Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 47:1-15

47  Sọ̀ kalẹ̀, kí o sì jókòó sínú ekuru,+ ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Bábílónì.+ Jókòó sílẹ̀ níbi tí ìtẹ́ kò sí,+ ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà.+ Nítorí pé ìwọ kì yóò tún ní ìrírí kí àwọn ènìyàn máa pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ àti ajíṣefínní.+  Mú ọlọ ọlọ́wọ́,+ kí o sì lọ ìyẹ̀fun. Ṣí ìbòjú rẹ.+ Bọ́ ibi títú yagba lára aṣọ kúrò.+ Káṣọ kúrò ní ẹsẹ̀.+ Sọdá àwọn odò.  Ó yẹ kí o tú ìhòòhò rẹ síta.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó yẹ kí a rí ẹ̀gàn rẹ.+ Èmi yóò gbẹ̀san,+ èmi kì yóò sì ṣojú àánú sí ènìyàn èyíkéyìí.  “Ẹnì kan wà tí ń tún wa rà.+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”+  Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́+ kí o sì wá sínú òkùnkùn,+ ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà;+ nítorí pé ìwọ kì yóò tún ní ìrírí kí àwọn ènìyàn máa pè ọ́ ní Ìyálóde+ Àwọn Ìjọba.+  Ìkannú mi ru sí àwọn ènìyàn mi.+ Mo sọ ogún mi di aláìmọ́,+ mo sì tẹ̀ síwájú láti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+ Ìwọ kò fi àánú kankan hàn sí wọn.+ O mú kí àjàgà rẹ wúwo gidigidi lọ́rùn àgbàlagbà.+  Ìwọ sì ń wí pé: “Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóo máa jẹ́ Ìyálóde,+ àní títí láé.” Ìwọ kò fi nǹkan wọ̀nyí sínú ọkàn-àyà rẹ; ìwọ kò rántí paríparí òpin ọ̀ràn náà.+  Wàyí o, gbọ́ èyí, ìwọ jayéjayé obinrin, tí ó jókòó nínú ààbò,+ tí ń wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíràn.+ Èmi kì yóò jókòó gẹ́gẹ́ bí opó, èmi kì yóò sì mọ àdánù àwọn ọmọ.”+  Ṣùgbọ́n nǹkan méjèèjì wọ̀nyí yóò dé bá ọ lójijì, ní ọjọ́ kan:+ àdánù àwọn ọmọ àti ìgbà opó. Ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n wọn ni wọn yóò dé bá ọ,+ nítorí ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjẹ́ rẹ, nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá èèdì rẹ—lọ́nà tí ó peléke.+ 10  Ìwọ sì ń bá a nìṣó ní gbígbẹ́kẹ̀lé ìwà búburú rẹ.+ Ìwọ ti wí pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó rí mi.”+ Ọgbọ́n rẹ àti ìmọ̀ rẹ+—èyí ni ó ti mú ọ lọ; o sì ń wí nínú ọkàn-àyà rẹ pé: “Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíràn.” 11  Ìyọnu àjálù yóò sì dé bá ọ; ìwọ kì yóò mọ ìtujú kankan sí i. Ìwọ yóò sì ko àgbákò;+ ìwọ kì yóò sì lè yẹ̀ ẹ́. Ìparun tí ìwọ kò mọ̀ rí yóò sì dé bá ọ lójijì.+ 12  Dúró jẹ́ẹ́, nísinsìnyí, ti ìwọ ti èèdì rẹ àti ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ àjẹ́ rẹ,+ nínú èyí tí o ti ń ṣe làálàá láti ìgbà èwe rẹ wá; bóyá ìwọ yóò lè jàǹfààní, bóyá ìwọ yóò lè fi ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì kọlu àwọn ènìyàn. 13  Àárẹ̀ ti mú ọ pẹ̀lú ògìdìgbó àwọn tí ń gbà ọ́ nímọ̀ràn. Kí wọ́n dìde dúró, nísinsìnyí, kí wọ́n sì gbà ọ́ là, àwọn tí ń jọ́sìn ọ̀run, àwọn tí ń wo ìràwọ̀,+ àwọn tí ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun nípa àwọn ohun tí yóò dé bá ọ. 14  Wò ó! Wọn wá dà bí àgékù pòròpórò.+ Ṣe ni iná yóò sun wọ́n kanlẹ̀.+ Wọn kì yóò dá ọkàn ara wọn nídè+ lọ́wọ́ agbára ọwọ́ iná náà.+ Kì yóò sí ìpọ́nyòò èédú fún àwọn ènìyàn láti yáná, kì yóò sí ìmọ́lẹ̀ iná láti jókòó sí iwájú rẹ̀. 15  Báyìí ni wọn yóò dà fún ọ dájúdájú, àwọn tí o ti bá ṣe làálàá gẹ́gẹ́ bí atujú+ rẹ láti ìgbà èwe rẹ wá. Wọn yóò rìn gbéregbère ní ti tòótọ́, olúkúlùkù sí ẹkùn ilẹ̀ tirẹ̀. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà ọ́ là.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé