Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 56:1-12

56  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ pa ìdájọ́ òdodo mọ́,+ kí ẹ sì máa ṣe ohun tí í ṣe òdodo.+ Nítorí pé ìgbàlà mi kù sí dẹ̀dẹ̀ kí ó wọlé wá,+ àti òdodo mi kí a ṣí i payá.+  Aláyọ̀ ni ẹni kíkú tí ń ṣe èyí,+ àti ọmọ aráyé tí ó rọ̀ mọ́ ọn,+ tí ń pa sábáàtì mọ́ kí ó má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́,+ tí ó sì ń pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kí ó má bàa ṣe búburú èyíkéyìí.+  Kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà má sì sọ pé,+ ‘Láìsí àní-àní, Jèhófà yóò pín mi níyà sí àwọn ènìyàn rẹ̀.’+ Kí ìwẹ̀fà+ má sì sọ pé, ‘Wò ó! Igi gbígbẹ ni mí.’”  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún àwọn ìwẹ̀fà tí ń pa àwọn sábáàtì mi mọ́, tí wọ́n sì ti yan ohun tí mo ní inú dídùn sí,+ tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi:+  “Àní èmi yóò fún wọn ní ohun ìránnilétí+ àti orúkọ+ ní ilé mi+ àti nínú àwọn ògiri mi, ohun tí ó sàn ju àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.+ Orúkọ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fún wọn,+ ọ̀kan tí a kì yóò ké kúrò.+  “Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó sì ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un+ àti láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà,+ láti lè di ìránṣẹ́ fún un, gbogbo àwọn tí ń pa sábáàtì mọ́ kí wọ́n má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi,+  dájúdájú, èmi yóò mú wọn wá sí òkè ńlá mímọ́+ mi pẹ̀lú, èmi yóò sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi.+ Odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ wọn àti àwọn ẹbọ+ wọn yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi.+ Nítorí pé ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà fún gbogbo ènìyàn.”+  Àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tí ń kó àwọn tí a fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọpọ̀,+ ni pé: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tirẹ̀ tí a ti kó jọpọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.”+  Gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá gbalasa, ẹ wá jẹun, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú igbó.+ 10  Afọ́jú ni àwọn olùṣọ́ rẹ̀.+ Kò sí ìkankan nínú wọn tí ó ṣàkíyèsí.+ Ajá tí kò lè fọhùn ni gbogbo wọn; wọn kò lè gbó,+ wọ́n ń mí hẹlẹ, wọ́n ń dùbúlẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti máa tòògbé.+ 11  Àní àwọn ajá tí ó le nínú ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọ̀kàn ni wọ́n;+ wọn kò ní ìtẹ́lọ́rùn rí.+ Wọ́n tún jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí kò mọ bí a ti ń lóye.+ Gbogbo wọn ti yí padà sí ọ̀nà ara wọn, olúkúlùkù fún èrè rẹ̀ aláìbá ìdájọ́ òdodo mu láti ojú ààlà+ tirẹ̀ pé: 12  “Ẹ wá! Kí n mu wáìnì díẹ̀; kí a sì mu ọtí tí ń pani ní àmuyó kẹ́ri.+ Ó dájú pé ọ̀la yóò rí gẹ́gẹ́ bí òní, yóò tóbi lọ́nà tí ó pọ̀ sí i gidigidi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé