Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 52:1-15

52  Jí, jí, gbé okun rẹ wọ̀,+ ìwọ Síónì! Gbé ẹ̀wù rẹ ẹlẹ́wà wọ̀,+ ìwọ Jerúsálẹ́mù, ìlú ńlá mímọ́!+ Nítorí pé aláìdádọ̀dọ́ àti aláìmọ́ kì yóò tún wá sínú rẹ mọ́.+  Gbọn ekuru kúrò lára rẹ,+ dìde, mú ìjókòó, ìwọ Jerúsálẹ́mù. Tú ọ̀já ọrùn rẹ fún ara rẹ, ìwọ òǹdè ọmọbìnrin Síónì.+  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Lọ́fẹ̀ẹ́ ni a tà yín,+ láìsan owó sì ni a óò tún yín rà.”+  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Íjíbítì ni àwọn ènìyàn mi sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ìgbà àkọ́kọ́ láti máa ṣe àtìpó níbẹ̀;+ láìnídìí, Ásíríà, ní tirẹ̀, sì ni wọ́n lára.”  “Wàyí o, kí ni mo nífẹ̀ẹ́ sí níhìn-ín?” ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí pé lọfẹ̀ẹ́ ni a kó àwọn ènìyàn mi.+ Àwọn ẹni náà tí ń ṣàkóso lé wọn lórí ń hu ṣáá,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “nígbà gbogbo, láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, sì ni a ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ mi.+  Fún ìdí yẹn, àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi,+ àní fún ìdí yẹn ní ọjọ́ yẹn, nítorí pé èmi ni Ẹni tí ń sọ̀rọ̀.+ Wò ó! Èmi ni.”  Ẹsẹ̀+ ẹni tí ń mú ìhìn rere+ wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o, ẹni tí ń kéde àlàáfíà+ fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá,+ ẹni tí ń kéde ìgbàlà+ fáyé gbọ́, ẹni tí ń sọ fún Síónì pé: “Ọlọ́run rẹ ti di ọba!”+  Fetí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́+ rẹ ti gbé ohùn wọn sókè.+ Ní ìsopọ̀ṣọ̀kan ni wọ́n ń fi ìdùnnú ké jáde; nítorí pé ojú ko ojú+ ni wọn yóò rí i nígbà tí Jèhófà bá kó Síónì jọ padà.+  Ẹ tújú ká, ẹ fi ìdùnnú ké jáde ní ìsopọ̀ṣọ̀kan, ẹ̀yin ibi ìparundahoro Jerúsálẹ́mù,+ nítorí pé Jèhófà ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú;+ ó ti tún Jerúsálẹ́mù rà.+ 10  Jèhófà ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+ gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.+ 11  Ẹ yí padà, ẹ yí padà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀,+ ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan;+ ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀,+ ẹ wẹ ara yín mọ́, ẹ̀yin tí ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà.+ 12  Nítorí pé ẹ kì yóò jáde lọ nínú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì, ẹ kì yóò sì lọ nínú fífẹsẹ̀fẹ.+ Nítorí pé Jèhófà yóò máa lọ àní níwájú yín,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni yóò sì jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ìhà ẹ̀yìn yín.+ 13  Wò ó! Ìránṣẹ́ mi+ yóò fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà.+ Yóò wà ní ipò gíga, a ó sì gbé e lékè dájúdájú, a ó sì gbé e ga gidigidi.+ 14  Títí dé àyè tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi wò ó sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì+—ìbàlẹ́wàjẹ́ náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ní ti ìrísí+ rẹ̀ tí ó fi ju ti ọkùnrin mìíràn àti ní ti ìdúró rẹ̀+ onídàńsáákì tí ó fi ju ti àwọn ọmọ aráyé— 15  bákan náà, òun yóò mú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ta gìrì.+ Àwọn ọba yóò pa ẹnu wọn dé sí i,+ nítorí pé ohun tí a kò tíì ròyìn lẹ́sẹẹsẹ fún wọn ni wọn yóò rí ní tòótọ́, ohun tí wọn kò tíì gbọ́ sì ni wọn yóò yí ìrònú wọn sí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé