Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 58:1-14

58  “Fi gbogbo ọ̀fun ké; má fawọ́ sẹ́yìn.+ Gbé ohùn rẹ sókè bí ìwo, kí o sì sọ ìdìtẹ̀ àwọn ènìyàn mi fún wọn,+ kí o sì sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jékọ́bù fún un.  Síbẹ̀, ní ọjọ́ dé ọjọ́, èmi ni wọ́n ń wá, ìmọ̀ àwọn ọ̀nà mi sì ni wọ́n fi inú dídùn hàn sí,+ bí orílẹ̀-èdè tí ń bá a lọ ní ṣíṣe òdodo, tí kò sì fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wọn sílẹ̀,+ ní ti pé wọ́n ń béèrè fún ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́ mi, wọ́n ń sún mọ́ Ọlọ́run tí wọ́n ní inú dídùn sí,+  “‘Fún ìdí wo ni a fi ń gbààwẹ̀ tí ìwọ kò sì rí i,+ tí a sì ń ṣẹ́ ọkàn+ wa níṣẹ̀ẹ́ tí ìwọ kò sì fiyè sí i?’+ “Ní tòótọ́, ẹ̀yin ń rí inú dídùn nínú ọjọ́ ààwẹ̀ gbígbà yín, nígbà tí gbogbo àwọn aṣelàálàá yín ń bẹ tí ẹ ń kó lọ ṣiṣẹ́ ṣáá.+  Ní tòótọ́, fún aáwọ̀ àti ìjàkadì ni ẹ ń gbààwẹ̀,+ àti fún fífi ìkúùkù ìwà burúkú gbáni.+ Ẹ̀yin kò ha ń gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ tí ẹ ń mú kí a gbọ́ ohùn yín ní ibi gíga?  Ṣé ó yẹ kí ààwẹ̀ tí mo yàn dà báyìí, bí ọjọ́ tí ará ayé ń ṣẹ́ ọkàn rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́?+ Tí ó ń tẹ orí rẹ̀ ba bí koríko etídò, kí ó sì tẹ́ aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú lásán-làsàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀?+ Ṣé èyí ni ẹ ń pè ní ààwẹ̀ àti ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Jèhófà?+  “Èyí ha kọ́ ni ààwẹ̀ tí mo yàn? Láti tú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìwà burúkú,+ láti tú ọ̀já ọ̀pá àjàgà,+ àti láti rán àwọn tí a ni lára lọ lómìnira,+ àti pé kí ẹ fa gbogbo ọ̀pá àjàgà já sí méjì?+  Kì í ha ṣe pípín oúnjẹ rẹ fún ẹni tí ebi ń pa,+ àti pé kí o mú àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, àwọn aláìnílé, wá sínú ilé rẹ?+ Pé, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ rí ẹnì kan tí ó wà ní ìhòòhò, kí o bò ó,+ àti pé kí o má fi ara rẹ pa mọ́ fún ẹran ara tìrẹ?+  “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò là gẹ́gẹ́ bí ọ̀yẹ̀;+ pẹ̀lú ìyára kánkán sì ni ìkọ́fẹ yóò rú jáde fún ọ.+ Iwájú rẹ sì ni òdodo rẹ yóò ti máa rìn dájúdájú;+ àní ògo Jèhófà ni yóò jẹ́ ẹ̀ṣọ́ rẹ níhà ẹ̀yìn.+  Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò pè, Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò sì dáhùn; ìwọ yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+ òun yóò sì wí pé, ‘Èmi rèé!’ “Bí ìwọ yóò bá mú ọ̀pá àjàgà,+ nína ìka,+ àti sísọ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́+ kúrò ní àárín rẹ; 10  tí ìwọ yóò sì yọ̀ǹda ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọkàn rẹ+ fún ẹni tí ebi ń pa, tí ìwọ yóò sì tẹ́ ọkàn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ lọ́rùn, ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú yóò kọ mànà àní nínú òkùnkùn, ìṣúdùdù rẹ yóò sì dà bí ọjọ́kanrí.+ 11  Ó dájú pé Jèhófà yóò máa ṣamọ̀nà+ rẹ nígbà gbogbo,+ yóò sì máa tẹ́ ọkàn rẹ lọ́rùn àní ní ilẹ̀ gbígbẹ,+ yóò sì fún egungun rẹ gan-an lókun;+ ìwọ yóò sì dà bí ọgbà tí a ń bomi rin dáadáa,+ àti bí orísun omi, omi tí kì í tanni jẹ. 12  Nítorí rẹ, ó dájú pé àwọn ènìyàn yóò kọ́ àwọn ibi tí a ti pa run di ahoro tipẹ́tipẹ́;+ ìwọ yóò gbé ìpìlẹ̀ àwọn ìran tí ń bá a lọ dìde.+ Ní ti tòótọ́, a óò máa pè ọ́ ní ẹni tí ń ṣe àtúnṣe àwọn àlàfo,+ àti ẹni tí ń mú àwọn òpópónà tí a óò máa gbé ẹ̀gbẹ́ wọn padà bọ̀ sípò. 13  “Bí ó bá jẹ́ pé nítorí sábáàtì, ìwọ yóò yí ẹsẹ̀ rẹ padà ní ti ṣíṣe àwọn ohun tí ìwọ ní inú dídùn sí ní ọjọ́ mímọ́ mi,+ tí ìwọ, ní tòótọ́, yóò sì pe sábáàtì ní inú dídùn kíkọyọyọ, ọjọ́ mímọ́ Jèhófà, èyí tí a ń ṣe lógo,+ tí ìwọ yóò sì ṣe é lógo ní tòótọ́ dípò títẹ̀lé àwọn ọ̀nà tìrẹ, dípò wíwá ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ àti sísọ ọ̀rọ̀ kan; 14  bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà,+ dájúdájú, èmi yóò mú kí o gun àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé;+ èmi yóò sì mú kí o jẹ nínú ohun ìní àjogúnbá Jékọ́bù baba ńlá rẹ,+ nítorí pé ẹnu Jèhófà ti sọ ọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé