Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 41:1-29

41  “Ẹ tẹ́tí sí mi ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin erékùṣù;+ kí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè+ pàápàá sì jèrè agbára padà. Kí wọ́n sún mọ́ tòsí.+ Ní àkókò yẹn, kí wọ́n sọ̀rọ̀. Ẹ jẹ́ kí a jọ sún mọ́ tòsí fún ìdájọ́.+  “Ta ni ó ti gbé ẹnì kan dìde láti yíyọ oòrùn?+ Ta ni ó tẹ̀ síwájú nínú òdodo láti pè é wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀, láti fi àwọn orílẹ̀-èdè fún un níwájú rẹ̀, àti láti mú kí ó máa tẹ àwọn ọba pàápàá lórí ba nìṣó?+ Ta ni ó ń fi wọ́n fún un bí ekuru fún idà rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé a ń fi ọrun rẹ̀ gbá wọn kiri bí àgékù pòròpórò lásán-làsàn?+  Ta ni ó ń lépa wọn, tí ó ń fi ẹsẹ̀ rìn lọ ní àlàáfíà ní ipa ọ̀nà tí òun kò gbà wá?  Ta ni ó ti ń gbé kánkán ṣiṣẹ́,+ tí ó sì ti ṣe èyí, tí ó ń pe àwọn ìran jáde láti ìbẹ̀rẹ̀?+ “Èmi, Jèhófà ni, tí í ṣe Ẹni Àkọ́kọ́;+ àti pẹ̀lú àwọn ẹni ìkẹyìn, èmi kan náà ni.”+  Àwọn erékùṣù+ rí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù. Àní àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì.+ Wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì ń bọ̀.  Olúkúlùkù wọn ń ran alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ọ̀kan a sì wí fún arákùnrin rẹ̀ pé: “Jẹ́ alágbára.”+  Bẹ́ẹ̀ ni oníṣẹ́ ọnà ń fún oníṣẹ́ irin+ lókun; ẹni tí ń fi ọmọ owú mú nǹkan jọ̀lọ̀ ń fún ẹni tí ń fi òòlù lu nǹkan nídìí owú lókun, ó ń sọ nípa ìjópọ̀ pé: “Ó dára.” Níkẹyìn, ẹnì kan fi ìṣó kàn án, tí a kò fi lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+  “Ṣùgbọ́n ìwọ, Ísírẹ́lì, ni ìránṣẹ́ mi,+ ìwọ, Jékọ́bù, ẹni tí mo ti yàn,+ irú-ọmọ Ábúráhámù+ ọ̀rẹ́ mi;+  ìwọ, tí mo ti dì mú láti àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé,+ àti ìwọ, tí mo ti pè àní láti àwọn apá rẹ̀ jíjìnnàréré.+ Mo sì tipa báyìí sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;+ mo ti yàn ọ́,+ èmi kò sì kọ̀ ọ́.+ 10  Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ.+ Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+ Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ.+ Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.+ Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún+ òdodo+ mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.’ 11  “Wò ó! Gbogbo àwọn tí ń gbaná jẹ mọ́ ọ ni ojú yóò tì, tí a ó sì tẹ́ lógo.+ Àwọn ènìyàn tí ń bá ọ ṣe aáwọ̀ yóò rí bí aláìjámọ́ nǹkan kan, wọn yóò sì ṣègbé.+ 12  Ìwọ yóò wá wọn kiri, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò rí wọn, àwọn ènìyàn tí ń bá ọ jìjàkadì.+ Wọn yóò rí bí aláìsí àti bí aláìjámọ́ nǹkan kan,+ àwọn tí ń bá ọ jagun. 13  Nítorí pé èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún+ rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà.+ Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’+ 14  “Má fòyà, ìwọ Jékọ́bù kòkòrò mùkúlú,+ ẹ̀yin ọkùnrin Ísírẹ́lì.+ Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni àsọjáde Jèhófà, àní Olùtúnnirà+ rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. 15  “Wò ó! Mo ti ṣe ọ́ ní ohun èlò ìpakà,+ ohun èlò ìpakà tuntun tí ó ní eyín olójú méjì. Ìwọ yóò tẹ àwọn òkè ńláńlá mọ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fọ́ wọn túútúú; àwọn òkè kéékèèké ni ìwọ yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.+ 16  Ìwọ yóò fẹ́+ wọn bí ọkà, àní ẹ̀fúùfù yóò sì gbé wọn lọ,+ ìjì ẹlẹ́fùúùfù pàápàá yóò sì gbá wọn lọ sí ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.+ Ìwọ fúnra rẹ yóò sì kún fún ìdùnnú nínú Jèhófà.+ Ìwọ yóò máa fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ṣògo nípa ara rẹ.”+ 17  “Àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn òtòṣì ń wá omi,+ ṣùgbọ́n kò sí rárá. Àní ahọ́n wọn ti gbẹ+ nítorí òùngbẹ.+ Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò dá wọn lóhùn.+ Èmi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kì yóò fi wọ́n sílẹ̀.+ 18  Lórí àwọn òkè kéékèèké dídán borokoto, èmi yóò ṣí àwọn odò, àti ní àárín àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì, èmi yóò ṣí àwọn ìsun.+ Èmi yóò sọ aginjù di adágún omi tí ó kún fún esùsú, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ aláìlómi di àwọn orísun omi.+ 19  Aginjù ni èmi yóò fìdí igi kédárì, igi bọn-ọ̀n-ní àti igi mátílì àti igi òróró+ kalẹ̀ sí. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ni èmi yóò fi igi júnípà, igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì sí lẹ́ẹ̀kan náà;+ 20  kí àwọn ènìyàn lè rí, kí wọ́n sì mọ̀, kí wọ́n sì kọbi ara sí i, kí wọ́n sì ní ìjìnlẹ̀ òye lẹ́ẹ̀kan náà, pé ọwọ́ Jèhófà gan-an ni ó ṣe èyí, àti pé Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tìkára rẹ̀ ni ó dá a.”+ 21  “Ẹ mú ọ̀ràn àríyànjiyàn+ yín wá síwájú,” ni Jèhófà wí. “Ẹ gbé ìjiyàn+ yín jáde,” ni Ọba Jékọ́bù+ wí. 22  “Ẹ gbé e jáde kí ẹ sì sọ àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún wa. Àwọn ohun àkọ́kọ́—ohun tí wọ́n jẹ́—ẹ sọ, kí a lè fi ọkàn-àyà wa sí i, kí a sì mọ ọjọ́ ọ̀la wọn. Tàbí kẹ̀, ẹ mú kí a gbọ́, àní àwọn ohun tí ń bọ̀ wá.+ 23  Ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la, kí a lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.+ Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí ẹ ṣe rere tàbí kí ẹ ṣe búburú, kí a lè wò yí ká, kí a sì rí i lẹ́ẹ̀kan náà.+ 24  Wò ó! Ohun tí kò sí ni yín, àṣeyọrí yín kò sì jámọ́ nǹkan kan.+ Ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yàn yín.+ 25  “Mo ti gbé ẹnì kan dìde láti àríwá, yóò sì wá.+ Láti yíyọ oòrùn+ ni yóò ti ké pe orúkọ mi. Yóò sì wá sórí àwọn ajẹ́lẹ̀ bí ẹni pé amọ̀+ ni wọ́n àti gan-an gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò tí ń tẹ ohun èlò rírin mọ́lẹ̀. 26  “Ta ni ó ti sọ ohunkóhun láti ìbẹ̀rẹ̀, kí a lè mọ̀, tàbí láti àwọn ìgbà tí ó ti kọjá, kí a lè sọ pé, ‘Ó tọ̀nà’?+ Ní ti tòótọ́, kò sí ẹni tí ó sọ ọ́. Ní ti tòótọ́, kò sí ẹni tí ó mú kí ènìyàn gbọ́. Ní ti tòótọ́, kò sí ẹni tí ó gbọ́ àsọjáde yín kankan.”+ 27  Ẹni àkọ́kọ́ wà, tí ó wí fún Síónì pé: “Wò ó! Àwọn rèé!”+ èmi yóò sì fún Jerúsálẹ́mù ní olùmú ìhìn rere wá.+ 28  Mo sì ń wò, kò sì sí ènìyàn kankan; lára àwọn wọ̀nyí, kò sì sí ẹni tí ń fúnni ní ìmọ̀ràn.+ Mo sì ń bi wọ́n léèrè ṣáá, kí wọ́n lè fèsì. 29  Wò ó! Gbogbo wọ́n jẹ́ ohun tí kò sí. Iṣẹ́ wọn kò jámọ́ nǹkan kan. Àwọn ère dídà wọ́n jẹ́ ẹ̀fúùfù àti òtúbáńtẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé