Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 49:1-26

49  Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù,+ kí ẹ sì fiyè sílẹ̀, ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré.+ Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó pè mí+ àní láti inú ikùn wá.+ Láti ìhà inú ìyá mi ni ó ti mẹ́nu kan orúkọ mi.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe ẹnu mi bí idà mímú.+ Inú òjìji+ ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi mí pa mọ́ sí.+ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sọ mí di ọfà dídán. Ó tọ́jú mi pa mọ́ sínú apó tirẹ̀.  Ó sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Ìwọ, Ísírẹ́lì,+ ni ìránṣẹ́ mi, ìwọ ẹni tí èmi yóò fi ẹwà mi hàn nínú rẹ̀.”+  Ṣùgbọ́n ní tèmi, mo wí pé: “Lásán ni mo ṣe làálàá.+ Òtúbáńtẹ́ àti asán ni mo ti lo gbogbo agbára mi fún.+ Lóòótọ́, ìdájọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ Jèhófà,+ owó ọ̀yà mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.”+  Wàyí o, Jèhófà, Ẹni tí ó ṣẹ̀dá mi láti inú ikùn wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ tirẹ̀,+ ti sọ pé kí n mú Jékọ́bù padà wá sọ́dọ̀ òun,+ kí a lè kó Ísírẹ́lì pàápàá jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.+ A ó sì ṣe mí lógo lójú Jèhófà, Ọlọ́run mi yóò sì di okun mi.  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ó ti ré kọjá ọ̀ràn tí kò tó nǹkan, pé o di ìránṣẹ́ mi láti gbé àwọn ẹ̀yà Jékọ́bù dìde, kí o sì mú àwọn tí a fi ìṣọ́ ṣọ́ lára Ísírẹ́lì padà wá;+ pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ti pèsè rẹ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ kí ìgbàlà mi lè wá títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”+  Èyí ni ohun tí Jèhófà, Olùtúnnirà Ísírẹ́lì,+ Ẹni Mímọ́ rẹ̀, wí fún ẹni tí a tẹ́ńbẹ́lú nínú ọkàn,+ fún ẹni tí orílẹ̀-èdè ń ṣe họ́ọ̀ sí,+ fún ìránṣẹ́ àwọn olùṣàkóso:+ “Àwọn ọba tìkára wọn yóò rí i, wọn yóò sì dìde dájúdájú,+ àti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò sì tẹrí ba, nítorí Jèhófà, ẹni tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, ẹni tí ó yàn ọ́.”+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo ti dá ọ lóhùn,+ àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ti ràn ọ́ lọ́wọ́;+ mo sì ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ kí n lè pèsè rẹ gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,+ láti tún ilẹ̀ náà ṣe,+ láti mú kí a gba àwọn ohun ìní àjogúnbá+ tí ó ti di ahoro padà,  láti sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n+ pé, ‘Ẹ jáde wá!’+ fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn+ pé, ‘Ẹ fi ara yín hàn!’+ Ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ni wọn yóò ti máa jẹ koríko, orí gbogbo ipa ọ̀nà àrìnkúnná sì ni wọn yóò ti máa jẹ̀.+ 10  Ebi kì yóò pa wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,+ tàbí kí ooru amóhungbẹ hán-ún hán-ún mú wọn tàbí kí oòrùn pa wọ́n.+ Nítorí pé Ẹni tí ń ṣe ojú àánú sí wọn yóò ṣamọ̀nà wọn,+ ẹ̀bá àwọn ìsun omi sì ni yóò darí wọn lọ.+ 11  Ṣe ni èmi yóò sọ gbogbo òkè ńlá mi di ọ̀nà, àwọn òpópó mi pàápàá yóò sì wà ní ibi gíga.+ 12  Wò ó! Àwọn wọ̀nyí yóò wá àní láti ibi jíjìnnàréré,+ sì wò ó! àwọn wọ̀nyí láti àríwá+ àti láti ìwọ̀-oòrùn,+ àti àwọn wọ̀nyí láti ilẹ̀ Sínímù.” 13  Ẹ kígbe ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run,+ sì kún fún ìdùnnú, ìwọ ilẹ̀ ayé.+ Kí àwọn òkè ńlá fi igbe ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tújú ká.+ Nítorí pé Jèhófà ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,+ ó sì fi ojú àánú hàn sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+ 14  Ṣùgbọ́n Síónì ń wí ṣáá pé: “Jèhófà ti fi mí sílẹ̀,+ Jèhófà tìkára rẹ̀ sì ti gbàgbé mi.”+ 15  Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀?+ Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé,+ síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.+ 16  Wò ó! Àtẹ́lẹwọ́ mi ni mo fín ọ sí.+ Àwọn ògiri rẹ wà ní iwájú mi nígbà gbogbo.+ 17  Àwọn ọmọ rẹ ti ṣe wéré. Àwọn ẹni náà tí ń ya ọ́ lulẹ̀, tí wọ́n sì ń pa ọ́ run di ahoro yóò jáde lọ àní kúrò lọ́dọ̀ rẹ. 18  Gbé ojú rẹ sókè yí ká, kí o sì wò. A ti kó gbogbo wọn jọpọ̀.+ Wọ́n ti wá sọ́dọ̀ rẹ. “Bí mo ti ń bẹ,” ni àsọjáde Jèhófà,+ “gbogbo wọn ni ìwọ yóò fi wọ ara rẹ gẹ́gẹ́ bí wíwọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́, ìwọ yóò sì dè wọ́n mọ́ ara rẹ bí ìyàwó.+ 19  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ibi ìparundahoro rẹ àti àwọn ibi ahoro rẹ àti ilẹ̀ àwókù rẹ ń bẹ,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nísinsìnyí ìwọ ti há jù fún gbígbé, tí àwọn tí ó gbé ọ mì gbìnrín sì jìnnà réré,+ 20  síbẹ̀, ní etí rẹ, àwọn ọmọ ìgbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ọ́+ yóò wí pé, ‘Àyè yìí ti há jù fún mi.+ Wá àyè fún mi, tí èmi yóò máa gbé.’+ 21  Ó dájú pé ìwọ yóò sọ nínú ọkàn-àyà rẹ pé, ‘Ta ni ó bá mi bí àwọn wọ̀nyí, níwọ̀n bí mo ti jẹ́ obìnrin tí ó ṣòfò àwọn ọmọ, tí ó sì jẹ́ aláìlè-méso-jáde, tí ó lọ sí ìgbèkùn, tí a sì mú ní ẹlẹ́wọ̀n?+ Ní ti àwọn wọ̀nyí, ta ni ó tọ́ wọn dàgbà?+ Wò ó! A ti fi mí sílẹ̀ sẹ́yìn ní èmi nìkan.+ Àwọn wọ̀nyí—ibo ni wọ́n ti wà?’”+ 22  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Wò ó! Èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè, àní sí àwọn orílẹ̀-èdè,+ èmi yóò sì gbé àmì àfiyèsí mi sókè sí àwọn ènìyàn.+ Wọn yóò sì gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá ní oókan àyà, èjìká sì ni wọn yóò gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ sí.+ 23  Àwọn ọba yóò sì di olùtọ́jú fún ọ,+ àwọn ọmọ aládé wọn obìnrin yóò sì di obìnrin olùṣètọ́jú fún ọ. Pẹ̀lú ìdojúbolẹ̀ ni wọn yóò sì tẹrí ba fún ọ,+ ekuru ẹsẹ̀ rẹ ni wọn yóò sì lá;+ ìwọ yóò ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, ẹni tí ó jẹ́ pé àwọn tí ó ní ìrètí nínú mi ni ojú kì yóò tì.”+ 24  A ha lè kó àwọn tí alágbára ńlá ti kó tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀ bí,+ tàbí kẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn òǹdè ti afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ha lè sá àsálà bí?+ 25  Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Àní ẹgbẹ́ àwọn òǹdè ti alágbára ńlá ni a óò kó lọ,+ àwọn tí a sì ti kó tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ pàápàá yóò sá àsálà.+ Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń bá ọ fà á, èmi tìkára mi yóò bá a fà á,+ àwọn ọmọ rẹ ni èmi fúnra mi yóò sì gbà là.+ 26  Ṣe ni èmi yóò mú kí àwọn tí ń ṣe ọ́ níkà jẹ ẹran ara wọn; àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó mu wáìnì dídùn, wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmupara. Gbogbo ẹran ara yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi, Jèhófà,+ ni Olùgbàlà+ rẹ àti Olùtúnnirà+ rẹ, Ẹni Alágbára Jékọ́bù.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé