Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 48:1-22

48  Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù, ẹ̀yin tí ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín+ àti ẹ̀yin tí ẹ jáde wá láti inú omi Júdà gan-an,+ ẹ̀yin tí ń fi orúkọ Jèhófà búra,+ tí ẹ sì ń mẹ́nu kan Ọlọ́run Ísírẹ́lì pàápàá,+ tí kì í ṣe ní òtítọ́, tí kì í sì í ṣe ní òdodo.+  Nítorí wọ́n ti pe ara wọn ní ará ìlú ńlá mímọ́ náà,+ wọ́n sì ti gbé ara wọn lé Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+  “Àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ni mo ti sọ àní láti ìgbà yẹn, ẹnu mi ni wọ́n sì ti jáde lọ, mo sì ń mú kí wọ́n di gbígbọ́.+ Lójijì, mo gbé ìgbésẹ̀, àwọn nǹkan náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé wá.+  Nítorí mímọ̀ tí mo mọ̀ pé ìwọ jẹ́ ẹni líle+ àti pé ọrùn rẹ jẹ́ fọ́nrán iṣan irin+ àti pé iwájú orí rẹ jẹ́ bàbà,+  pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ń sọ fún ọ ṣáá láti ìgbà yẹn. Kí ó tó di pé ó wọlé wá, mo mú kí o gbọ́ ọ,+ kí o má bàa sọ pé, ‘Òrìṣà mi ni ó ṣe wọ́n, àti pé ère gbígbẹ́ mi àti ère dídà mi ni ó pàṣẹ wọn.’+  Ìwọ ti gbọ́.+ Wo gbogbo rẹ̀.+ Ní tiyín, ẹ kì yóò ha sọ ọ́ bí?+ Mo ti jẹ́ kí o gbọ́ àwọn nǹkan tuntun láti àkókò yìí, àní àwọn nǹkan tí a fi pa mọ́, tí o kò mọ̀.+  Àkókò yìí ni a óò dá wọn, kì í sì í ṣe láti ìgbà yẹn, àní àwọn nǹkan tí o kò gbọ́ ṣáájú òní, kí o má bàa sọ pé, ‘Wò ó! Mo ti mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀.’+  “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ kò gbọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò mọ̀, bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ kò là láti ìgbà yẹn wá. Nítorí mo mọ̀ dunjú pé ṣe ni o ń ṣe àdàkàdekè ṣáá,+ àti pé ‘olùrélànàkọjá láti inú ikùn wá’ ni a pè ọ́.+  Nítorí orúkọ mi, èmi yóò dẹwọ́ ìbínú mi,+ àti nítorí ìyìn mi, èmi yóò kó ara mi níjàánu sí ọ, kí kíké ọ kúrò má bàa ṣẹlẹ̀.+ 10  Wò ó! Mo ti yọ́ ọ mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ti fàdákà.+ Mo ti yàn ọ́ nínú ìléru ìyọ́rin ti ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́.+ 11  Nítorí tèmi, nítorí tèmi, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀,+ nítorí pé báwo ni ẹnì kan ṣe lè jẹ́ kí a sọ òun di aláìmọ́?+ Èmi kì yóò sì fi ògo tèmi fún ẹlòmíràn.+ 12  “Fetí sí mi, ìwọ Jékọ́bù, àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti pè, Ẹnì kan náà ni mí.+ Èmi ni ẹni àkọ́kọ́.+ Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ni ẹni ìkẹyìn.+ 13  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọwọ́ mi ni ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,+ ọwọ́ ọ̀tún mi sì ni ó na ọ̀run.+ Mo ń pè wọ́n, kí wọ́n lè máa bá a nìṣó ní dídúró pa pọ̀.+ 14  “Ẹ kóra jọpọ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì gbọ́.+ Ta ni lára wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí? Jèhófà tìkára rẹ̀ ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ Òun yóò ṣe ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ̀ sí Bábílónì,+ apá rẹ̀ yóò sì wà lára àwọn ará Kálídíà.+ 15  Èmi—èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, mo ti pè é.+ Mo ti mú un wọlé wá, mímú kí ọ̀nà rẹ̀ yọrí sí rere yóò sì ṣẹlẹ̀.+ 16  “Ẹ sún mọ́ mi. Ẹ gbọ́ èyí. Láti ìbẹ̀rẹ̀, èmi kò sọ̀rọ̀ ní ibi ìlùmọ́ rárá.+ Láti ìgbà tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ ni mo ti wà níbẹ̀.” Wàyí o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti rán mi, àní ẹ̀mí rẹ̀.+ 17  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùtúnnirà+ rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+ “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní,+ Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.+ 18  Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́!+ Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò,+ òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.+ 19  Àwọn ọmọ rẹ ì bá sì dà bí iyanrìn, àwọn ọmọ ìran láti ìhà inú rẹ ì bá sì dà bí hóró rẹ̀.+ Orúkọ ẹni ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa á rẹ́ ráúráú kúrò níwájú mi.”+ 20  Ẹ jáde lọ kúrò ní Bábílónì!+ Ẹ fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà.+ Àní ẹ fi ìró igbe ìdùnnú sọ ọ́ jáde, ẹ mú kí a gbọ́ èyí.+ Ẹ jẹ́ kí ó jáde lọ sí ìkángun ilẹ̀ ayé.+ Ẹ sọ pé: “Jèhófà ti tún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jékọ́bù rà.+ 21  Òùngbẹ kò sì gbẹ wọ́n+ nígbà tí ó ń mú kí wọ́n rìn la àwọn ibi ìparundahoro kọjá.+ Ó mú kí omi láti inú àpáta ṣàn jáde fún wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí la àpáta kí omi náà lè ṣàn jáde.”+ 22  “Kò sí àlàáfíà,” ni Jèhófà wí, “fún àwọn ẹni burúkú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé