Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 36:1-22

36  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹrìnlá Hesekáyà Ọba pé Senakéríbù+ ọba Ásíríà+ gòkè wá gbéjà ko gbogbo ìlú ńlá olódi ti Júdà, ó sì tẹ̀ síwájú láti gbà wọ́n.+  Níkẹyìn, ọba Ásíríà rán Rábúṣákè+ láti Lákíṣì+ lọ sí Jerúsálẹ́mù,+ lọ bá Hesekáyà Ọba, pẹ̀lú ẹgbẹ́ ológun tí ó bùáyà, ó sì dúró jẹ́ẹ́ ní ọ̀nà omi+ ti odò adágún tí ń bẹ ní apá òkè+ ní òpópó pápá alágbàfọ̀.+  Nígbà náà ni Élíákímù+ ọmọkùnrin Hilikáyà, ẹni tí ń bójú tó agbo ilé, àti Ṣébínà+ akọ̀wé àti Jóà+ ọmọkùnrin Ásáfù+ akọ̀wé ìrántí,+ jáde tọ̀ ọ́ wá.  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sọ fún Hesekáyà pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá,+ ọba Ásíríà,+ wí: “Kí ni ohun ìgbọ́kànlé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé?+  Ìwọ sọ (ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ni) pé, ‘Ìmọ̀ràn àti agbára ńlá wà fún ogun.’+ Wàyí o, ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+  Wò ó! Ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé ìtìlẹyìn esùsú fífọ́ yìí,+ lé Íjíbítì,+ tí ó jẹ́ pé, bí ènìyàn bá fara tì í, ṣe ni yóò wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí yóò sì gún un. Bí Fáráò+ ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé e.+  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ìwọ sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni ẹni tí àwa gbẹ́kẹ̀ lé,’+ òun ha kọ́ ni ẹni tí Hesekáyà ti mú àwọn ibi gíga+ rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ yìí ni kí ẹ ti tẹrí ba’?”’+  Ǹjẹ́ nísinsìnyí, jọ̀wọ́, mú ohun ìdúró wá+ fún olúwa mi ọba Ásíríà,+ kí n sì fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin láti rí i bóyá ìwọ, níhà ọ̀dọ̀ rẹ, lè fi olùgun ẹṣin sórí wọn.+  Báwo wá ni ìwọ ṣe lè yí ojú gómìnà kan padà lára èyí tí ó kéré jù lọ nínú àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi,+ nígbà tí ìwọ, níhà ọ̀dọ̀ rẹ, gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Íjíbítì fún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti fún àwọn ẹlẹ́ṣin?+ 10  Wàyí o, ó ha jẹ́ láìgba ọlá àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo gòkè wá gbéjà ko ilẹ̀ yìí láti run ún? Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó wí fún mi pé,+ ‘Gòkè lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì run ún.’”+ 11  Látàrí èyí, Élíákímù+ àti Ṣébínà+ àti Jóà+ sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀wọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Síríà,+ nítorí àwa gbọ́; má sì bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè àwọn Júù+ ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri.”+ 12  Ṣùgbọ́n Rábúṣákè wí pé: “Ṣé olúwa yín àti ẹ̀yin ni olúwa mi rán mi sí láti bá sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni? Kì í ha ṣe sí àwọn ọkùnrin tí ó jókòó sórí ògiri, pé kí wọ́n lè jẹ ìgbọ̀nsẹ̀ ara wọn, kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”+ 13  Rábúṣákè sì ń bá a lọ ní dídúró,+ ó sì fi ohùn rara ké jáde ní èdè àwọn Júù,+ ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 14  Èyí ni ohun tí ọba wí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekáyà tàn yín jẹ,+ nítorí kò lè dá yín nídè.+ 15  Ẹ má sì jẹ́ kí Hesekáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+ wí pé: “Láìkùnà, Jèhófà yóò dá wa nídè.+ A kì yóò fi ìlú ńlá yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 16  Ẹ má fetí sí Hesekáyà, nítorí pé èyí ni ohun tí ọba Ásíríà wí: “Ẹ túúbá fún mi,+ kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá, kí olúkúlùkù sì máa jẹ láti inú àjàrà tirẹ̀ àti olúkúlùkù láti inú igi ọ̀pọ̀tọ́+ tirẹ̀, kí olúkúlùkù sì máa mu omi inú ìkùdu+ tirẹ̀, 17  títí èmi yóò fi wá, tí èmi yóò sì kó yín lọ ní ti tòótọ́ sí ilẹ̀ tí ó dà bí ilẹ̀ tiyín,+ ilẹ̀ ọkà àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti àwọn ọgbà àjàrà; 18  kí Hesekáyà má bàa dẹ yín lọ,+ wí pé, ‘Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò dá wa nídè.’ Olúkúlùkù ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ha ti dá ilẹ̀ tirẹ̀ nídè kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà bí?+ 19  Àwọn ọlọ́run Hámátì+ àti Áápádì+ dà? Àwọn ọlọ́run Séfáfáímù+ dà? Wọn ha sì ti dá Samáríà nídè kúrò lọ́wọ́ mi?+ 20  Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí tí ó tíì dá ilẹ̀ wọn nídè kúrò lọ́wọ́ mi,+ tí Jèhófà yóò fi dá Jerúsálẹ́mù nídè kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+ 21  Wọ́n sì ń bá a lọ ní dídákẹ́, wọn kò sì dá a lóhùn ọ̀rọ̀ kan,+ nítorí àṣẹ ọba ni pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 22  Ṣùgbọ́n Élíákímù+ ọmọkùnrin Hilikáyà, ẹni tí ń bójú tó agbo ilé,+ àti Ṣébínà+ akọ̀wé àti Jóà+ ọmọkùnrin Ásáfù akọ̀wé ìrántí tọ Hesekáyà wá ti àwọn ti ẹ̀wù gbígbọ̀nya,+ wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè+ fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé