Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 31:1-9

31  Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì fún ìrànwọ́,+ àwọn tí ó gbójú lé ẹṣin lásán-làsàn,+ tí wọ́n sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun,+ nítorí tí wọ́n pọ̀ níye, àti sínú ẹṣin ogun, nítorí tí wọ́n jẹ́ alágbára ńlá gan-an, ṣùgbọ́n tí wọn kò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, tí wọn kò sì wá Jèhófà tìkára rẹ̀.+  Òun sì gbọ́n pẹ̀lú,+ yóò sì mú ohun tí ó kún fún ìyọnu àjálù wá,+ kì yóò sì kó ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ jẹ;+ ṣe ni òun yóò sì dìde sí ilé àwọn aṣebi+ àti lòdì sí ìrànwọ́ àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.+  Àmọ́ ṣá o, ará ayé+ ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì í sì í ṣe Ọlọ́run; ẹran ara+ sì ni àwọn ẹṣin wọn, wọn kì í sì í ṣe ẹ̀mí. Jèhófà alára yóò sì na ọwọ́ rẹ̀, ṣe ni ẹni tí ń fúnni ní ìrànlọ́wọ́ yóò sì kọsẹ̀,+ ẹni tí a ń ràn lọ́wọ́ yóò sì ṣubú, lẹ́ẹ̀kan náà gbogbo wọn yóò sì wá sí òpin.  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ti ń kùn hùn-ùn, àní ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀,+ lórí ẹran ọdẹ rẹ̀, nígbà tí a bá pe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn olùṣọ́ àgùntàn jáde sí i, láìka ohùn wọn sí, kì yóò jáyà, láìka arukutu wọn sí, kì yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀; bákan náà ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sọ̀ kalẹ̀ wá láti ja ogun ní tìtorí Òkè Ńlá Síónì àti ní tìtorí òkè kékeré rẹ̀.+  Bí àwọn ẹyẹ tí ń fò, bákan náà ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò gbèjà Jerúsálẹ́mù.+ Ní gbígbèjà rẹ̀, dájúdájú, òun yóò dá a nídè pẹ̀lú.+ Ní dídá a sí, òun yóò mú kí ó sá àsálà pẹ̀lú.”  “Ẹ padà+ sọ́dọ̀ Ẹni tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lọ jinlẹ̀ nínú ìdìtẹ̀ sí.+  Nítorí pé ní ọjọ́ yẹn, olúkúlùkù yóò kọ àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí, èyí tí a fi fàdákà ṣe àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò níye lórí, èyí tí a fi wúrà ṣe,+ èyí tí ọwọ́ yín ti ṣe fún ara yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀.+  Ará Ásíríà yóò sì ṣubú nípa idà, tí kì í ṣe ti ènìyàn; idà kan, tí kì í ṣe ti ará ayé sì ni yóò jẹ ẹ́ run.+ Yóò sì sá lọ nítorí idà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ yóò wá wà fún òpò àfipámúniṣe pàápàá.  Àpáta gàǹgà rẹ̀ yóò sì kọjá lọ nítorí jìnnìjìnnì tí ó bùáyà, àti nítorí àmì àfiyèsí,+ àwọn ọmọ aládé rẹ̀ yóò jáyà,” ni àsọjáde Jèhófà, ẹni tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ wà ní Síónì, tí ìléru+ rẹ̀ sì wà ní Jerúsálẹ́mù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé