Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 27:1-13

27  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà,+ tòun ti idà rẹ̀ líle tí ó tóbi,+ tí ó sì lágbára, yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí Léfíátánì,+ ejò tí ń yọ́ bẹ̀rẹ́,+ àní sí Léfíátánì, ejò wíwọ́, dájúdájú, òun yóò pa ẹran ńlá abàmì inú òkun,+ èyí tí ń bẹ nínú òkun.  Ní ọjọ́ yẹn, ẹ kọrin sí obìnrin náà+ pé: “Ọgbà àjàrà+ wáìnì tí ń yọ ìfóófòó!  Èmi, Jèhófà, yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.+ Ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú ni èmi yóò máa bomi rin ín.+ Kí ẹnikẹ́ni má bàa yí àfiyèsí rẹ̀ lòdì sí i, èmi yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ ní òru àti ní ọ̀sán pàápàá.+  Èmi kò ní ìhónú kankan.+ Ta ni yóò fún mi ní àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún+ àti èpò nínú ìjà ogun? Ṣe ni èmi yóò gbé ẹsẹ̀ lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Èmi yóò dáná sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan náà.+  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó di ibi odi agbára mi mú, kí ó wá àlàáfíà pẹ̀lú mi; àlàáfíà ni kí ó wá pẹ̀lú mi.”+  Ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, Jékọ́bù yóò ta gbòǹgbò, Ísírẹ́lì+ yóò mú ìtànná jáde, yóò sì rú jáde ní tòótọ́; ṣe ni wọn yóò wulẹ̀ fi èso kún ojú ilẹ̀ eléso.+  Ní ti ìkọlù ẹni tí ó kọlù ú, ṣé dandan ni kí ènìyàn kọlù ú ni? Tàbí kẹ̀, ní ti ìpakúpa àwọn tirẹ̀ tí a pa, ṣé dandan ni kí a pa á ni?+  Igbe ìdáyàfoni ni ìwọ yóò fi bá a fà á nígbà tí ìwọ bá rán an jáde. Òun yóò fi ẹ̀fúùfù òjijì rẹ̀ lé e jáde, èyí tí ó le ní ọjọ́ ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn.+  Nítorí náà, ọ̀nà yìí ni a ó gbà ṣètùtù fún ìṣìnà Jékọ́bù,+ èyí sì ni gbogbo èso náà nígbà tí ó bá mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò,+ nígbà tí ó bá sọ gbogbo òkúta pẹpẹ di òkúta ẹfun tí a ti lọ̀ lúúlúú, tí àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ àti àwọn pẹpẹ tùràrí kì yóò fi dìde dúró.+ 10  Nítorí pé ìlú ńlá olódi yóò wà láìsí olùgbé, ilẹ̀ ìjẹko ni a ó fi sílẹ̀ láìyà síbẹ̀, a ó sì pa á tì bí aginjù.+ Ibẹ̀ ni ọmọ màlúù yóò ti máa jẹko, ibẹ̀ sì ni yóò máa dùbúlẹ̀ sí; òun yóò sì jẹ àwọn ẹ̀tun rẹ̀ ní ti tòótọ́.+ 11  Nígbà tí àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ kéékèèké bá ti gbẹ dànù, àwọn obìnrin tí ń wọlé bọ̀ yóò ṣẹ́ wọn kúrò, wọn yóò fi iná sí wọn.+ Nítorí wọn kì í ṣe àwọn ènìyàn tí òye wọ́n múná dóko.+ Ìdí nìyẹn tí Olùṣẹ̀dá rẹ̀ kì yóò fi àánú hàn sí i rárá, tí Aṣẹ̀dá rẹ̀ kì yóò sì fi ojú rere hàn sí i rárá.+ 12  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò lu èso já bọ́,+ láti ibi ìṣàn Odò+ títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Íjíbítì,+ bẹ́ẹ̀ sì ni a ó ṣa ẹ̀yin fúnra yín ní ọ̀kan tẹ̀ lé èkejì,+ ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì. 13  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé fífun ìwo ńlá+ yóò ṣẹlẹ̀, àwọn tí yóò sì ṣègbé ní ilẹ̀ Ásíríà+ àti àwọn tí a óò fọ́n ká ní ilẹ̀ Íjíbítì+ yóò wá dájúdájú, wọn yóò sì tẹrí+ ba fún Jèhófà ní òkè ńlá mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé