Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 39:1-8

39  Ní àkókò yẹn, Merodaki-báládánì+ ọmọkùnrin Báládánì ọba Bábílónì+ fi àwọn lẹ́tà àti ẹ̀bùn+ ránṣẹ́ sí Hesekáyà, lẹ́yìn tí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn, ṣùgbọ́n ti ara rẹ̀ ti le padà.+  Nítorí náà, Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nítorí wọn,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n,+ fàdákà àti wúrà àti òróró básámù+ àti òróró dáradára àti gbogbo ilé ìhámọ́ra+ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí a rí nínú àwọn ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan kan tí Hesekáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé tirẹ̀+ àti nínú gbogbo àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀.+  Lẹ́yìn ìyẹn, Aísáyà wòlíì wọlé tọ Hesekáyà Ọba wá, ó sì sọ fún un pé:+ “Kí ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wí, ibo sì ni wọ́n ti wá sọ́dọ̀ rẹ?” Nítorí náà, Hesekáyà wí pé: “Láti ilẹ̀ jíjìnnà ni wọ́n ti wá sọ́dọ̀ mi, láti Bábílónì.”+  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kí ni wọ́n rí nínú ilé rẹ?”+ Hesekáyà fèsì pé: “Ohun gbogbo tí ó wà nínú ilé mi ni wọ́n rí. Kò sí nǹkan kan tí èmi kò fi hàn wọ́n nínú àwọn ìṣúra mi.”  Aísáyà wá sọ fún Hesekáyà+ pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,  ‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀, gbogbo ohun tí ó sì wà nínú ilé tìrẹ àti èyí tí àwọn baba ńlá rẹ ti tò jọ pa mọ́ títí di òní yìí ni a óò kó lọ sí Bábílónì ní ti tòótọ́.’+ ‘Kì yóò ṣẹ́ ku nǹkan kan,’+ ni Jèhófà wí.  ‘Àwọn kan lára ọmọ tìrẹ tí yóò ti inú rẹ jáde wá, àwọn tí ìwọ yóò bí, àwọn pàápàá ni a óò kó,+ ní ti tòótọ́ wọn yóò di òṣìṣẹ́ láàfin+ ọba Bábílónì.’”+  Látàrí ìyẹn, Hesekáyà wí fún Aísáyà pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ìwọ sọ dára.”+ Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Nítorí pé àlàáfíà àti òtítọ́+ yóò máa bá a lọ ní àwọn ọjọ́ mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé