Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 30:1-33

30  “Ègbé ni fún àwọn alágídí ọmọ,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn tí ó ti ṣe tán láti mú ète ṣẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá;+ àti láti da ẹbọ ìtasílẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí mi, kí wọ́n lè fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀;+  àwọn tí ó mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì,+ tí wọn kò sì wádìí lẹ́nu mi,+ láti wá ibi ààbò nínú ibi odi agbára Fáráò àti láti sá di òjìji Íjíbítì!+  Àní ibi odi agbára Fáráò yóò jẹ́ ìdí tí ìtìjú yóò fi bá yín,+ ibi ìsádi lábẹ́ òjìji Íjíbítì yóò sì jẹ́ okùnfà ìtẹ́lógo.+  Nítorí pé àwọn ọmọ aládé rẹ̀ ti wà ní Sóánì,+ àwọn aṣojú rẹ̀ sì dé Hánésì pàápàá.  Dájúdájú, ìtìjú yóò bá olúkúlùkù nítorí àwọn ènìyàn tí kò ṣeni láǹfààní kankan, àwọn tí kò ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan àti àwọn tí kò ṣe àǹfààní kankan, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ ìdí fún ìtìjú àti okùnfa ẹ̀gàn pẹ̀lú.”+  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí àwọn ẹranko gúúsù:+ La ilẹ̀ wàhálà+ àti àwọn ipò ìnira kọjá, ti kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn tí ń kùn hùn-ùn, ti paramọ́lẹ̀ àti ejò oníná tí ń fò,+ èjìká àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ti dàgbà tán ni wọ́n fi ru àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn, iké àwọn ràkúnmí+ sì ni wọ́n fi ru àwọn ìpèsè wọn. Wọn kì yóò já sí àǹfààní kankan fún àwọn ènìyàn náà.  Asán gbáà sì ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì yóò sì ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan.+ Nítorí náà, mo ti pe ẹni yìí ní: “Ráhábù+—wọ́n wà fún jíjókòó jẹ́ẹ́.”  “Wá nísinsìnyí, kọ ọ́ sára wàláà pẹ̀lú wọn, kí o sì ṣàkọọ́lẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé pàápàá,+ kí ó lè jẹ́ fún ọjọ́ ọ̀la, láti ṣe ẹ̀rí fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  Nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n,+ àwọn aláìlóòótọ́ ọmọ,+ àwọn ọmọ tí kò fẹ́ gbọ́ òfin Jèhófà;+ 10  àwọn tí ó sọ fún àwọn tí ń rí pé, ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ rí,’ àti fún àwọn tí ń rí ìran pé, ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ rí ìran ohunkóhun tí ó jẹ́ títọ́+ sí wa. Ẹ máa sọ àwọn ohun dídùn mọ̀nràn-ìn mọran-in fún wa; ẹ máa rí ìran àwọn ohun ìtannijẹ.+ 11  Ẹ yà kúrò lójú ọ̀nà; ẹ yapa kúrò ní ipa ọ̀nà.+ Ẹ mú kí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wá sí òpin kìkì ní tìtorí wa.’”+ 12  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wí: “Nítorí kíkọ̀ tí ẹ kọ ọ̀rọ̀ yìí,+ níwọ̀n bí ẹ sì ti gbẹ́kẹ̀ lé jìbìtì lílù àti ohun békebèke, tí ẹ sì gbára lé e,+ 13  nítorí náà ni ìṣìnà yìí yóò ṣe jẹ́ sí yín bí abala tí ó ti là, tí ó máa tó wó lulẹ̀, ìwúsíta lára ògiri gíga sókè,+ ìwópalẹ̀ èyí tí ó lè dé lójijì, ní ìṣẹ́jú akàn.+ 14  Ṣe ni ẹnì kan yóò fọ́ ọ bí ìgbà tí a bá fọ́ ìṣà títóbi ti àwọn amọ̀kòkò,+ èyí tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́ láìsí pé ẹni náà dá a sí, tí yóò fi jẹ́ pé, lára ìfọ́síwẹ́wẹ́ rẹ̀, a kì yóò rí àpáàdì tí a ó fi wa iná láti ibi ìdáná tàbí láti fi ré omi láti àbàtà.”+ 15  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ wí: “Nípa pípadà wá àti sísinmi ni a ó fi gbà yín là. Agbára ńlá yín yóò sì wà nínú àìní ìyọlẹ́nu rárá àti nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé.”+ Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́.+ 16  Ẹ sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Rárá, ṣùgbọ́n àwa yóò sá lọ lórí ẹṣin!”+ Ìdí nìyẹn tí ẹ ó fi sá lọ. “Ẹṣin yíyára sì ni àwa yóò gùn!”+ Ìdí nìyẹn tí àwọn tí ń lépa yín yóò fi ara wọn hàn ní ẹni yíyára.+ 17  Ẹgbẹ̀rún yóò wárìrì ní tìtorí ìbáwí mímúná ẹnì kan;+ ní tìtorí ìbáwí mímúná ẹni márùn-ún, ẹ óò sá lọ títí ohun tí ẹ óò ṣẹ́ kù yóò fi rí bí òpó kan ní orí òkè ńlá àti bí àmì àfiyèsí kan lórí òkè kékeré.+ 18  Nítorí náà, Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín,+ nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín.+ Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.+ Aláyọ̀+ ni gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún un.+ 19  Nígbà tí àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Síónì+ yóò máa gbé ní Jerúsálẹ́mù,+ ìwọ kì yóò sunkún rárá.+ Láìkùnà, òun yóò fi ojú rere hàn sí ọ ní gbígbọ́ ìró igbe ẹkún rẹ; gbàrà tí ó bá gbọ́ ọ, yóò dá ọ lóhùn ní tòótọ́.+ 20  Ṣe ni Jèhófà yóò sì fún yín ní oúnjẹ tí í ṣe wàhálà àti omi tí í ṣe ìnilára;+ síbẹ̀, Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá kì yóò tún fi ara rẹ̀ pa mọ́, ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá.+ 21  Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà.+ Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ́ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.+ 22  Ohun tí a fi bo ère fífín rẹ tí a fi fàdákà+ ṣe àti ìbora fífúnpinpin ti ère dídà+ rẹ tí a fi wúrà+ ṣe sì ni ẹ ó sọ di ẹlẹ́gbin. Ìwọ yóò tú wọn ká.+ Bí obìnrin tí ń ṣe nǹkan oṣù, ìwọ yóò wí fún un pé: “Ìdọ̀tí lásán-làsàn!”+ 23  Dájúdájú, òun yóò sì rọ òjò sí irúgbìn rẹ, èyí tí o fún sí ilẹ̀,+ àti gẹ́gẹ́ bí èso ilẹ̀, èyíinì ni oúnjẹ, tí yóò di sísanra àti olóròóró.+ Ní ọjọ́ yẹn, ohun ọ̀sìn rẹ yóò máa jẹko ní pápá ìjẹko aláyè gbígbòòrò.+ 24  Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ti dàgbà tán, tí wọ́n ń ro ilẹ̀ yóò sì máa jẹ oúnjẹ ẹran tí a fi ewéko olómi-kíkan sí, èyí tí a fi ṣọ́bìrì+ àti àmúga fẹ́. 25  Àti lórí gbogbo òkè ńlá gíga àti lórí gbogbo òkè kékeré tí ó ga ni àwọn ìṣàn,+ àwọn kòtò omi yóò wà, ní ọjọ́ ìfikúpa tìrìgàngàn nígbà tí àwọn ilé gogoro bá ṣubú.+ 26  Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú yóò sì dà bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí ń ràn yòò; àní ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí ń ràn yòò yóò sì di ìlọ́po méje rẹ̀,+ bí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ méje, ní ọjọ́ tí Jèhófà di ìwópalẹ̀+ àwọn ènìyàn rẹ̀, àní tí ó ṣe ìwòsàn+ ọgbẹ́ ríronilára gógó tí ó wáyé nítorí ẹgba tí ó nani. 27  Wò ó! Orúkọ Jèhófà ń bọ̀ láti ibi jíjìnnàréré, ó ń jó pẹ̀lú ìbínú+ rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọsánmà ṣíṣúdùdù. Ní ti ètè rẹ̀, ó kún fún ìdálẹ́bi, ahọ́n rẹ̀ sì dà bí iná tí ń jẹni run.+ 28  Ẹ̀mí rẹ̀ sì dà bí àkúnya ọ̀gbàrá tí ó dé ọrùn,+ láti fi ajọ̀+ ohun àìníláárí fi àwọn orílẹ̀-èdè làkàlàkà síwá-sẹ́yìn; ìjánu+ tí ń mú kí ènìyàn rìn gbéregbère yóò sì wà ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn ènìyàn náà.+ 29  Ẹ óò wá ní orin+ kan bí èyí tí a ń kọ ní òru tí ènìyàn sọ ara rẹ̀ di mímọ́ fún àjọyọ̀,+ àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà bí ti ẹni tí ń rìn tòun ti fèrè+ láti dé orí òkè ńlá Jèhófà,+ àní dé orí Àpáta Ísírẹ́lì.+ 30  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì mú kí a gbọ́ iyì ohùn rẹ̀,+ yóò sì mú kí a rí ìsọ̀kalẹ̀ apá rẹ̀,+ nínú híhó ìbínú+ àti ọwọ́ iná tí ń jẹni run+ àti òjò òjijì apọnmùúmùú àti ìjì òjò+ àti àwọn òkúta yìnyín.+ 31  Nítorí pé ní tìtorí ohùn Jèhófà, Ásíríà ni a óò kó ìpayà bá;+ àní òun yóò fi ọ̀gọ lù ú.+ 32  Gbogbo ìfìlàkàlàkà ọ̀pá ìfinani rẹ̀, èyí tí Jèhófà yóò mú kí ó sọ̀ kalẹ̀ sára Ásíríà yóò sì jẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlù tanboríìnì àti àwọn háàpù+ dájúdájú; àwọn ìjà ogun tí a ti ń ju àwọn ohun ìjà fìrìfìrì sì ni òun yóò fi bá wọn jà ní ti tòótọ́.+ 33  Nítorí pé a ti ṣètò Tófétì+ rẹ̀ ní àkókò àìpẹ́ yìí; a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú fún ọba tìkára rẹ̀.+ Ó ti mú kí ìtòjọpelemọ rẹ̀ jinlẹ̀. Iná àti igi pọ̀ yanturu. Èémí Jèhófà, bí ọ̀gbàrá imí ọjọ́, ń jó o.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé