́ kò sì lè wọlé.+ 15  Òtítọ́ sì dàwáàrí,+ ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń yí padà kúrò nínú ìwà búburú ni a ń fi ṣe ìjẹ.+ Jèhófà rí i, ó sì burú ní ojú rẹ̀ pé kò sí ìdájọ́ òdodo.+ 16  Nígbà tí ó sì rí i pé kò sí ènìyàn kankan, ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà á pé kò sí ẹnì kankan tí ń báni ṣìpẹ̀.+ Apá rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a gbani là, òdodo rẹ̀ sì ni ohun tí ó tì í lẹ́yìn.+ 17  Nígbà náà ni ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe,+ ó sì fi àṣíborí ìgbàlà sí orí rẹ̀.+ Síwájú sí i, ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ àgbéwọ̀,+ ó sì fi ìtara bo ara rẹ̀ bí ẹni pé aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ ni. 18  Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìbálò náà ni òun yóò san ẹ̀san lọ́nà tí ó bá a mu rẹ́gí,+ ìhónú fún àwọn elénìní rẹ̀, ìlòsí yíyẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.+ Yóò san ìlòsí yíyẹ fún àwọn erékùṣù.+ 19  Láti wíwọ̀-oòrùn sì ni wọn yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù orúkọ Jèhófà,+ àti ògo rẹ̀ láti yíyọ oòrùn,+ nítorí pé yóò wọlé wá bí odò tí ń kó wàhálà báni, èyí tí ẹ̀mí Jèhófà gan-an ń gbá lọ.+ 20  “Dájúdájú, Olùtúnnirà+ yóò sì wá sí Síónì,+ àti sọ́dọ̀ àwọn tí ń yí padà kúrò nínú ìrélànàkọjá nínú Jékọ́bù,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 21  “Àti pé ní tèmi, èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn,”+ ni Jèhófà wí. “Ẹ̀mí mi tí ó wà lára rẹ+ àti àwọn ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí ẹnu rẹ+—a kì yóò mú wọn kúrò ní ẹnu rẹ tàbí kúrò ní ẹnu àwọn ọmọ rẹ tàbí kúrò ní ẹnu àwọn ọmọ-ọmọ rẹ,” ni Jèhófà wí, “láti ìsinsìnyí lọ àní dé àkókò tí ó lọ kánrin.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé