Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 53:1-12

53  Ta ni ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a gbọ́?+ Ní ti apá Jèhófà,+ ta sì ni a ti ṣí i payá fún?+  Yóò sì jáde wá bí ẹ̀ka igi+ níwájú ẹni, àti bí gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ aláìlómi. Kò ní ìdúró onídàńsáákì, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ọlá ńlá kankan;+ nígbà tí a bá sì rí i, kò ní ìrísí tí a ó fi ní ìfẹ́-ọkàn sí i.+  A tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwọn ènìyàn sì yẹra fún un,+ ọkùnrin tí a pète fún ìrora àti fún dídi ojúlùmọ̀ àìsàn.+ Ó sì dà bí ìfojú-ẹni-pamọ́ sí wa.+ A tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwa sì kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan.+  Lóòótọ́, àwọn àìsàn wa ni òun fúnra rẹ̀ gbé;+ àti pé ní ti ìrora wa, ó rù wọ́n.+ Ṣùgbọ́n àwa fúnra wa kà á sí ẹni tí ìyọnu bá,+ ẹni tí Ọlọ́run kọlù,+ tí ó sì ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́.+  Ṣùgbọ́n a gún un+ nítorí ìrélànàkọjá wa;+ a ń tẹ̀ ẹ́ rẹ́ nítorí àwọn ìṣìnà wa.+ Ìnàlẹ́gba tí a pète fún àlàáfíà wa ń bẹ lára rẹ̀,+ àti nítorí àwọn ọgbẹ́+ rẹ̀ ni ìmúniláradá fi wà fún wa.+  Gbogbo wa ti rìn gbéregbère bí àgùntàn;+ olúkúlùkù wa ni ó ti yíjú sí bíbá ọ̀nà ara rẹ̀ lọ; Jèhófà alára sì ti mú kí ìṣìnà gbogbo wa ṣalábàápàdé ẹni yẹn.+  A ni ín lára dé góńgó,+ ó sì jẹ́ kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́;+ síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀. A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa;+ àti bí abo àgùntàn tí ó yadi níwájú àwọn olùrẹ́run rẹ̀, òun kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀ pẹ̀lú.+  Nítorí ìkálọ́wọ́kò àti ìdájọ́ ni a fi mú un lọ;+ ta sì ni yóò dàníyàn nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀?+ Nítorí pé a yà á nípa+ sí ilẹ̀ àwọn alààyè.+ Nítorí ìrélànàkọjá+ àwọn ènìyàn mi ni ó fi gba ọgbẹ́.+  Òun yóò sì ṣe ibi ìsìnkú rẹ̀ àní pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú,+ àti pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ikú rẹ̀,+ láìka òtítọ́ náà sí pé kò hu ìwà ipá kankan,+ bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹ̀tàn kankan ní ẹnu rẹ̀.+ 10  Ṣùgbọ́n Jèhófà tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí títẹ̀ ẹ́ rẹ́;+ ó mú kí ó ṣàìsàn.+ Bí ìwọ yóò bá fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi,+ òun yóò rí àwọn ọmọ rẹ̀,+ yóò mú ọjọ́ rẹ̀ gùn,+ ohun tí Jèhófà ní inú dídùn+ sí yóò sì kẹ́sẹ járí ní ọwọ́ rẹ̀.+ 11  Nítorí ìdààmú ọkàn rẹ̀, òun yóò wò,+ òun yóò ní ìtẹ́lọ́rùn.+ Nípasẹ̀ ìmọ̀ rẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi,+ olódodo, yóò fi mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn;+ àwọn ìṣìnà wọn ni òun fúnra rẹ̀ yóò sì rù.+ 12  Fún ìdí yẹn, èmi yóò fún un ní ìpín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀,+ tòun ti àwọn alágbára ńlá ni yóò sì jùmọ̀ pín ohun ìfiṣèjẹ,+ nítorí òtítọ́ náà pé ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú,+ àwọn olùrélànàkọjá ni a sì kà á mọ́;+ òun fúnra rẹ̀ sì ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn pàápàá,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣìpẹ̀ nítorí àwọn olùrélànàkọjá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé