Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 51:1-23

51  “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn tí ń lépa òdodo,+ ẹ̀yin tí ń wá ọ̀nà láti rí Jèhófà.+ Ẹ yíjú sí àpáta+ tí a ti gbẹ́ yín jáde, àti ihò kòtò tí a ti wà yín jáde.  Ẹ yíjú sí Ábúráhámù+ baba yín+ àti Sárà+ tí ó fi ìrora ìbímọ bí yín ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nítorí pé ọ̀kan ṣoṣo ni òun nígbà tí mo pè é,+ mo sì tẹ̀ síwájú láti bù kún un, mo sì sọ ọ́ di púpọ̀.+  Nítorí ó dájú pé Jèhófà yóò tu Síónì nínú.+ Ó dájú pé òun yóò tu gbogbo ibi ìparundahoro rẹ̀ nínú,+ òun yóò sì ṣe aginjù rẹ̀ bí Édẹ́nì+ àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ rẹ̀ bí ọgbà Jèhófà.+ Ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ pàápàá ni a óò rí nínú rẹ̀, ìdúpẹ́ àti ohùn orin atunilára.+  “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; àti ìwọ àwùjọ orílẹ̀-èdè mi,+ fi etí sí mi. Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ mi, àní òfin kan yóò jáde lọ,+ ìpinnu ìdájọ́ mi ni èmi yóò sì mú kí ó fìdí kalẹ̀ àní gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn.+  Òdodo mi sún mọ́lé.+ Ìgbàlà+ mi yóò jáde lọ dájúdájú, apá mi yóò sì dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.+ Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò fi ìrètí wọn sí,+ apá mi sì ni wọn yóò dúró dè.+  “Ẹ gbé ojú yín sókè sí ọ̀run,+ kí ẹ sì wo ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Nítorí pé àní ọ̀run ni a óò fọ́n ká ní wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí èéfín,+ ilẹ̀ ayé yóò sì gbó bí ẹ̀wù,+ àwọn olùgbé rẹ̀ pàápàá yóò sì kú bí kòkòrò kantíkantí lásán-làsàn. Ṣùgbọ́n ní ti ìgbàlà mi, yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ a kì yóò sì fọ́ òdodo mi túútúú.+  “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ó mọ òdodo, ẹ̀yin ènìyàn tí òfin mi wà ní ọkàn-àyà yín.+ Ẹ má fòyà ẹ̀gàn àwọn ẹni kíkú, ẹ má sì jẹ́ kí a kó ìpayà bá yín kìkì nítorí ọ̀rọ̀ èébú wọn.+  Nítorí pé òólá yóò jẹ wọ́n tán bí ẹni pé ẹ̀wù ni wọ́n, òólá aṣọ yóò sì jẹ wọ́n tán bí irun àgùntàn.+ Ṣùgbọ́n ní ti òdodo mi, yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti ìgbàlà mi, fún àwọn ìran tí kò níye.”+  Jí, jí, gbé okun wọ̀,+ ìwọ apá Jèhófà!+ Jí gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí ìgbà àwọn ìran tí ó ti kọjá sẹ́yìn tipẹ́tipẹ́.+ Ìwọ ha kọ́ ni ó fọ́ Ráhábù+ sí wẹ́wẹ́, tí ó gún ẹran ńlá abàmì inú òkun+ ní àgúnyọ? 10  Ìwọ ha kọ́ ni ó mú òkun gbẹ, omi alagbalúgbú ibú?+ Ẹni tí ó sọ àwọn ibú òkun di ọ̀nà fún àwọn tí a tún rà láti gbà sọdá?+ 11  Nígbà náà ni àwọn tí Jèhófà tún rà padà yóò padà, tí wọn yóò sì wá sí Síónì ti àwọn ti igbe ìdùnnú,+ ayọ̀ yíyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin yóò sì wà ní orí wọn.+ Ọwọ́ wọn yóò tẹ ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀.+ Ṣe ni ẹ̀dùn-ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn yóò fò lọ.+ 12  “Èmi—èmi fúnra mi ni Ẹni tí ń tù yín nínú.+ “Ta ni ọ́ tí ìwọ yóò fi máa fòyà ẹni kíkú tí yóò kú,+ àti ọmọ aráyé tí a ó sọ di koríko tútù lásán-làsàn?+ 13  Tí ìwọ yóò sì fi gbàgbé Jèhófà Olùṣẹ̀dá rẹ,+ Ẹni tí ó na ọ̀run,+ tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,+ tí ìwọ fi wà nínú ìbẹ̀rùbojo nígbà gbogbo láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní tìtorí ìhónú ẹni tí ó há ọ mọ́,+ bí ẹni pé ó ti múra tán pátápátá láti run ọ́?+ Ìhónú ẹni tí ó há ọ mọ́ dà?+ 14  “Dájúdájú, ẹni tí ó tẹ̀ ba pẹ̀lú àwọn ẹ̀wọ̀n ni a ó fi ìyára kánkán tú,+ kí ó má bàa lọ nínú ikú sí kòtò,+ kí ó má sì ṣaláìní oúnjẹ.+ 15  “Ṣùgbọ́n èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń ru òkun sókè kí ìgbì rẹ̀ lè di aláriwo líle.+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+ 16  Èmi yóò sì fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ,+ èmi yóò sì fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́ dájúdájú,+ kí n lè gbin ọ̀run,+ kí n sì lè fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,+ kí n sì wí fún Síónì pé, ‘Ìwọ ni ènìyàn mi.’+ 17  “Ta jí, ta jí, dìde, ìwọ Jerúsálẹ́mù,+ ìwọ tí o ti mu ife ìhónú+ Jèhófà ní ọwọ́ rẹ̀. Gàásì náà, ife tí ń fa títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́, ni o ti mu, ni o ti fà gbẹ.+ 18  Kò sí ìkankan lára gbogbo ọmọ+ tí ó bí tí ó ń darí rẹ̀, kò sì sí ìkankan lára gbogbo ọmọ tí ó tọ́ dàgbà tí ó ń di ọwọ́ rẹ̀ mú.+ 19  Ohun méjì wọnnì ni ó ṣẹlẹ̀ sí ọ.+ Ta ni yóò bá ọ kẹ́dùn?+ Ìfiṣèjẹ àti ìwópalẹ̀, àti ebi àti idà!+ Ta ni yóò tù ọ́ nínú?+ 20  Àwọn ọmọ rẹ ti dákú lọ gbári.+ Wọ́n ti dùbúlẹ̀ sí ìkòríta gbogbo ojú pópó bí àgùntàn ìgbẹ́ tí ó wà nínú àwọ̀n,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó kún fún ìhónú Jèhófà,+ ìbáwí mímúná Ọlọ́run rẹ.”+ 21  Nítorí náà, jọ̀wọ́, fetí sí èyí, ìwọ obìnrin+ tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, tí ó sì ti mu àmupara, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe pẹ̀lú wáìnì.+ 22  Èyí ni ohun tí Olúwa rẹ, Jèhófà, àní Ọlọ́run rẹ, tí ń báni fà á+ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ wí: “Wò ó! Ṣe ni èmi yóò gba ife tí ń fa títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́+ kúrò lọ́wọ́ rẹ. Gàásì náà, ife ìhónú mi—ìwọ kì yóò tún mu ún mọ́.+ 23  Ṣe ni èmi yóò fi í sí ọwọ́ àwọn tí ń sún ọ bínú,+ àwọn tí ó sọ fún ọkàn rẹ pé, ‘Tẹ̀ ba kí a lè sọdá,’ tí ó fi jẹ́ pé ṣe ni o máa ń ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀, àti bí ojú pópó fún àwọn tí ń sọdá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé