Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 4:1-6

4  Obìnrin méje yóò sì rá ọkùnrin kan mú ní ọjọ́ yẹn+ ní ti tòótọ́, wọn yóò sì wí pé: “Oúnjẹ tiwa ni àwa yóò máa jẹ, aṣọ àlàbora tiwa sì ni àwa yóò máa wọ̀; kìkì pé kí a máa fi orúkọ rẹ pè wá, láti mú ẹ̀gàn wa kúrò.”+  Ní ọjọ́ yẹn, ohun tí Jèhófà mú kí ó rú jáde+ yóò wá wà fún ìṣelóge àti fún ògo,+ èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ohun ìyangàn+ àti ohun ẹlẹ́wà fún àwọn tí ó sá àsálà lára Ísírẹ́lì.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, àwọn tí ó ṣẹ́ kù ní Síónì àti àwọn tí a ṣẹ́ kù ní Jerúsálẹ́mù ni a ó sọ pé wọ́n jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀,+ olúkúlùkù ẹni tí a kọ sílẹ̀ fún ìwàláàyè ní Jerúsálẹ́mù.+  Nígbà tí Jèhófà bá ti fọ ìgbọ̀nsẹ̀ àwọn ọmọbìnrin Síónì+ nù, tí yóò sì ṣan+ ìtàjẹ̀sílẹ̀+ Jerúsálẹ́mù pàápàá kúrò láàárín rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí ìdájọ́ àti nípasẹ̀ ẹ̀mí jíjó kanlẹ̀,+  dájúdájú, Jèhófà yóò dá àwọsánmà ní ọ̀sán àti èéfín, àti ìtànyòò iná tí ń jó fòfò+ ní òru+ sórí gbogbo ibi àfìdímúlẹ̀ tí ń bẹ ní Òkè Ńlá Síónì+ àti sórí ibi àpéjọpọ̀ rẹ̀; nítorí pé ibi ààbò yóò wà lórí gbogbo ògo.+  Àtíbàbà kan yóò sì wà fún ibòji ní ọ̀sán kúrò lọ́wọ́ ooru gbígbẹ,+ àti fún ibi ìsádi àti fún ibi ìfarapamọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò àti kúrò lọ́wọ́ ìrọ̀sílẹ̀ òjò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé