Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 24:1-23

24  Wò ó! Jèhófà sọ ilẹ̀ di òfìfo, ó sì sọ ọ́ di ahoro,+ ó sì ti lọ́ ojú rẹ̀,+ ó sì ti tú àwọn olùgbé rẹ̀ ká.+  Yóò sì wá rí bákan náà fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún àlùfáà; bákan náà fún ìránṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún ọ̀gá rẹ̀; bákan náà fún ìránṣẹ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún olúwa rẹ̀ obìnrin; bákan náà fún olùrà gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún olùtà; bákan náà fún awínni gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún ayá-nǹkan; bákan náà fún olùgba èlé gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún ẹni tí ń san èlé.+  Láìkùnà, a ó sọ ilẹ̀ náà di òfìfo, láìkùnà, a ó sì piyẹ́ rẹ̀,+ nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ ọ̀rọ̀ yìí.+  Ilẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀,+ ó ti ṣá. Ilẹ̀ eléso ti gbẹ, ó ti ṣá. Àwọn ẹni gíga lára àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ti gbẹ.+  A ti sọ ilẹ̀ náà gan-an di eléèérí lábẹ́ àwọn olùgbé rẹ̀,+ nítorí pé wọ́n ti pẹ́ òfin kọjá,+ wọ́n ti yí ìlànà padà,+ wọ́n ti ba májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin jẹ́.+  Ìdí nìyẹn tí ègún pàápàá fi jẹ ilẹ̀ náà run,+ tí a sì ka àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ sí ẹlẹ́bi. Ìdí nìyẹn tí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà fi pẹ̀dín ní iye, tí ìwọ̀nba kéréje ẹni kíkú sì fi ṣẹ́ kù.+  Wáìnì tuntun ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀, àjàrà ti rọ,+ gbogbo àwọn tí ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nínú ọkàn-àyà ti bẹ̀rẹ̀ sí mí ìmí ẹ̀dùn.+  Ayọ̀ ńláǹlà àwọn ìlù tanboríìnì ti kásẹ̀ nílẹ̀, ariwo àwọn ẹni tí ayọ̀ kún inú wọn fọ́fọ́ ti dẹ́kun, ayọ̀ ńláǹlà háàpù ti kásẹ̀ nílẹ̀.+  Wọ́n ń mu wáìnì láìsí orin; ọtí tí ń pani ti di kíkorò fún àwọn tí ń mu ún. 10  Ìlú tí a kọ̀ tì ni a ti wó lulẹ̀;+ gbogbo ilé ni a ti tì pa, kí ó má bàa ṣeé wọ̀. 11  Igbe ẹkún ń bẹ ní àwọn ojú pópó nítorí àìsí wáìnì. Gbogbo ayọ̀ yíyọ̀ ti kọjá lọ; ayọ̀ ńláǹlà ilẹ̀ náà ti lọ.+ 12  Nínú ìlú ńlá, ipò ìyàlẹ́nu ni a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn; ẹnubodè ni a ti fọ́ túútúú di òkìtì àlàpà lásán-làsàn.+ 13  Nítorí pé báyìí ni yóò dà ní àárín ilẹ̀ náà, láàárín àwọn ènìyàn, bí lílu igi ólífì,+ bí èéṣẹ́ nígbà tí kíkó èso àjàrà jọ bá ti wá sí òpin.+ 14  Àwọn alára yóò gbé ohùn wọn sókè, wọn yóò máa fi ìdùnnú ké jáde. Dájúdájú, nínú ìlọ́lájù Jèhófà ni wọn yóò ké jáde lọ́nà híhan gan-an-ran láti òkun wá.+ 15  Ìdí nìyẹn tí wọn yóò fi máa yin Jèhófà lógo+ ní ẹkùn ilẹ̀ ìmọ́lẹ̀,+ wọn yóò máa yin orúkọ Jèhófà,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lógo ní àwọn erékùṣù òkun. 16  Láti ìkángun ilẹ̀ náà, àwọn orin atunilára ń bẹ tí àwa ti gbọ́,+ pé: “Ìṣelóge fún Olódodo!”+ Ṣùgbọ́n mo wí pé: “Rírù ń bẹ fún mi,+ rírù ń bẹ fún mi! Mo gbé! Àwọn olùṣe àdàkàdekè ti ṣe àdàkàdekè.+ Àní àwọn olùṣe àdàkàdekè ti fi àdàkàdekè hùwà lọ́nà àdàkàdekè.”+ 17  Ìbẹ̀rùbojo àti ibi jíjinkòtò àti pańpẹ́ ń bẹ lórí rẹ, ìwọ olùgbé ilẹ̀ náà.+ 18  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sá fún ìró ohun tí ń kó ìbẹ̀rùbojo bá a yóò já sínú ibi jíjinkòtò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń gòkè bọ̀ láti inú ibi jíjinkòtò ni pańpẹ́ yóò mú.+ Nítorí pé, àní àwọn ibodè ibú omi ibi gíga lókè ni a óò ṣí ní ti tòótọ́,+ àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ náà yóò sì mì jìgìjìgì.+ 19  Ilẹ̀ náà ti fọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ dájúdájú, ilẹ̀ náà ni a ti gbọ̀n jìgìjìgì dájúdájú, ilẹ̀ náà ni a ti mú ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ dájúdájú.+ 20  Ilẹ̀ náà ń rìn tàgétàgé dájúdájú bí ọ̀mùtípara, ó sì ń fì síhìn-ín sọ́hùn-ún bí ahéré alóre.+ Ìrélànàkọjá rẹ̀ sì ti di wíwúwo lórí rẹ̀,+ yóò sì ṣubú, tí kì yóò tún dìde mọ́.+ 21  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ibi gíga ní ibi gíga, àti sí àwọn ọba ilẹ̀ lórí ilẹ̀.+ 22  Ṣe ni a ó fi ìkójọ bí ti àwọn ẹlẹ́wọ̀n kó wọn jọ sínú kòtò,+ a ó sì tì wọ́n pa mọ́ inú àjà ilẹ̀;+ a ó sì fún wọn ní àfiyèsí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀ yanturu.+ 23  Òṣùpá àrànmọ́jú sì ti tẹ́, ìtìjú sì ti bá oòrùn tí ń ràn yòò,+ nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti di ọba+ tògo-tògo+ ní Òkè Ńlá Síónì+ àti ní Jerúsálẹ́mù àti ní iwájú àwọn àgbàlagbà ọkùnrin rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé