Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 35:1-10

35  Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà,+ pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.+  Láìkùnà, yóò yọ ìtànná,+ ní ti tòótọ́ yóò fi tayọ̀tayọ̀ kún fún ìdùnnú àti fífi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.+ Ògo Lẹ́bánónì pàápàá ni a ó fi fún un,+ ọlá ńlá Kámẹ́lì+ àti ti Ṣárónì.+ Àwọn kan yóò wà tí yóò rí ògo Jèhófà,+ ọlá ńlá Ọlọ́run wa.+  Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lera lókun, ẹ sì mú àwọn eékún tí ń gbò yèpéyèpé le gírígírí.+  Ẹ sọ fún àwọn tí ń ṣàníyàn nínú ọkàn-àyà+ pé: “Ẹ jẹ́ alágbára.+ Ẹ má fòyà.+ Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín yóò wá tòun ti ẹ̀san,+ Ọlọ́run yóò wá, àní tòun ti ìsanpadà.+ Òun fúnra rẹ̀ yóò wá, yóò sì gbà yín là.”+  Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là,+ etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí.+  Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe,+ ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.+ Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.  Ilẹ̀ tí ooru ti mú gbẹ hán-ún hán-ún yóò sì ti wá rí bí odò adágún tí ó kún fún esùsú, ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò sì ti wá rí bí àwọn ìsun omi.+ Ibi gbígbé àwọn akátá,+ ibi ìsinmi wọn, ni koríko tútù yóò wà pẹ̀lú esùsú àti òrépèté.+  Dájúdájú, òpópó+ kan yóò sì wá wà níbẹ̀, àní ọ̀nà kan; Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́ sì ni a ó máa pè é.+ Aláìmọ́ kì yóò gbà á kọjá.+ Yóò sì wà fún ẹni tí ń rìn lójú ọ̀nà, òmùgọ̀ kankan kì yóò sì rìn káàkiri lórí rẹ̀.  Kìnnìún kankan kì yóò sí níbẹ̀, irú apẹranjẹ ẹranko ẹhànnà kankan kì yóò sì wá sórí rẹ̀.+ Ìkankan kì yóò sí níbẹ̀;+ àwọn tí a tún rà sì ni yóò máa rìn níbẹ̀.+ 10  Àní àwọn tí Jéhòfá tún rà padà yóò sì padà dé,+ wọn yóò sì fi igbe ìdùnnú wá sí Síónì dájúdájú;+ ayọ̀ yíyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin yóò sì wà ní orí wọn.+ Ọwọ́ wọn yóò sì tẹ ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀, ẹ̀dùn-ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé