Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 55:1-13

55  Kére o, gbogbo ẹ̀yin tí òùngbẹ ń gbẹ!+ Ẹ wá síbi omi.+ Àti ẹ̀yin tí kò ní owó! Ẹ wá, ẹ rà, kí ẹ sì jẹ.+ Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ wá, ẹ ra wáìnì+ àti wàrà,+ àní láìsí owó àti láìsí ìdíyelé.+  Èé ṣe tí ẹ fi ń san owó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ, èé sì ti ṣe tí làálàá yín jẹ́ fún ohun tí kì í yọrí sí ìtẹ́lọ́rùn?+ Ẹ fetí sí mi dáadáa, kí ẹ sì máa jẹ ohun tí ó dára,+ kí ọkàn yín sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀rá.+  Ẹ dẹ etí sílẹ̀,+ kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi.+ Ẹ fetí sílẹ̀, ọkàn yín yóò sì máa wà láàyè nìṣó,+ pẹ̀lú ìmúratán sì ni èmi yóò bá yín dá májẹ̀mú+ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ti àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Dáfídì, àwọn èyí tí ó ṣeé gbíyè lé.+  Wò ó! Mo ti fi í+ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè+ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí,+ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú+ àti aláṣẹ+ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.  Wò ó! Orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni ìwọ yóò pè,+ àwọn ará orílẹ̀-èdè tí kò sì mọ̀ ọ́ yóò sáré wá àní sọ́dọ̀ rẹ,+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ àti nítorí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ nítorí pé òun yóò ti ṣe ọ́ lẹ́wà.+  Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i.+ Ẹ pè é nígbà tí ó wà ní tòsí.+  Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,+ kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀;+ kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un,+ àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.+  “Nítorí pé ìrònú yín kì í ṣe ìrònú mi,+ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi kì í ṣe ọ̀nà yín,”+ ni àsọjáde Jèhófà.  “Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé,+ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,+ bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.+ 10  Nítorí pé gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde,+ tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́,+ 11  bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí.+ Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí,+ ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí,+ yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.+ 12  “Nítorí pé ayọ̀ yíyọ̀ ni ẹ ó fi jáde lọ,+ àlàáfíà sì ni a ó fi mú yín wọlé.+ Àwọn òkè ńláńlá àti àwọn òkè kéékèèké pàápàá yóò fi igbe ìdùnnú+ tújú ká níwájú yín, àní gbogbo àwọn igi pápá yóò pàtẹ́wọ́.+ 13  Dípò ìgbòrò ẹlẹ́gùn-ún, igi júnípà ni yóò hù jáde.+ Dípò èsìsì ajónilára, igi mátílì ni yóò hù jáde.+ Yóò sì di ohun lílókìkí fún Jèhófà,+ àmì fún àkókò tí ó lọ kánrin+ tí a kì yóò ké kúrò.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé