Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 34:1-17

34  Ẹ sún mọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, láti gbọ́;+ àti ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè,+ ẹ fetí sílẹ̀. Kí ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀ fetí sílẹ̀,+ ilẹ̀ eléso+ àti gbogbo èso rẹ̀.+  Nítorí pé Jèhófà ní ìkannú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,+ àti ìhónú sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.+ Òun yóò yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun; yóò fi wọ́n fún ìfikúpa.+  A ó sì sọ àwọn tí a pa nínú wọn síta; àti ní ti òkú wọn, àyán wọn yóò gòkè;+ àwọn òkè ńláńlá yóò sì yọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn.+  Gbogbo àwọn tí í ṣe ara ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run yóò sì jẹrà dànù.+ A ó sì ká ọ̀run jọ,+ gẹ́gẹ́ bí ìwé àkájọ; gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn yóò sì kíweje, gan-an gẹ́gẹ́ bí ewé ti ń kíweje kúrò lára àjàrà àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kíweje kúrò lára igi ọ̀pọ̀tọ́.+  “Nítorí ó dájú pé a ó rin idà+ mi gbingbin ní ọ̀run. Wò ó! Yóò sọ̀ kalẹ̀ wá sórí Édómù,+ àti sórí àwọn ènìyàn tí mo ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun+ nínú ìdájọ́ òdodo.  Jèhófà ní idà kan; a óò mú un kún fún ẹ̀jẹ̀;+ a óò mú un rin ṣìnkìn fún ọ̀rá, fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ àgbò àti òbúkọ, fún ọ̀rá+ kíndìnrín àwọn àgbò. Nítorí pé Jèhófà ní ẹbọ ní Bósírà, àti ìfikúpa ńlá ní ilẹ̀ Édómù.+  Àwọn akọ màlúù ìgbẹ́+ yóò sì sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú wọn, àti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù pẹ̀lú àwọn alágbára;+ ilẹ̀ wọn yóò sì rin gbingbin fún ẹ̀jẹ̀, a ó sì mú ekuru wọn gan-an rin ṣìnkìn fún ọ̀rá.”+  Nítorí pé Jèhófà ní ọjọ́ ẹ̀san,+ ọdún àwọn ẹ̀san iṣẹ́ fún ẹjọ́ lórí Síónì.+  Àwọn ọ̀gbàrá rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀, ekuru rẹ̀ ni a ó sì sọ di imí ọjọ́; ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì dà bí ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tí ń jó.+ 10  Ní òru tàbí ní ọ̀sán, a kì yóò pa á; fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èéfín rẹ̀ yóò máa gòkè.+ Láti ìran dé ìran ni yóò gbẹ hán-ún hán-ún;+ títí láé àti láéláé, kò sí ẹni tí yóò gbà á kọjá.+ 11  Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ yóò sì gbà á, àwọn òwìwí elétí gígùn àti ẹyẹ ìwò pàápàá yóò sì máa gbé inú rẹ̀;+ òun yóò sì na okùn ìdiwọ̀n+ òfìfo àti àwọn òkúta òfò sórí rẹ̀. 12  Àwọn ọ̀tọ̀kùlú rẹ̀—kò sí ìkankan níbẹ̀ tí wọn yóò pè wá sí ipò ọba, àní gbogbo ọmọ aládé rẹ̀ yóò sì di aláìjámọ́ nǹkan kan.+ 13  Ẹ̀gún yóò hù sórí àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀, èsìsì àti èpò ẹlẹ́gùn-ún yóò hù sí àwọn ibi olódi rẹ̀;+ yóò sì di ibi gbígbé fún àwọn akátá,+ àgbàlá fún àwọn ògòǹgò.+ 14  Àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò sì bá àwọn ẹranko tí ń hu pàdé, ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́+ pàápàá yóò sì pe alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé ibẹ̀ ni ẹyẹ aáṣẹ̀rẹ́ yóò fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ sí, tí yóò sì ti rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀.+ 15  Ibẹ̀ ni ejò ọlọ́fà kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí, tí ó sì yé ẹyin sí, yóò sì pa ẹyin, yóò sì kó wọn jọpọ̀ sábẹ́ òjìji rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ibẹ̀ ni àwọn àwòdì+ yóò kó ara wọn jọpọ̀ sí, olúkúlùkù pẹ̀lú èkejì rẹ̀. 16  Ẹ wá a fún ara yín nínú ìwé+ Jèhófà, kí ẹ sì kà á sókè: kò sí ọ̀kan tí ó dàwáàrí nínú wọn;+ ní ti tòótọ́, olúkúlùkù wọn kò kùnà láti ní ẹnì kejì rẹ̀, nítorí pé ẹnu Jèhófà ni ó pa àṣẹ náà,+ ẹ̀mí rẹ̀ sì ni ó kó wọn jọpọ̀.+ 17  Àti pé, Òun ni ó ṣẹ́ kèké fún wọn, ọwọ́ rẹ̀ sì ni ó fi fi okùn ìdiwọ̀n+ pín ibẹ̀ fún wọn. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò gbà á; ìran dé ìran ni wọn yóò máa gbé inú rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé