Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 5:1-30

5  Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n kọrin fún olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, orin kan nípa ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.+ Ọgbà àjàrà kan wà tí olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n ní sí ẹ̀gbẹ́ òkè kékeré eléso.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí walẹ̀ rẹ̀, ó sì kó àwọn òkúta rẹ̀ kúrò, ó sì gbin ààyò àjàrà pupa sínú rẹ̀, ó sì kọ́ ilé gogoro sí àárín rẹ̀.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó gbẹ́ ibi ìfúntí wáìnì sínú rẹ̀.+ Ó sì ń retí pé kí ó so èso àjàrà,+ ṣùgbọ́n ó so èso àjàrà ìgbẹ́+ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.  “Wàyí o, ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù àti ẹ̀yin ènìyàn Júdà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ọgbà àjàrà mi.+  Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀?+ Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé mo ń retí pé kí ó so èso àjàrà, ṣùgbọ́n tí ó so èso àjàrà ìgbẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?  Wàyí o, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí èmi yóò ṣe sí ọgbà àjàrà mi di mímọ̀ fún yín: Ìmúkúrò ọgbà ààbò+ rẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀, yóò sì di sísun kanlẹ̀.+ Ìwólulẹ̀ ògiri òkúta rẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀, yóò sì di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀.+  Èmi yóò sì sọ ọ́ di ohun tí a pa run.+ A kì yóò rẹ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò fi ọkọ́ ro ó.+ Yóò sì hu igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún àti èpò;+ èmi yóò sì gbé àṣẹ kalẹ̀ fún àwọsánmà pé kí ó má ṣe mú kí òjò gbára jọ kí ó sì rọ̀ sórí rẹ̀.+  Nítorí ọgbà àjàrà+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni ilé Ísírẹ́lì, àwọn ọkùnrin Júdà sì ni oko ọ̀gbìn tí òun ní ìfẹ́ni fún.+ Ó sì ń retí láti rí ìdájọ́,+ ṣùgbọ́n, wò ó! rírú òfin ni ó rí; ó ń retí láti rí òdodo, ṣùgbọ́n, wò ó! igbe ẹkún+ ni ó rí.”  Ègbé ni fún àwọn tí ń so ilé pọ̀ mọ́ ilé,+ àti àwọn tí ń fi pápá kún pápá títí kò fi sí àyè mọ́,+ a sì ti mú kí ẹ máa dá gbé ní àárín ilẹ̀ náà!  Ní etí mi, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun [ti búra pé] ọ̀pọ̀ ilé, bí wọ́n tilẹ̀ tóbi, tí wọ́n sì dára, yóò di ohun ìyàlẹ́nu pátápátá, láìsí olùgbé.+ 10  Nítorí pé, àní sarè mẹ́wàá+ ọgbà àjàrà yóò mú kìkì òṣùwọ̀n báàfù+ kan ṣoṣo jáde, àní irúgbìn tí ó jẹ́ òṣùwọ̀n hómérì kan yóò sì mú kìkì òṣùwọ̀n eéfà+ kan jáde. 11  Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kí wọ́n lè máa wá kìkì ọtí tí ń pani+ kiri, àwọn tí ń dúró pẹ́ títí di òkùnkùn alẹ́ tí ó fi jẹ́ pé wáìnì mú wọn gbiná!+ 12  Háàpù àti ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì àti fèrè, àti wáìnì sì ní láti wà níbi àsè wọn;+ ṣùgbọ́n ìgbòkègbodò Jèhófà ni wọn kò bojú wò, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sì ni wọn kò rí.+ 13  Nítorí náà, àwọn ènìyàn mi yóò ní láti lọ sí ìgbèkùn nítorí àìní ìmọ̀;+ ògo wọn yóò sì jẹ́ àwọn ènìyàn tí ìyàn ti hàn léèmọ̀,+ ogunlọ́gọ̀ wọn yóò sì gbẹ hán-ún hán-ún lọ́wọ́ òùngbẹ.+ 14  Nítorí náà, Ṣìọ́ọ̀lù ti sọ ọkàn ara rẹ̀ di aláyè gbígbòòrò, ó sì ti ṣí ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu ré kọjá ààlà;+ ohun tí ó jẹ́ ọlọ́lá ńlá nínú rẹ̀, àti ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀ rẹ̀ àti ẹni aláyọ̀ ńláǹlà, yóò sì sọ̀ kalẹ̀ sínú rẹ̀ dájúdájú.+ 15  Ará ayé yóò sì tẹrí ba, ènìyàn yóò sì di rírẹ̀sílẹ̀, kódà ojú àwọn ẹni gíga yóò di rírẹ̀sílẹ̀.+ 16  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì di gíga nípasẹ̀ ìdájọ́,+ Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni Mímọ́,+ yóò sì sọ ara rẹ̀ di mímọ́ dájúdájú nípasẹ̀ òdodo.+ 17  Àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn yóò sì máa jẹko ní ti gidi bí ẹni pé nínú pápá ìjẹko wọn; àwọn ibi ahoro ti àwọn ẹran tí a bọ́ dáadáa sì ni àwọn àtìpó yóò jẹ.+ 18  Ègbé ni fún àwọn tí ń fi àwọn ìjàrá àìsọ òtítọ́ fa ìṣìnà, tí wọ́n sì ń fi ohun tí a lè pè ní àwọn okùn kẹ̀kẹ́ fa ẹ̀ṣẹ̀;+ 19  àwọn tí ń sọ pé: “Kí iṣẹ́ rẹ̀ ṣe kánkán; kí ó wá kíákíá, kí a lè rí i; kí ìmọ̀ràn Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sún mọ́ tòsí, kí ó sì wá, kí a lè mọ̀ ọ́n!”+ 20  Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára,+ àwọn tí ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn, àwọn tí ń fi ohun kíkorò dípò dídùn àti ohun dídùn dípò kíkorò!+ 21  Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n ní ojú ara wọn, tí wọ́n sì jẹ́ olóye àní ní iwájú àwọn fúnra wọn!+ 22  Ègbé ni fún àwọn tí ó jẹ́ alágbára ńlá nínú mímu wáìnì, àti fún àwọn ènìyàn tí ó ní ìmí fún ṣíṣe àdàlù ọtí tí ń pani,+ 23  àwọn tí ń pe ẹni burúkú ní olódodo ní tìtorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+ tí wọ́n sì gba àní òdodo olódodo kúrò lọ́wọ́ rẹ̀!+ 24  Nítorí náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ti ń jẹ àgékù pòròpórò+ run, tí koríko gbígbẹ lásán-làsàn sì máa ń rá sínú ọwọ́ iná, gbòǹgbò ìdí wọn gan-an yóò dà bí òórùn dídìkàsì,+ ìtànná wọn pàápàá yóò gòkè lọ gẹ́gẹ́ bí erukutu, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ àsọjáde Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sì ni wọn kò bọ̀wọ̀ fún.+ 25  Ìdí nìyẹn tí ìbínú Jèhófà fi gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ̀, òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí wọn, yóò sì kọlù wọ́n.+ Ṣìbáṣìbo yóò sì bá àwọn òkè ńlá,+ òkú wọn yóò sì dà bí ohun àkódànù ní àárín ojú pópó.+ Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ ṣì nà jáde síbẹ̀. 26  Ó sì ti gbé àmì àfiyèsí sókè sí orílẹ̀-èdè ńlá kan tí ó jìnnà réré,+ ó sì ti súfèé sí i ní ìkángun ilẹ̀ ayé;+ sì wò ó! pẹ̀lú ìṣekánkán ni yóò wọlé wá pẹ̀lú ìyára.+ 27  Kò sí ẹni tí ó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ń kọsẹ̀ lára wọn. Kò sí ẹni tí ń tòògbé, kò sì sí ẹni tí ń sùn. Ìgbànú tí ń bẹ ní abẹ́nú wọn ni a kì yóò sì tú, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò já okùn sálúbàtà wọn sí méjì; 28  nítorí pé ọfà wọn mú, gbogbo ọrun wọn sì wà ní fífà.+ Àní pátákò àwọn ẹṣin wọn ni a ó kà sí akọ òkúta,+ àgbá kẹ̀kẹ́ wọn ni a ó sì kà sí ẹ̀fúùfù oníjì.+ 29  Ìkéramúramù wọn dà bí ti kìnnìún, wọ́n sì ń ké ramúramù bí àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀.+ Wọn yóò sì kùn hùn-ùn, wọn yóò sì gbá ẹran ọdẹ mú, wọn yóò sì gbé e lọ láìséwu, kì yóò sì sí olùdáǹdè.+ 30  Wọn yóò sì kùn hùn-un lórí rẹ̀ ní ọjọ́ yẹn bí híhó òkun.+ Ènìyàn yóò sì tẹjú mọ́ ilẹ̀ náà ní ti tòótọ́, sì wò ó! òkùnkùn tí ń kó wàhálà báni+ ni ó wà; ìmọ́lẹ̀ pàápàá ti ṣókùnkùn nítorí àwọn ohun tí ń kán sí i lórí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé