Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 26:1-21

26  Ní ọjọ́ yẹn,+ orin yìí ni a ó kọ+ ní ilẹ̀ Júdà:+ “A ní ìlú ńlá tí ó lágbára.+ Ó mú ìgbàlà pàápàá wá fún àwọn ògiri àti ohun àfiṣe-odi.+  Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè,+ kí orílẹ̀-èdè òdodo tí ń pa ìwà ìṣòtítọ́ mọ́ lè wọlé.+  Ìtẹ̀sí tí a tì lẹ́yìn dáadáa ni ìwọ yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ nínú àlàáfíà tí ń bá a nìṣó,+ nítorí pé ìwọ ni a mú kí ẹnì kan gbẹ́kẹ̀ lé.+  Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+ ní ìgbà gbogbo, nítorí pé inú Jáà Jèhófà ni Àpáta+ àkókò tí ó lọ kánrin wà.  “Nítorí pé ó ti rẹ àwọn tí ń gbé ibi gíga sílẹ̀,+ ìlú gíga.+ Ó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀, ó rẹ̀ ẹ́ kanlẹ̀; ó mú un fara kan ekuru.+  Ẹsẹ̀ yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, ẹsẹ̀ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, ìṣísẹ̀ àwọn ẹni rírẹlẹ̀.”+  Ipa ọ̀nà olódodo jẹ́ ìdúróṣánṣán.+ Níwọ̀n bí ìwọ ti jẹ́ adúróṣánṣán, ìwọ yóò mú ipa ọ̀nà olódodo jọ̀lọ̀.+  Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí ipa ọ̀nà àwọn ìdájọ́ rẹ, Jèhófà, ni a fi ní ìrètí nínú rẹ.+ Orúkọ rẹ àti ìrántí rẹ+ ni ohun tí ọkàn ń fẹ́.+  Ọkàn mi ni mo fi ṣe àfẹ́rí rẹ ní òru;+ bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀mí mi nínú mi ni mo fi ń wá ọ ṣáá;+ nítorí pé, nígbà tí àwọn ìdájọ́ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ wá fún ilẹ̀ ayé,+ òdodo+ ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.+ 10  Bí a tilẹ̀ fi ojú rere hàn sí ẹni burúkú, kò kúkú ní kọ́ òdodo.+ Ní ilẹ̀ ìfòtítọ́-hùwà ni yóò ti máa hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu,+ kì yóò sì rí ọlá ògo Jèhófà.+ 11  Jèhófà, ọwọ́ rẹ ti di gíga,+ ṣùgbọ́n wọn kò rí i.+ Wọn yóò wò, ojú yóò sì tì wọ́n+ nítorí ìtara fún àwọn ènìyàn rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, iná+ náà fún àwọn elénìní rẹ yóò jẹ wọ́n run. 12  Jèhófà, ìwọ yóò yan àlàáfíà fún wa,+ nítorí pé gbogbo iṣẹ́ wa ni o ti ṣe fún wa.+ 13  Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, àwọn ọ̀gá mìíràn yàtọ̀ sí ìwọ ti ṣe gẹ́gẹ́ bí olúwa wa.+ Nípasẹ̀ rẹ nìkan ni a óò mẹ́nu kan orúkọ rẹ.+ 14  Òkú ni wọ́n; wọn kì yóò wà láàyè.+ Ní jíjẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú,+ wọn kì yóò dìde.+ Nítorí náà, ìwọ ti yí àfiyèsí rẹ kí o lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú, kí o sì pa gbogbo mímẹ́nukàn wọ́n run.+ 15  Ìwọ ti fi kún orílẹ̀-èdè náà; Jèhófà, ìwọ ti fi kún orílẹ̀-èdè náà;+ ìwọ ti ṣe ara rẹ lógo.+ Ìwọ ti sún gbogbo ojú ààlà ilẹ̀ náà síwájú jìnnà-jìnnà.+ 16  Jèhófà, nígbà wàhálà, wọ́n yí àfiyèsí wọn sọ́dọ̀ rẹ;+ wọ́n tú ọ̀rọ̀ àdúrà wúyẹ́wúyẹ́ jáde nígbà tí wọ́n rí ìbáwí rẹ.+ 17  Gan-an gẹ́gẹ́ bí aboyún ti ń sún mọ́ àtibímọ, tí ó ń ní ìrora ìrọbí, tí ó ń ké jáde nínú ìroragógó ìbímọ, bẹ́ẹ̀ ni àwa dà nítorí rẹ, Jèhófà.+ 18  Àwa ti lóyún, a ti ní ìrora ìrọbí;+ a ti bí ohun tí a lè pè ní ẹ̀fúùfù. A kò ṣàṣeparí ìgbàlà gidi ní ti ilẹ̀ náà,+ ìkankan nínú àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso náà kò sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá nínú ìbímọ.+ 19  “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè.+ Òkú tèmi—wọn yóò dìde.+ Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru!+ Nítorí pé ìrì+ rẹ dà bí ìrì ewéko málò,+ ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.+ 20  “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ.+ Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá.+ 21  Nítorí pé, wò ó! Jèhófà ń jáde bọ̀ láti ipò rẹ̀, láti béèrè ìjíhìn fún ìṣìnà àwọn olùgbé ilẹ̀ náà lòdì sí òun,+ dájúdájú, ilẹ̀ náà yóò sì fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹ̀+ hàn síta, kì yóò sì tún bo àwọn tirẹ̀ tí a pa mọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé