Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 54:1-17

54  “Fi ìdùnnú ké jáde, ìwọ àgàn tí kò bímọ!+ Fi igbe ìdùnnú tújú ká, kí o sì ké lọ́nà híhan gan-an-ran,+ ìwọ tí kò ní ìrora ìbímọ,+ nítorí àwọn ọmọ ẹni tí ó ti di ahoro pọ̀ níye ju àwọn ọmọ obìnrin tí ó ní ọkọ tí í ṣe olówó orí rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.  “Mú kí ibi àgọ́ rẹ túbọ̀ ní àyè gbígbòòrò.+ Kí wọ́n sì na àwọn aṣọ àgọ́ ibùgbé rẹ títóbilọ́lá. Má fawọ́ sẹ́yìn. Mú kí àwọn okùn àgọ́ rẹ gùn sí i, kí o sì mú àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ tìrẹ wọ̀nyẹn le.+  Nítorí pé ìwọ yóò ya sí ọ̀tún àti sí òsì,+ àwọn ọmọ tìrẹ yóò sì gba àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá,+ wọn yóò sì máa gbé àwọn ìlú ńlá tí ó ti di ahoro pàápàá.+  Má fòyà,+ nítorí pé a kì yóò kó ìtìjú bá ọ;+ má sì jẹ́ kí ìtẹ́lógo bá ọ, nítorí pé a kì yóò já ọ kulẹ̀.+ Nítorí pé ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ+ pàápàá, ẹ̀gàn ìgbà opó rẹ tí ń bá a nìṣó ni ìwọ kì yóò sì rántí mọ́.”  “Nítorí pé Olùṣẹ̀dá rẹ Atóbilọ́lá+ ni ọkọ olówó orí rẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀;+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sì ni Olùtúnnirà+ rẹ. Ọlọ́run gbogbo ilẹ̀ ayé ni a óò máa pè é.+  Nítorí pé Jèhófà pè ọ́ bí ẹni pé ìwọ jẹ́ aya tí a fi sílẹ̀ pátápátá, tí a sì pa ẹ̀mí rẹ̀ lára,+ àti gẹ́gẹ́ bí aya ìgbà èwe+ tí a wá já sílẹ̀,”+ ni Ọlọ́run rẹ wí.  “Ìṣẹ́jú díẹ̀ ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá,+ ṣùgbọ́n àánú ńláǹlà ni èmi yóò fi kó ọ jọpọ̀.+  Nínú àkúnya ìkannú ni mo fi ojú mi pa mọ́ fún ọ fún kìkì ìṣẹ́jú kan,+ ṣùgbọ́n inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fi ṣàánú fún ọ dájúdájú,”+ ni Jèhófà, Olùtúnnirà+ rẹ, wí.  “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ Nóà ni èyí rí sí mi.+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti búra pé omi Nóà kì yóò tún kọjá lórí ilẹ̀ ayé mọ́,+ bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra pé dájúdájú, ìkannú mi kì yóò ru sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí lọ́nà mímúná.+ 10  Nítorí pé a lè ṣí àwọn òkè ńláńlá pàápàá kúrò, àní àwọn òkè kéékèèké sì lè ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,+ ṣùgbọ́n inú rere mi onífẹ̀ẹ́ ni a kì yóò mú kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+ bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àlàáfíà mi kì yóò ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,”+ ni Jèhófà, Ẹni tí ó ṣàánú fún ọ,+ wí. 11  “Ìwọ obìnrin tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,+ tí ìjì líle ń bì síwá-sẹ́yìn,+ tí a kò tù nínú,+ kíyè sí i, èmi yóò fi àpòrọ́ erùpẹ̀ líle mọ àwọn òkúta rẹ,+ èmi yóò sì fi sàfáyà+ fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀+ dájúdájú. 12  Òkúta rúbì ni èmi yóò sì fi ṣe odi orí òrùlé rẹ, òkúta oníná pípọ́n yòò ni èmi yóò sì fi ṣe àwọn ẹnubodè rẹ,+ àwọn òkúta mèremère ni èmi yóò sì fi ṣe gbogbo ààlà rẹ. 13  Gbogbo ọmọ+ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.+ 14  A ó fìdí rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òdodo.+ Ìwọ yóò jìnnà réré sí ìnilára+—nítorí tí ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìkankan—àti sí ohunkóhun tí ń jáni láyà, nítorí pé kì yóò sún mọ́ ọ.+ 15  Bí ẹnikẹ́ni bá gbéjà kò ọ́ pẹ́nrẹ́n, kí yóò jẹ́ nípasẹ̀ àwọn àṣẹ ìtọ́ni mi.+ Ẹnì yòówù tí ó bá gbéjà kò ọ́ yóò ṣubú àní ní tìtorí rẹ.”+ 16  “Wò ó! Èmi fúnra mi ni ó dá oníṣẹ́ ọnà, ẹni tí ń fẹ́ atẹ́gùn+ sí iná èédú,+ tí ó sì ń mú ohun ìjà jáde wá gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà rẹ̀. Èmi fúnra mi, pẹ̀lú, ni ó dá apanirun+ fún iṣẹ́ ìfọ́bàjẹ́. 17  Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere,+ ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi.+ Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà,+ ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọ́n ti wá,” ni àsọjáde Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé