Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 23:1-18

23  Ọ̀rọ̀ ìkéde nípa Tírè:+ Ẹ hu, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì!+ nítorí a ti fi í ṣe ìjẹ kúrò nínú jíjẹ́ èbúté ọkọ̀, kúrò nínú jíjẹ́ ibi wíwọ̀.+ Láti ilẹ̀ Kítímù+ ni a ti ṣí i payá fún wọn.  Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ etí òkun. Àwọn olówò láti Sídónì,+ àwọn tí ń sọdá òkun—wọ́n ti kún inú rẹ.  Orí omi púpọ̀ sì ni irúgbìn Ṣíhórì+ wà, ìkórè Náílì, owó àpawọlé rẹ̀; ó sì wá jẹ́ èrè àwọn orílẹ̀-èdè.+  Kí ojú tì ọ́, ìwọ Sídónì;+ nítorí pé òkun, ìwọ ibi odi agbára òkun, ti sọ pé: “Èmi kò ní ìrora ìbímọ rí, èmi kò sì bímọ rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin rí, èmi kò sì tọ́jú àwọn wúńdíá dàgbà.”+  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó jẹ mọ́ Íjíbítì,+ bákan náà ni àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora mímúná nítorí ìròyìn nípa Tírè.+  Ẹ sọdá sí Táṣíṣì; ẹ hu, ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ etí òkun.  Ṣé èyí ni ìlú ńlá yín tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà láti àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, láti àwọn àkókò ìjímìjí rẹ̀? Tẹ́lẹ̀ rí, ẹsẹ̀ rẹ̀ máa ń gbé e lọ sí ibi jíjìnnàréré láti ṣe àtìpó.  Ta ni ó ti ṣe ìpinnu yìí+ lòdì sí Tírè, tí í ṣe adéniláde, tí àwọn olówò rẹ̀ jẹ́ ọmọ aládé, tí àwọn oníṣòwò rẹ̀ jẹ́ ọlọ́lá ilẹ̀ ayé?+  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tìkára rẹ̀ ti ṣe ìpinnu yìí,+ láti sọ ìyangàn gbogbo ẹwà di aláìmọ́,+ láti fojú tín-ín-rín gbogbo ọlọ́lá ilẹ̀ ayé.+ 10  Sọdá ilẹ̀ rẹ bí Odò Náílì, ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì.+ Kò tún sí ọgbà tí a ti ń kan ọkọ̀ òkun mọ́.+ 11  Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun; ó ti kó ṣìbáṣìbo bá àwọn ìjọba.+ Jèhófà tìkára rẹ̀ ti pa àṣẹ lòdì sí Foníṣíà, láti pa àwọn ibi odi agbára rẹ̀ rẹ́ ráúráú.+ 12  Ó sì wí pé: “Má yọ ayọ̀ ńláǹlà mọ́ láé,+ ìwọ ẹni tí a ni lára, wúńdíá ọmọbìnrin Sídónì.+ Dìde, sọdá sí Kítímù+ alára. Níbẹ̀ pàápàá, ìwọ kì yóò rí ìsinmi.” 13  Wò ó! Ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.+ Èyí ni àwọn ènìyàn náà—kì í ṣe Ásíríà+ ni ẹni náà—wọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ fún àwọn olùgbé aṣálẹ̀.+ Wọ́n ti gbé àwọn ilé gogoro wọn ti ìsàgatì nà ró;+ wọ́n ti tú àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ sí borokoto;+ ẹnì kan ti ṣe é ní ìrúnwómúwómú.+ 14  Ẹ hu, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì, nítorí pé a ti fi ibi odi agbára yín ṣe ìjẹ.+ 15  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Tírè ni a ó gbàgbé fún àádọ́rin ọdún,+ lọ́nà kan náà bí àwọn ọjọ́ ọba kan. Ní òpin àádọ́rin ọdún, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin kárùwà kan ti wí pé: 16  “Mú háàpù, lọ yí ká ìlú ńlá, ìwọ kárùwà tí a ti gbàgbé.+ Sa gbogbo ipá rẹ ní títa àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín; sọ orin rẹ di púpọ̀, kí a lè rántí rẹ.” 17  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní òpin àádọ́rin ọdún náà pé Jèhófà yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí Tírè, yóò sì padà sídìí ọ̀yà rẹ̀,+ yóò sì máa bá gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí ó wà ní ojú ilẹ̀ ṣe kárùwà.+ 18  Èrè rẹ̀ àti ọ̀yà rẹ̀+ yóò sì di ohun mímọ́ lójú Jèhófà. A kì yóò tò ó jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò tọ́jú rẹ̀ pa mọ́, nítorí pé ọ̀yà rẹ̀ yóò wá jẹ́ ti àwọn tí ń gbé níwájú Jèhófà,+ fún jíjẹ àjẹyó àti fún ìbora agbógoyọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé