Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 37:1-38

37  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Hesekáyà Ọba gbọ́, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bora,+ ó sì wá sínú ilé Jèhófà.+  Síwájú sí i, ó rán Élíákímù,+ ẹni tí ń bójú tó agbo ilé, àti Ṣébínà akọ̀wé+ àti àwọn àgbà ọkùnrin nínú àwọn àlùfáà+ tí wọ́n fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bora, sí Aísáyà+ ọmọkùnrin Émọ́sì, tí í ṣe wòlíì.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Èyí ni ohun tí Hesekáyà wí, ‘Ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ wàhálà+ àti ti ìbáwí mímúná àti ti àfojúdi tí ó kún fún ìpẹ̀gàn,+ nítorí pé àwọn ọmọ ń bọ̀ títí wọ́n fi dé ẹnu ilé ọlẹ̀, kò sì sí agbára láti bímọ.+  Bóyá Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè,+ ẹni tí olúwa rẹ̀ ọba Ásíríà rán láti ṣáátá+ Ọlọ́run alààyè, òun yóò sì pè é wá jíhìn ní ti tòótọ́ fún àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbọ́.+ Kí o sì gbé àdúrà sókè+ nítorí ti àṣẹ́kù tí a lè rí.’”+  Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Hesekáyà Ọba wọlé tọ Aísáyà wá.+  Nígbà náà ni Aísáyà sọ fún wọn pé: “Èyí ni kí ẹ sọ fún olúwa yín, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí:+ “Má fòyà+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, èyí tí àwọn ẹmẹ̀wà+ ọba Ásíríà sọ sí mi tèébútèébú.  Kíyè sí i, èmi yóò fi ẹ̀mí+ kan sínú rẹ̀, òun yóò sì gbọ́ ìròyìn kan,+ yóò sì padà sí ilẹ̀ tirẹ̀; dájúdájú, èmi yóò mú kí ó tipa idà ṣubú ní ilẹ̀ tirẹ̀.”’”+  Lẹ́yìn ìyẹn, Rábúṣákè+ padà, ó sì rí i tí ọba Ásíríà ń bá Líbínà+ jà, nítorí ó gbọ́ pé ó ti ṣí kúrò ní Lákíṣì.+  Wàyí o, ó gbọ́ tí a sọ nípa Tíhákà+ ọba Etiópíà pé: “Ó ti jáde wá láti bá ọ jà.” Nígbà tí ó gbọ́, lójú-ẹsẹ̀, ó rán àwọn ońṣẹ́+ sí Hesekáyà pé: 10  “Èyí ni kí ẹ sọ fún Hesekáyà ọba Júdà, ‘Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé tàn ọ́ jẹ,+ wí pé: “A kì yóò fi Jerúsálẹ́mù lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 11  Wò ó! Ìwọ alára ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Ásíríà ṣe sí gbogbo ilẹ̀ nípa yíyà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun,+ a ó ha sì dá ìwọ alára nídè bí?+ 12  Àwọn ọlọ́run+ àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi run ha ti dá wọn nídè bí,+ àní Gósánì+ àti Háránì+ àti Réséfù àti àwọn ọmọ Édẹ́nì+ tí ó wà ní Tẹli-ásárì? 13  Ọba Hámátì+ àti ọba Áápádì+ àti ọba ìlú ńlá Séfáfáímù+—ti Hénà àti ti Ífáhì dà?’”+ 14  Nígbà náà ni Hesekáyà gba àwọn lẹ́tà náà lọ́wọ́ àwọn ońṣẹ́ náà, ó sì kà wọ́n,+ lẹ́yìn èyí tí Hesekáyà gòkè lọ sí ilé Jèhófà, ó sì tẹ́ ẹ síwájú Jèhófà.+ 15  Hesekáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà,+ pé: 16  “Ìwọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tí ń jókòó sórí àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́ ti gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.+ Ìwọ tìkára rẹ ni ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.+ 17  Dẹ etí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì gbọ́.+ La ojú rẹ,+ Jèhófà, kí o sì wò, kí o sì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Senakéríbù+ tí ó fi ránṣẹ́ láti ṣáátá Ọlọ́run alààyè.+ 18  Òtítọ́ ni, Jèhófà, pé àwọn ọba Ásíríà ti pa gbogbo ilẹ̀ run di ahoro, àti ilẹ̀ tiwọn.+ 19  Gbígbé àwọn ọlọ́run wọn lé iná lọ́wọ́ sì ṣẹlẹ̀,+ nítorí pé wọn kì í ṣe ọlọ́run,+ bí kò ṣe iṣẹ́ ọnà ọwọ́ ènìyàn,+ igi àti òkúta, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n pa wọ́n run.+ 20  Wàyí o, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa,+ gbà wá là lọ́wọ́ rẹ̀,+ kí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni [Ọlọ́run].”+ 21  Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́ sí Hesekáyà, pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Nítorí pé o ti gbàdúrà sí mi nípa Senakéríbù ọba Ásíríà,+ 22  èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ lòdì sí i: “Wúńdíá ọmọbìnrin Síónì ti tẹ́ńbẹ́lú rẹ, ó ti fi ọ́ ṣẹ̀sín.+ Ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù ti mi orí rẹ̀ lẹ́yìn rẹ.+ 23  Ta ni ìwọ ṣáátá,+ tí o sì sọ̀rọ̀ sí tèébútèébú?+ Ta sì ni ìwọ gbé ohùn rẹ sókè lòdì sí,+ Tí ìwọ sì gbé ojú rẹ ga sókè sí?+ Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì mà ni!+ 24  Ìwọ tipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣáátá Jèhófà, ìwọ sì wí pé,+ ‘Ògìdìgbó kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun mi ni èmi fúnra mi+ Ni èmi yóò fi gun ibi gíga àwọn ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá dájúdájú,+ Àwọn apá ibi jíjìnnàréré jù lọ ní Lẹ́bánónì;+ Èmi yóò sì gé àwọn kédárì rẹ̀ gíga fíofío lulẹ̀, àwọn ààyò igi júnípà rẹ̀.+ Èmi yóò sì wọ ìpẹ̀kun ibi gíga rẹ̀, igbó ọgbà igi eléso rẹ̀.+ 25  Dájúdájú, èmi fúnra mi yóò walẹ̀, èmi yóò sì mu omi, Èmi yóò sì fi àtẹ́lẹsẹ̀ mi mú gbogbo ipa odò Náílì+ ti Íjíbítì gbẹ táútáú.’+ 26  Ṣé ìwọ kò tíì gbọ́ ni?+ Láti àwọn àkókò jíjìnnà, èyí ni èmi yóò ṣe dájúdájú.+ Láti àwọn ọjọ́ tí ó ti kọjá lọ ni mo tilẹ̀ ti ṣẹ̀dá rẹ̀.+ Wàyí o, èmi yóò mú un wá dájúdájú.+ Ìwọ yóò sì wà fún mímú kí àwọn ìlú ńlá olódi di ahoro gẹ́gẹ́ bí ìtòjọpelemọ àwókù.+ 27  Àwọn olùgbé inú wọn yóò sì jẹ́ ọlọ́wọ́ ahẹrẹpẹ;+ Ṣe ni àyà wọn yóò wulẹ̀ máa já, tí ojú yóò sì tì wọ́n.+ Wọn yóò dà bí ewéko pápá àti ọ̀jẹ̀lẹ́ koríko,+ Koríko orí òrùlé+ àti ti ilẹ̀ onípele títẹ́jú níwájú ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn.+ 28  Jíjókòó jẹ́ẹ́ rẹ àti jíjáde+ rẹ àti wíwọlé rẹ sì ni mo mọ̀ dáadáa,+ Àti ríru tí o ń ru ara rẹ sókè sí mi,+ 29  Nítorí pé ríru tí o ń ru ara rẹ sókè sí mi+ àti kíké tí o ń ké ramúramù ti dé etí mi.+ Dájúdájú, èmi yóò sì fi ìwọ̀ mi sí imú rẹ àti ìjánu mi sáàárín ètè rẹ,+ Ní tòótọ́, èmi yóò sì mú ọ padà lọ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá.”+ 30  “‘Èyí ni yóò sì jẹ́ àmì fún ọ: Ní ọdún yìí, jíjẹ láti inú èéhù àwọn kóró dídàálẹ̀+ yóò wáyé, àti ní ọdún kejì, ọkà tí ó lalẹ̀ hù; ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ fún irúgbìn, kí ẹ sì kárúgbìn, kí ẹ sì gbin ọgbà àjàrà, kí ẹ sì jẹ èso rẹ̀.+ 31  Àwọn tí ó sì sá àsálà lára ilé Júdà, àwọn tí ó ṣẹ́ kù,+ yóò sì ta gbòǹgbò lọ sísàlẹ̀ dájúdájú, wọn yóò sì so èso sókè.+ 32  Nítorí pé àṣẹ́kù yóò jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù,+ àwọn tí ó sì sá àsálà yóò jáde lọ láti Òkè Ńlá Síónì.+ Ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni yóò ṣe èyí.+ 33  “‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa ọba Ásíríà:+ “Kì yóò wá sínú ìlú ńlá yìí,+ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ta ọfà kan sí ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi apata kò ó lójú, bẹ́ẹ̀ ni kì yòó mọ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì nà ró tì í.”’+ 34  “‘Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò gbà padà, kì yóò sì wá sínú ìlú ńlá yìí,’ ni àsọjáde Jèhófà.+ 35  ‘Dájúdájú, èmi yóò sì gbèjà+ ìlú ńlá yìí láti gbà á là nítorí tèmi+ àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.’”+ 36  Áńgẹ́lì+ Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti jáde lọ, ó sì ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n balẹ̀ nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà.+ Nígbà tí àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, họ́wù, òkú ni gbogbo wọ́n jẹ́ níbẹ̀.+ 37  Fún ìdí yìí, Senakéríbù+ ọba Ásíríà ṣí kúrò, ó sì padà lọ,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé Nínéfè.+ 38  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ó ti ń tẹrí ba ní ilé Nísírọ́kì+ ọlọ́run rẹ̀,+ Adiramélékì àti Ṣárésà, àwọn ọmọkùnrin tirẹ̀, fi idà ṣá a balẹ̀,+ wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì.+ Esari-hádónì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé