Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 38:1-22

38  Ní ọjọ́ wọnnì, Hesekáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Aísáyà+ ọmọkùnrin Émọ́sì, tí í ṣe wòlíì, wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Pa àṣẹ fún agbo ilé rẹ,+ nítorí pé ìwọ fúnra rẹ yóò kú ní tòótọ́, ìwọ kì yóò sì yè.’”+  Látàrí ìyẹn, Hesekáyà yí ojú sí ògiri,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà,+  ó sì wí pé: “Mo fi taratara bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀wọ́, rántí+ bí mo ṣe rìn+ níwájú rẹ nínú òtítọ́+ àti pẹ̀lú ọkàn-àyà pípé pérépéré,+ ohun tí ó dára ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.” Hesekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.+  Ọ̀rọ̀+ Jèhófà sì tọ Aísáyà wá wàyí, pé:  “Lọ, kí o sì sọ fún Hesekáyà pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ+ wí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ.+ Mo ti rí omijé rẹ.+ Kíyè sí i, èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ rẹ;+  èmi yóò sì dá ìwọ àti ìlú ńlá yìí nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Ásíríà, èmi yóò sì gbèjà ìlú ńlá yìí dájúdájú.+  Èyí ni àmì fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé Jèhófà yóò mú ọ̀rọ̀ yìí tí ó ti sọ ṣẹ:+  Kíyè sí i, èmi yóò mú kí òjìji tí ń bẹ lára àwọn ìdásẹ̀lé ara àtẹ̀gùn, tí oòrùn+ ti mú kí ó sọ̀ kalẹ̀ sára àtẹ̀gùn Áhásì, kí ó tọsẹ̀ padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá ara àtẹ̀gùn.”’”+ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, oòrùn padà sẹ́yìn ní ìdásẹ̀lé mẹ́wàá ara àtẹ̀gùn lórí àtẹ̀gùn tí ó ti sọ̀ kalẹ̀ lé.+  Ìwé Hesekáyà ọba Júdà, nígbà tí ó ṣàìsàn+ tí ó sì sàn nínú àìsàn rẹ̀.+ 10  Èmi fúnra mi wí pé: “Àárín àwọn ọjọ́ mi ni èmi yóò lọ sí àwọn ẹnubodè+ Ṣìọ́ọ̀lù. A ó fi ìyókù+ àwọn ọdún mi dù mí.” 11  Mo wí pé: “Èmi kì yóò rí Jáà, àní Jáà, ní ilẹ̀ àwọn alààyè.+ Èmi kì yóò wo aráyé mọ́—pẹ̀lú àwọn olùgbé ilẹ̀ ìdákẹ́. 12  A ti fa ibi gbígbé mi tu,+ a sì ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi bí àgọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn. Mo ti ká ìwàláàyè mi jọ gẹ́gẹ́ bí olófì; Ẹnì kan tẹ̀ síwájú láti ké mi kúrò+ lára àwọn fọ́nrán òwú títa gan-an. Láti ojúmọmọ títí di òru, o ń fi mí léni lọ́wọ́.+ 13  Mo ti tu ara mi lára pẹ̀sẹ̀ títí di òwúrọ̀.+ Bí kìnnìún, bẹ́ẹ̀ ni ó ń fọ́ gbogbo egungun mi;+ Láti ojúmọmọ títí di òru, o ń fi mí léni lọ́wọ́.+ 14  Bí ẹyẹ olófèéèré, ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ké ṣíoṣío;+ Mo ń ké kúùkúù bí àdàbà.+ Ojú mi ti wo ibi gíga tí-tí-tí:+ ‘Jèhófà, mo wà lábẹ́ ìnilára. Dúró tì mí.’+ 15  Kí ni kí n sọ, kí sì ni òun yóò wí fún mi ní ti tòótọ́?+ Òun fúnra rẹ̀ ti gbé ìgbésẹ̀.+ Mo ń rìn tìrònú-tìrònú ní gbogbo ọdún mi nínú ìkorò ọkàn mi.+ 16  ‘Jèhófà, ní tìtorí èyíinì, wọ́n ń wà láàyè nìṣó; àti ní ti gbogbo ènìyàn, ipasẹ̀ wọn ni ìwàláàyè ẹ̀mí mi.+ Ìwọ yóò sì mú mi padà sípò ìlera, ìwọ yóò sì pa mí mọ́ láàyè dájúdájú.+ 17  Wò ó! Dípò àlàáfíà mo ní ohun kíkorò, bẹ́ẹ̀ ni, kíkorò;+ Ìwọ fúnra rẹ sì ti fà mọ́ ọkàn mi, o sì pa á mọ́ kúrò nínú kòtò ìfọ́kélekèle.+ Nítorí pé o ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.+ 18  Nítorí pé kì í ṣe Ṣìọ́ọ̀lù ni ó lè gbé ọ lárugẹ;+ ikú pàápàá kò lè yìn ọ́.+ Àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò kò lè wo òótọ́ rẹ tìrètí-tìrètí.+ 19  Àlààyè, alààyè, òun ni ó lè gbé ọ lárugẹ,+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti lè ṣe ní òní yìí.+ Baba fúnra rẹ̀ lè fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìmọ̀+ nípa òótọ́ rẹ. 20  Jèhófà, dáwọ́ lé gbígbà mí là,+ a ó sì máa kọ àwọn àṣàyàn orin mi tí a fi ohun èlò olókùn tín-ín-rín kọ+ Ní gbogbo ọjọ́ ayé wa ní ilé Jèhófà.’”+ 21  Aísáyà sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Kí wọ́n mú ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ, kí wọ́n sì fi pa ojú oówo náà,+ kí ó lè sàn.”+ 22  Láàárín àkókò náà, Hesekáyà sọ pé: “Kí ni àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí ilé Jèhófà?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé