Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 44:1-28

44  “Wàyí o, fetí sílẹ̀, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,+ àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti yàn.+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùṣẹ̀dá+ rẹ àti Aṣẹ̀dá+ rẹ, ẹni tí ó ti ń ràn ọ́ lọ́wọ́ àní láti inú ikùn wá,+ ‘Má fòyà,+ ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, àti ìwọ, Jéṣúrúnì,+ ẹni tí mo ti yàn.  Nítorí pé èmi yóò da omi sára ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,+ àti àwọn odò kéékèèké tí ń ṣàn sórí ibi gbígbẹ.+ Èmi yóò da ẹ̀mí mi sára irú-ọmọ rẹ,+ àti ìbùkún mi sára àwọn ọmọ ìran rẹ.  Ṣe ni wọn yóò sì rú yọ bí ẹni pé láàárín koríko tútù,+ bí àwọn igi pọ́pílà+ tí ń bẹ lẹ́bàá àwọn kòtò omi.  Ẹni yìí yóò wí pé: “Ti Jèhófà ni èmi.”+ Ẹni yẹn yóò sì fi orúkọ Jékọ́bù pe ara rẹ̀,+ ẹlòmíràn yóò sì kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀ pé: “Ti Jèhófà ni.” Ènìyàn yóò sì fi orúkọ Ísírẹ́lì fún ara rẹ̀ ní orúkọ oyè.’+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ọba Ísírẹ́lì+ àti Olùtúnnirà+ rẹ̀, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn,+ yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.+  Ta sì ni ó dà bí èmi?+ Kí ó pè, kí ó lè sọ ọ́, kí ó sì gbé e kalẹ̀ fún mi.+ Láti ìgbà tí mo ti yan àwọn ènìyàn àtọjọ́mọ́jọ́ sípò,+ àwọn ohun tí ń bọ̀ àti àwọn ohun tí ó máa tó dé, kí wọ́n sọ níhà ọ̀dọ̀ wọn.  Ẹ má ṣe ní ìbẹ̀rùbojo, ẹ má sì di ẹni tí a dà lọ́kàn rú.+ Láti ìgbà yẹn síwájú, èmi kò ha ti mú kí ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan gbọ́, tí mo sì sọ ọ́ jáde?+ Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi.+ Ọlọ́run kan ha wà yàtọ̀ sí mi bí?+ Ó tì o, kò sí Àpáta kankan.+ Èmi kò mọ ìkankan.’”  Òtúbáńtẹ́ ni gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère gbígbẹ́,+ àwọn olólùfẹ́ wọn pàápàá kì yóò ṣàǹfààní;+ àti gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí wọn, wọn kò rí nǹkan kan, wọn kò sì mọ nǹkan kan,+ kí ojú lè tì wọ́n.+ 10  Ta ni ó ti ṣẹ̀dá ọlọ́run kan tàbí tí ó mọ ère dídà lásán-làsàn?+ Ó jẹ́ èyí tí kò ṣàǹfààní rárá.+ 11  Wò ó! Ojú yóò ti gbogbo alájọṣe rẹ̀ pàápàá,+ láti inú àwọn ará ayé sì ni àwọn oníṣẹ́ ọnà náà ti wá. Gbogbo wọn yóò kó ara wọn jọpọ̀.+ Wọn yóò dúró bọrọgidi. Ìbẹ̀rùbojo yóò bá wọn. Ojú yóò tì wọ́n lẹ́ẹ̀kan náà.+ 12  Ní ti agbẹ́rin tí ń lo ohun èlò tí a fi ń gbẹ́ nǹkan, ọwọ́ rẹ̀ dí bí ó ti ń ṣe é lórí ẹyín iná; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òòlù ṣe é, ọwọ́ rẹ̀ sì dí bí ó ti ń fi apá rẹ̀ lílágbára ṣe é.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ebi ń pa á, nítorí náà, kò ní agbára. Kò tíì mu omi; nítorí náà, ó rẹ̀ ẹ́. 13  Ní ti agbẹ́gi, ó na okùn ìdiwọ̀n; ó fi ẹfun pupa sàmì sí i; ó fi ìfági fá a; ó sì ń fi kọ́ńpáàsì sàmì sí i, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ṣe é bí àwòrán ènìyàn,+ bí ẹwà aráyé, láti jókòó nínú ilé.+ 14  Ẹnì kan wà tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ láti gé kédárì lulẹ̀; ó sì mú irú igi kan, àní igi ràgàjì kan, ó sì jẹ́ kí ó di líle fún ara rẹ̀ láàárín àwọn igi igbó.+ Ó gbin igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì, àní ọ̀yamùúmùú òjò sì ń mú kí ó tóbi sí i. 15  Ó sì ti di ohun kan fún ènìyàn láti fi mú kí iná máa jó. Nítorí náà, ó mú lára rẹ̀ kí ó lè yáná. Ní ti gidi, ó dá iná, ó sì yan búrẹ́dì ní tòótọ́. Bákan náà, ó ṣiṣẹ́ lórí ọlọ́run kan tí òun lè máa tẹrí ba fún.+ Ó ṣe é ní ère gbígbẹ́,+ ó sì ń wólẹ̀ fún un. 16  Ìdajì rẹ̀ ni ó sun nínú iná. Orí ìdajì rẹ̀ ni ó ti yan àyangbẹ ẹran tí ó ń jẹ, ó sì yó. Ó tún yáná, ó sì wí pé: “Àháà! Mo ti yáná. Mo ti rí ìmọ́lẹ̀ iná.” 17  Ṣùgbọ́n ìyókù rẹ̀ ni ó fi ṣe ọlọ́run ní tòótọ́, ó fi ṣe ère gbígbẹ́. Ó ń wólẹ̀ fún un, ó sì ń tẹrí bá, ó sì ń gbàdúrà sí i, ó sì ń wí pé: “Dá mi nídè, nítorí pé ìwọ ni ọlọ́run mi.”+ 18  Wọn kò mọ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lóye,+ nítorí tí nǹkan ti rá wọn lójú kí wọ́n má bàa ríran,+ nǹkan sì ti rá ọkàn-àyà wọn kí wọ́n má bàa ní ìjìnlẹ̀ òye.+ 19  Kò sì sí ẹni tí ó mú un wá sí ìrántí nínú ọkàn-àyà+ rẹ̀ tàbí tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye,+ pé: “Ìdajì rẹ̀ ni mo ti sun nínú iná, orí ẹyín iná rẹ̀ pẹ̀lú sì ni mo ti yan búrẹ́dì; mo yan ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó yẹ kí n fi ìyókù rẹ̀ ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lásán-làsàn?+ Ǹjẹ́ ó yẹ kí n máa wólẹ̀ fún igi gbígbẹ?” 20  Ó ń fi eérú bọ́ ara rẹ̀.+ Ọkàn-àyà rẹ̀ tí a ti tàn jẹ ti mú un ṣáko lọ.+ Kò sì dá ọkàn rẹ̀ nídè, bẹ́ẹ̀ sì ni kò wí pé: “Kò ha sí èké ní ọwọ́ ọ̀tún mi?”+ 21  “Rántí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jékọ́bù,+ àti ìwọ, Ísírẹ́lì, nítorí pé ìránṣẹ́ mi ni ọ́.+ Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ.+ Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ jẹ́. Ìwọ Ísírẹ́lì, a kì yóò gbàgbé rẹ níhà ọ̀dọ̀ mi.+ 22  Ṣe ni èmi yóò nu àwọn ìrélànàkọjá rẹ kúrò gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú àwọsánmà,+ àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà. Padà sọ́dọ̀ mi,+ nítorí pé èmi yóò tún ọ rà dájúdájú.+ 23  “Ẹ fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin ọ̀run,+ nítorí pé Jèhófà ti gbé ìgbésẹ̀!+ Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun,+ ẹ̀yin apá ìsàlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé!+ Ẹ tújú ká, ẹ̀yin òkè ńláńlá,+ pẹ̀lú igbe ìdùnnú, ìwọ igbó àti gbogbo ẹ̀yin igi tí ń bẹ nínú rẹ̀! Nítorí pé Jèhófà ti tún Jékọ́bù rà, ó sì fi ẹwà rẹ̀ hàn lára Ísírẹ́lì.”+ 24  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùtúnnirà+ rẹ àti Aṣẹ̀dá rẹ láti inú ikùn wá: “Èmi, Jèhófà, ń ṣe ohun gbogbo, mo na ọ̀run+ ní èmi nìkan, mo tẹ́ ilẹ̀ ayé.+ Ta ni ó wà pẹ̀lú mi? 25  Mo ń mú àwọn iṣẹ́ àmì àwọn olùsọ òfìfo ọ̀rọ̀ já sí pàbó, èmi sì ni Ẹni tí ń mú kí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ pàápàá máa ṣe bí ayírí;+ Ẹni tí ń dá àwọn ọlọ́gbọ́n padà sẹ́yìn, àti Ẹni tí ń sọ ìmọ̀ wọn pàápàá di ìwà òmùgọ̀;+ 26  Ẹni tí ń mú kí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ, àti Ẹni tí ń mú ìmọ̀ràn àwọn ońṣẹ́+ rẹ̀ ṣẹ pátápátá; Ẹni tí ń wí nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘A óò gbé inú rẹ̀,’+ àti nípa àwọn ìlú ńlá Júdà pé, ‘A óò tún wọn kọ́,+ èmi yóò sì gbé àwọn ibi ahoro rẹ̀ dìde’;+ 27  Ẹni tí ń wí fún ibú omi pé, ‘Gbẹ; gbogbo odò rẹ sì ni èmi yóò mú gbẹ táútáú’;+ 28  Ẹni tí ó wí nípa Kírúsì+ pé, ‘Òun ni olùṣọ́ àgùntàn mi, gbogbo ohun tí mo sì ní inú dídùn sí ni òun yóò mú ṣe pátápátá’;+ àní nínú àsọjáde mi nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘A óò tún un kọ́,’ àti nípa tẹ́ńpìlì pé, ‘A ó fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé