Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 42:1-25

42  Wò ó! Ìránṣẹ́ mi,+ tí mo dì mú ṣinṣin!+ Àyànfẹ́ mi,+ ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà!+ Èmi ti fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀.+ Ìdájọ́ òdodo fún àwọn orílẹ̀-èdè ni ohun tí yóò mú wá.+  Kì yóò ké jáde tàbí kí ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, kì yóò sì jẹ́ kí a gbọ́ ohùn òun ní ojú pópó.+  Kò sí esùsú fífọ́ tí òun yóò ṣẹ́;+ àti ní ti òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó bàìbàì, òun kì yóò fẹ́ ẹ pa. Nínú òótọ́ ni òun yóò mú ìdájọ́ òdodo wá.+  Òun kì yóò di bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò tẹ̀ ẹ́ rẹ́ títí yóò fi gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ilẹ̀ ayé;+ òfin rẹ̀ sì ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò máa dúró dè.+  Èyí ni ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run+ àti Ẹni Atóbilọ́lá tí ó nà án;+ Ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé+ àti èso rẹ̀,+ Ẹni tí ó fi èémí+ fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí rẹ̀,+ àti ẹ̀mí fún àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀:+  “Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti pè ọ́ nínú òdodo,+ mo sì tẹ̀ síwájú láti di ọwọ́ rẹ mú.+ Èmi yóò sì máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, èmi yóò sì fi ọ́ fúnni gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú àwọn ènìyàn,+ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+  kí o lè la àwọn ojú tí ó fọ́,+ kí o lè mú ẹlẹ́wọ̀n jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀,+ kí o lè mú àwọn tí ó jókòó sínú òkùnkùn jáde kúrò ní àtìmọ́lé.+  “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi;+ èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn+ mi fún àwọn ère fífín.+  “Àwọn nǹkan àkọ́kọ́—àwọn ni ó ń ṣẹlẹ̀ yìí,+ ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tuntun ni mo ń sọ jáde. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí rú yọ, mo mú kí ẹ gbọ́ wọn.”+ 10  Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+ ìyìn rẹ̀ láti ìkángun ilẹ̀ ayé,+ ẹ̀yin tí ẹ ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú òkun+ àti ohun tí ó kún inú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn.+ 11  Kí aginjù+ àti àwọn ìlú ńlá rẹ̀ gbé ohùn wọn sókè, àwọn ibi ìtẹ̀dó tí Kídárì ń gbé.+ Kí àwọn olùgbé orí àpáta gàǹgà+ fi ìdùnnú ké jáde. Kí àwọn ènìyàn ké sókè láti orí àwọn òkè ńlá. 12  Kí wọ́n gbé ògo fún Jèhófà,+ kí wọ́n sì sọ ìyìn rẹ̀ jáde àní ní àwọn erékùṣù.+ 13  Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò jáde lọ bí alágbára ńlá.+ Òun yóò jí ìtara dìde bí jagunjagun.+ Yóò kígbe, bẹ́ẹ̀ ni, yóò fi igbe ogun ta;+ yóò fi ara rẹ̀ hàn ní alágbára ńlá ju àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ.+ 14  “Mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ìgbà pípẹ́.+ Mo ń bá a lọ ní dídákẹ́.+ Mo ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu.+ Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó fẹ́ bímọ, èmi yóò kérora, èmi yóò mí hẹlẹ, èmi yóò sì mí gúlegúle lẹ́ẹ̀kan náà.+ 15  Èmi yóò pa àwọn òkè ńláńlá àti òkè kéékèèké run di ahoro,+ gbogbo ewéko wọn sì ni èmi yóò mú gbẹ dànù. Ṣe ni èmi yóò sọ àwọn odò di àwọn erékùṣù, àwọn odò adágún tí ó kún fún esùsú ni èmi yóò sì mú gbẹ táútáú.+ 16  Ṣe ni èmi yóò sì mú kí àwọn afọ́jú rìn ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀;+ òpópónà tí wọn kò mọ̀ ni èmi yóò mú kí wọ́n rìn.+ Èmi yóò sọ ibi tí ó ṣókùnkùn níwájú wọn di ìmọ́lẹ̀,+ èmi yóò sì sọ àgbègbè ilẹ̀ kángunkàngun di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ.+ Ìwọ̀nyí ni nǹkan tí èmi yóò ṣe fún wọn, dájúdájú, èmi kì yóò fi wọ́n sílẹ̀.”+ 17  A óò dá wọn padà, ojú yóò tì wọ́n gidigidi, àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ère gbígbẹ́,+ àwọn tí ń wí fún ère dídà pé: “Ẹ̀yin ni ọlọ́run wa.”+ 18  Ẹ gbọ́, ẹ̀yin adití; kí ẹ sì wo iwájú láti ríran, ẹ̀yin afọ́jú.+ 19  Ta ni ó fọ́jú, bí kì í bá ṣe ìránṣẹ́ mi, ta sì ni ó dití bí ońṣẹ́ mi tí mo rán? Ta ni ó fọ́jú bí ẹni tí a san lẹ́san, tàbí tí ó fọ́jú bí ìránṣẹ́ Jèhófà?+ 20  Ó jẹ́ ọ̀ràn rírí ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyè sí i.+ Ó jẹ́ ọ̀ràn líla etí, ṣùgbọ́n ìwọ kò fetí sílẹ̀.+ 21  Jèhófà fúnra rẹ̀, nítorí òdodo rẹ̀,+ ti ní inú dídùn ní ti pé kí ó gbé òfin ga lọ́lá,+ kí ó sì sọ ọ́ di ọlọ́lá ọba. 22  Ṣùgbọ́n ó jẹ́ àwọn ènìyàn tí a piyẹ́, tí a sì kó ní ìkógun,+ gbogbo wọn ni a dẹ pańpẹ́ mú nínú àwọn ihò, inú àwọn àtìmọ́lé sì ni a fi wọ́n pa mọ́ sí.+ Wọ́n ti wá wà fún ìpiyẹ́ láìsí olùdáǹdè,+ fún ìkógun láìsí ẹnikẹ́ni láti sọ pé: “Kó o padà!” 23  Ta ni yóò fi etí sí èyí nínú yín? Ta ni yóò fiyè sílẹ̀, tí yóò sì fetí sílẹ̀ nítorí ọjọ́ iwájú?+ 24  Ta ni ó fi Jékọ́bù fún ìkógun lásán-làsàn, àti Ísírẹ́lì fún àwọn olùpiyẹ́? Jèhófà ha kọ́, Ẹni tí a dẹ́ṣẹ̀ sí, ẹni tí wọn kò fẹ́ láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹni tí wọn kò sì fetí sí òfin rẹ̀?+ 25  Nítorí náà, Ó ń bá a nìṣó ní dída ìhónú lé e lórí, ìbínú rẹ̀, àti okun ogun.+ Ó sì ń jẹ ẹ́ run nìṣó yí ká,+ ṣùgbọ́n kò fiyè sí i;+ ó sì ń jó o nìṣó, ṣùgbọ́n kò jẹ́ fi nǹkan kan sí ọkàn-àyà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé