Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 33:1-24

33  Ègbé ni fún ìwọ tí ń fini ṣe ìjẹ, láìjẹ́ pé a fi ìwọ alára ṣe ìjẹ, àti fún ìwọ tí ń ṣe àdàkàdekè, láìjẹ́ pé àwọn mìíràn ṣe àdàkàdekè sí ọ!+ Gbàrà tí o bá ṣe tán gẹ́gẹ́ bí afiniṣèjẹ, a ó fi ọ́ ṣe ìjẹ.+ Gbàrà tí o bá parí ṣíṣe àdàkàdekè, wọn yóò ṣe àdàkàdekè sí ọ.+  Jèhófà, fi ojú rere hàn sí wa.+ Ọ̀dọ̀ rẹ ni a fi ìrètí wa sí.+ Di apá+ wa ní òròòwúrọ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni, di ìgbàlà wa ní àkókò wàhálà.+  Ní gbígbọ́ ìró yánpọnyánrin, àwọn ènìyàn sá lọ.+ Ní dídìde tí ìwọ dìde, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́n ká.+  Ohun ìfiṣèjẹ+ yín ni a ó sì kó jọ ní tòótọ́ bí aáyán nígbà tí wọ́n bá ń kóra jọpọ̀, bí ìrọ́gìrọ́gìrọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ eéṣú tí ń rọ́ luni.+  Dájúdájú, Jèhófà ni a óò gbé ga sókè,+ nítorí ó ń gbé ní ibi gíga.+ Yóò fi ìdájọ́ òdodo àti òdodo kún Síónì.+  Ìṣeégbẹ́kẹ̀lé àwọn àkókò rẹ yóò sì jẹ́ ọ̀pọ̀ yanturu ìgbàlà+—ọgbọ́n àti ìmọ̀,+ ìbẹ̀rù Jèhófà,+ èyí tí í ṣe ìṣúra ti ẹni tí ó ni ín.  Wò ó! Àní àwọn akọni wọn ti ké jáde ní ojú pópó; àní àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà+ yóò sunkún lọ́nà kíkorò.  Àwọn òpópó ni a ti sọ di ahoro;+ ẹni tí ń gba ipa ọ̀nà kọjá ti ṣíwọ́.+ Ó ti ba májẹ̀mú jẹ́;+ ó ti fojú pa àwọn ìlú ńlá rẹ́;+ kò gba ti ẹni kíkú rò.+  Ilẹ̀ náà ti wọnú ìṣọ̀fọ̀, ó ti rọ dànù.+ Lẹ́bánónì ti tẹ́;+ ó ti rà dànù. Ṣárónì+ ti dà bí pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀; Báṣánì àti Kámẹ́lì sì ń gbọn ewé wọn dànù.+ 10  “Ṣe ni èmi yóò dìde wàyí,”+ ni Jèhófà wí, “ṣe ni èmi yóò gbé ara mi ga wàyí;+ ṣe ni èmi yóò gbé ara mi sókè wàyí.+ 11  Ẹ lóyún koríko gbígbẹ;+ ẹ óò bí àgékù pòròpórò. Ẹ̀mí yín, gẹ́gẹ́ bí iná,+ yóò jẹ yín run.+ 12  Àwọn ènìyàn yóò sì dà bí ìjóná ẹfun. Bí àwọn ẹ̀gún tí a gé kúrò, a ó ti iná bọ̀ wọ́n.+ 13  Ẹ gbọ́, ẹ̀yin tí ẹ wà ní ibi jíjìnnàréré, ohun tí èmi yóò ṣe!+ Kí ẹ sì mọ agbára ńlá mi,+ ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí. 14  Ní Síónì, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ti wà nínú ìbẹ̀rùbojo;+ ìgbọ̀nrìrì ti gbá àwọn apẹ̀yìndà mú,+ pé: ‘Ta ni nínú wa tí ó lè bá iná tí ń jẹni run gbé fún ìgbà èyíkéyìí?+ Ta ni nínú wà tí ó lè bá àgbáàràgbá iná wíwà pẹ́ títí gbé fún ìgbà èyíkéyìí?’+ 15  “Ẹnì kan wà tí ń rìn nínú òdodo tí ń bá a lọ títí,+ tí ó sì ń sọ ohun dídúróṣánṣán,+ tí ó ń kọ èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu, èyí tí ó wá láti inú jìbìtì,+ tí ó ń gbọn ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú dídi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ mú,+ tí ó ń di etí rẹ̀ sí fífetísí ìtàjẹ̀sílẹ̀, tí ó sì ń pa ojú rẹ̀ dé kí ó má bàa rí ohun tí ó burú.+ 16  Òun ni ẹni tí yóò máa gbé àwọn ibi gíga pàápàá;+ ibi gíga ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ àwọn ibi àpáta gàǹgà tí ó ṣòro láti dé.+ A ó fi oúnjẹ rẹ̀ fún un;+ ìpèsè omi rẹ̀ yóò jẹ́ aláìkùnà.”+ 17  Ojú rẹ yóò rí ọba kan nínú ìrẹwà rẹ̀;+ wọn yóò rí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.+ 18  Ọkàn-àyà rẹ yóò sọ̀rọ̀ ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́+ lórí ohun tí ń da jìnnìjìnnì boni pé: “Akọ̀wé dà? Ẹni tí ń san nǹkan fúnni dà?+ Ẹni tí ń ka àwọn ilé gogoro dà?”+ 19  Ìwọ kì yóò rí àwọn aláfojúdi ènìyàn kankan, àwọn ènìyàn tí èdè wọ́n jinlẹ̀ jù láti fetí sí, àwọn tí ahọ́n wọn ń kólòlò tí ìwọ kì yóò lóye wọn.+ 20  Wo Síónì,+ ìlú àwọn àkókò àjọyọ̀ wa!+ Ojú rẹ yóò rí Jerúsálẹ́mù tí í ṣe ibi gbígbé tí kò ní ìyọlẹ́nu, àgọ́ tí ẹnikẹ́ni kì yóò ká kúrò.+ A kì yóò fa àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ rẹ̀ tu láé, a kì yóò sì fa ìkankan lára àwọn ìjàrá rẹ̀ já sí méjì.+ 21  Ṣùgbọ́n níbẹ̀, Jèhófà, Ọba Ọlọ́lá,+ yóò jẹ́ ibi àwọn odò fún wa,+ ibi àwọn ipa odò tí ó gbòòrò. Ọ̀wọ́ ọkọ̀ alájẹ̀ kankan kì yóò gba orí rẹ̀, ọkọ̀ òkun ọlọ́lá ńlá kankan kì yóò sì gba orí rẹ̀ kọjá. 22  Nítorí pé Jèhófà ni Onídàájọ́+ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀,+ Jèhófà ni Ọba+ wa; òun fúnra rẹ̀ yóò gbà wá là.+ 23  Àwọn ìjàrá rẹ yóò rọ̀ dirodiro; wọn kì yóò di òpó ìgbòkun ọkọ̀ mú ní nínàró ṣánṣán; wọn kò ta ìgbòkun. Ní àkókò yẹn, àní ọ̀pọ̀ yanturu ohun ìfiṣèjẹ ni a óò pín; àwọn tí ó yarọ pàápàá yóò piyẹ́ ohun púpọ̀+ ní ti tòótọ́. 24  Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”+ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé