Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 32:1-20

32  Wò ó! Ọba+ kan yóò jẹ fún òdodo;+ àti ní ti àwọn ọmọ aládé,+ wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.  Olúkúlùkù yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò,+ bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi,+ bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.+  Ojú àwọn tí ń ríran kì yóò sì lẹ̀ pọ̀, àní etí àwọn tí ń gbọ́ràn yóò sì tẹ́ sílẹ̀.+  Àní ọkàn-àyà àwọn tí ń kánjú jù yóò sì ronú nípa ìmọ̀,+ àní ahọ́n àwọn akólòlò yóò ṣe kíá ní sísọ àwọn ohun ṣíṣe kedere.+  A kì yóò tún pe òpònú ní ọ̀làwọ́ mọ́; àti ní ti oníwàkíwà, a kì yóò sọ pé ó jẹ́ ọ̀tọ̀kùlú;+  nítorí pé òpònú alára yóò máa sọ ọ̀rọ̀ òpònú lásán-làsàn,+ àní ọkàn-àyà rẹ̀ yóò sì máa ṣiṣẹ́ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,+ láti máa ṣiṣẹ́ ìpẹ̀yìndà+ àti láti máa sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ sí Jèhófà, láti mú kí ọkàn àwọn tí ebi ń pa ṣófo,+ ó sì ń mú kí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ pàápàá ṣe aláìní ohun mímu.  Ní ti oníwàkíwà, àwọn ohun èlò rẹ̀ burú;+ òun fúnra rẹ̀ ti fúnni ní ìmọ̀ràn fún ìwà àìníjàánu,+ láti fi àwọn àsọjáde èké fọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ bàjẹ́,+ àní nígbà tí òtòṣì ń sọ ohun tí ó tọ́.  Ní ti ẹni tí ó jẹ́ ọ̀làwọ́, ohun ọ̀làwọ́ ni ó fúnni ní ìmọ̀ràn lé lórí; òun fúnra rẹ̀ yóò sì dìde láti fara mọ́ àwọn ohun ọ̀làwọ́.+  “Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ wà ní ìdẹ̀rùn, ẹ dìde, ẹ fetí sí ohùn mi!+ Ẹ̀yin ọmọbìnrin tí kò bìkítà, ẹ fi etí sí àsọjáde mi! 10  Láàárín ọdún kan àti ọjọ́ mélòó kan, ṣìbáṣìbo yóò bá ẹ̀yin aláìbìkítà,+ nítorí pé kíká èso àjàrà yóò ti wá sí òpin, ṣùgbọ́n kò sí àkójọ èso tí yóò wọlé wá.+ 11  Ẹ wárìrì, ẹ̀yin obìnrin tí ó wà ní ìdẹ̀rùn! Kí ṣìbáṣìbo bá yín, ẹ̀yin aláìbìkítà! Ẹ bọ́ṣọ, kí ẹ sì tú ara yín sí ìhòòhò, kí ẹ sì sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ abẹ́nú.+ 12  Ẹ lu ara yín ní ọmú nínú ìdárò+ nítorí àwọn pápá fífani-lọ́kàn-mọ́ra,+ nítorí àjàrà tí ń so èso. 13  Lórí ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi, ẹ̀gún lásán-làsàn àti àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún ọ̀gàn ni ó ń hù jáde,+ nítorí tí wọ́n wà lórí gbogbo ilé ayọ̀ ńláǹlà, bẹ́ẹ̀ ni, ìlú tí ayọ̀ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́.+ 14  Nítorí pe ilé gogoro ibùgbé pàápàá ni a ti ṣá tì,+ àní riworiwo ìlú ńlá ni a ti pa tì; Ófélì+ àti ilé ìṣọ́ pàápàá ti di èkìdá àwọn pápá, fún àkókò tí ó lọ kánrin ni yóò jẹ́ ayọ̀ ńláǹlà àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, pápá ìjẹko agbo ẹran ọ̀sìn; 15  títí di ìgbà tí a óò tú ẹ̀mí jáde sórí wa láti ibi gíga lókè,+ tí aginjù yóò sì di ọgbà igi eléso, tí a ó sì ka ọgbà igi eléso náà sí igbó gidi.+ 16  “Dájúdájú, ìdájọ́ òdodo yóò sì máa gbé aginjù, àní òdodo yóò sì máa gbé inú ọgbà igi eléso.+ 17  Iṣẹ́ òdodo tòótọ́ yóò sì di àlàáfíà;+ iṣẹ́ ìsìn òdodo tòótọ́ yóò sì di ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 18  Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.+ 19  Dájúdájú, yóò sì rọ yìnyín nígbà tí igbó bá lọ sílẹ̀,+ tí ìlú ńlá náà sì di rírẹ̀sílẹ̀ ní ipò ìrẹ̀wálẹ̀.+ 20  “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ń fún irúgbìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo omi,+ tí ń rán ẹsẹ̀ akọ màlúù àti ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jáde.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé