Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 29:1-24

29  “Ègbé ni fún Áríélì,+ fún Áríélì, ìlú tí Dáfídì dó sí!+ Ẹ fi ọdún kún ọdún; ẹ jẹ́ kí àwọn àjọyọ̀+ lọ yí ká.  Ṣe ni èmi yóò sì mú kí nǹkan le dan-in dan-in+ fún Áríélì, ìṣọ̀fọ̀ àti ìdárò+ yóò sì wà, yóò sì dà bí ibi ìdáná pẹpẹ Ọlọ́run+ fún mi.  Èmi yóò sì dó tì ọ́ ní ìhà gbogbo, èmi yóò sì fi igi ọgbà sàga tì ọ́, èmi yóò sì gbé àwọn agbàrà dìde tì ọ́.+  Ìwọ yóò sì di rírẹ̀sílẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni ìwọ yóò ti máa sọ̀rọ̀, bí ẹni pé láti inú ekuru sì ni àsọjáde rẹ yóò ti máa dún lọ́nà rírẹlẹ̀.+ Ohùn rẹ yóò sì dà bí ti abẹ́mìílò àní láti inú ilẹ̀, láti inú ekuru sì ni àsọjáde rẹ yóò ti máa ké ṣíoṣío.+  Ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ó jẹ́ àjèjì sí ọ yóò sì dà bí ekuru lẹ́búlẹ́bú,+ ogunlọ́gọ̀ àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀+ yóò sì dà bí ìyàngbò tí ń kọjá lọ.+ Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ìṣẹ́jú akàn, lójijì.+  Láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni ìwọ yóò ti gba àfiyèsí pẹ̀lú ààrá àti pẹ̀lú ìmìtìtì àti pẹ̀lú ìró ńlá, ẹ̀fúùfù oníjì àti ìjì líle, àti ọwọ́ iná tí ń jẹni run.”+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ bí ẹni pé ojú àlá ni, nínú ìran òru, ní ti ogunlọ́gọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ń bá Áríélì ja ogun,+ àní gbogbo àwọn tí ń bá a ja ogun, àti àwọn ilé gogoro ìsàgatì tí ń bẹ lòdì sí i àti àwọn tí ń mú nǹkan le dan-in dan-in fún un.+  Bẹ́ẹ̀ ni, yóò ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa lá àlá, sì kíyè sí i, ó ń jẹun, ó sì jí ní tòótọ́, ọkàn rẹ̀ sì ṣófo;+ àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá, sì kíyè sí i, ó ń mu omi, ó sì jí ní tòótọ́, sì kíyè sí i, ó rẹ̀ ẹ́, ọkàn rẹ̀ sì gbẹ táútáú; báyìí ni yóò rí fún ogunlọ́gọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ń bá Òkè Ńlá Síónì ja ogun.+  Ẹ dúró pẹ́, kí kàyéfì sì ṣe yín;+ ẹ sọ ara yín di afọ́jú, kí ẹ sì fọ́jú.+ Wọ́n ti yó,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú wáìnì; wọ́n ń rìn tàgétàgé, ṣùgbọ́n kì í ṣe nítorí ọtí tí ń pani.+ 10  Nítorí pé Jèhófà ti da ẹ̀mí oorun àsùnwọra+ lù yín; ó sì pa ojú yín dé, tí í ṣe àwọn wòlíì,+ ó sì ti bo orí yín pàápàá,+ tí í ṣe àwọn olùríran.+ 11  Ìran ohun gbogbo sì dà bí ọ̀rọ̀ ìwé tí a ti fi èdìdì dì fún yín,+ èyí tí wọ́n fi fún ẹni tí ó mọ̀wé, pé: “Jọ̀wọ́, ka èyí sókè,” yóò sì sọ pé: “Èmi kò lè kà á, nítorí pé a ti fi èdìdì dì í”;+ 12  a ó sì fi ìwé náà fún ẹni tí kò mọ̀wé, ẹnì kan wí pé: “Jọ̀wọ́, ka èyí sókè,” yóò sì sọ pé: “Èmi kò mọ̀wé rárá.” 13  Jèhófà sì sọ pé: “Nítorí ìdí náà pé àwọn ènìyàn yìí ti fi ẹnu wọn sún mọ́ mi, tí wọ́n sì ti fi kìkì ètè wọn yìn mí lógo,+ tí wọ́n sì ti mú ọkàn-àyà wọn pàápàá lọ jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ mi,+ tí ìbẹ̀rù tí wọ́n ní fún mi sì ti di àṣẹ ènìyàn tí wọ́n fi ń kọ́ni,+ 14  nítorí náà, èmi rèé, Ẹni tí yóò tún gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà àgbàyanu pẹ̀lú àwọn ènìyàn yìí,+ lọ́nà àgbàyanu àti pẹ̀lú ohun àgbàyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n wọn yóò sì ṣègbé, àní òye àwọn olóye wọn yóò sì fi ara rẹ̀ pa mọ́.”+ 15  Ègbé ni fún àwọn tí ń lọ jinlẹ̀-jinlẹ̀ nínú fífi ète pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà tìkára rẹ̀,+ àti àwọn tí iṣẹ́ wọ́n ti wáyé ní ibi tí ó ṣókùnkùn,+ nígbà tí wọ́n ń sọ pé: “Ta ní ń rí wa, ta sì ni ó mọ̀ nípa wa?”+ 16  Ẹ wo bí ìwà àyídáyidà yín ti pọ̀ tó! Ṣé ó yẹ kí a ka amọ̀kòkò sí ọ̀kan náà pẹ̀lú amọ̀?+ Nítorí pé, ṣé ó yẹ kí ohun tí a ṣe sọ nípa ẹni tí ó ṣe é pé: “Òun kọ́ ni ó ṣe mí”?+ Ṣé ohun náà tí a ṣẹ̀dá yóò sì sọ ní tòótọ́ nípa ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ pé: “Kò fi òye hàn”?+ 17  Kì í ha ṣe kìkì àkókò kúkúrú gan-an ni ó ṣẹ́ kù tí a ó sì sọ Lẹ́bánónì di ọgbà igi eléso,+ tí a ó sì ka ọgbà igi eléso náà sí ọ̀kan náà pẹ̀lú igbó?+ 18  Ní ọjọ́ yẹn, àwọn adití yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé náà+ dájúdájú, ojú àwọn afọ́jú pàápàá yóò sì ríran nínú ìṣúdùdù àti nínú òkùnkùn.+ 19  Ṣe ni àwọn ọlọ́kàn tútù+ yóò sì mú ayọ̀ yíyọ̀ wọn pọ̀ sí i nínú Jèhófà tìkára rẹ̀, àní àwọn òtòṣì nínú aráyé yóò sì kún fún ìdùnnú nínú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ 20  nítorí pé afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ yóò dé òpin rẹ̀,+ afọ́nnu yóò sì wá sí òpin rẹ̀,+ gbogbo àwọn tí ó wà lójúfò láti ṣe ìpalára+ sì ni a óò ké kúrò, 21  àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ènìyàn mú un wọnú ẹ̀ṣẹ̀,+ àti àwọn tí ń dẹ ìjẹ̀ sílẹ̀ de ẹni náà tí ń fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ẹnubodè,+ àti àwọn tí ń fi òfìfo ìjiyàn ti olódodo sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.+ 22  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún ilé Jékọ́bù, ẹni tí ó tún Ábúráhámù rà padà:+ “Ojú kì yóò ti Jékọ́bù nísinsìnyí, bẹ́ẹ̀ ni ojú rẹ̀ kì yóò di ràndánràndán nísinsìnyí;+ 23  nítorí pé nígbà tí ó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, ní àárín rẹ̀,+ wọn yóò sọ orúkọ mi di mímọ́,+ dájúdájú, wọn yóò sọ Ẹni Mímọ́ Jékọ́bù+ di mímọ́, wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ hàn fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 24  Àwọn tí ń ṣìnà nínú ẹ̀mí wọn yóò sì wá mọ òye ní tòótọ́, àwọn tí ń ráhùn pàápàá yóò sì gba ìtọ́ni.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé