Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 21:1-17

21  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí aginjù òkun:+ Bí àwọn ẹ̀fúùfù oníjì+ ní gúúsù ti ń lọ síwájú, láti aginjù ni ó ti ń bọ̀, láti ilẹ̀ tí ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù.+  Ìran líle+ kan wà tí a ti sọ fún mi: Olùṣe àdàkàdekè ń ṣe àdàkàdekè, afiniṣèjẹ sì ń fini ṣe ìjẹ.+ Gòkè lọ, ìwọ Élámù! Sàga tì, ìwọ Mídíà!+ Gbogbo ìmí ẹ̀dùn nítorí rẹ̀ ni mo ti mú kí ó kásẹ̀ nílẹ̀.+  Ìdí nìyẹn tí ìgbáròkó mi fi kún fún ìrora mímúná.+ Àní ìsúnkì iṣan ti mú mi, bí ìsúnkì iṣan obìnrin tí ó fẹ́ bímọ.+ Mo ti di aláìbalẹ̀ ara tí n kò fi gbọ́ràn; ìyọlẹ́nu ti bá mi tí n kò fi ríran.  Ọkàn-àyà mi ti rìn gbéregbère; àní ìgbọ̀njìnnìjìnnì ti kó ìpayà bá mi. Wíríwírí ọjọ́ tí ara mi fà mọ́ ni a ti sọ di ìwárìrì fún mi.+  Kí títẹ́ tábìlì, ṣíṣètò àyè ìjókòó, jíjẹ, mímu ṣẹlẹ̀!+ Ẹ dìde, ẹ̀yin ọmọ aládé,+ ẹ fòróró yan apata.+  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: “Lọ, yan alóre sẹ́nu iṣẹ́, kí ó lè sọ ohun tí òun ń rí.”+  Ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun tí ó ní àdìpọ̀ méjì-méjì ẹṣin ogun, kẹ̀kẹ́ ogun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kẹ̀kẹ́ ogun ràkúnmí. Ó sì fiyè sílẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú ìfiyèsílẹ̀ púpọ̀.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké bí kìnnìún+ pé: “Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán, ibi ìṣọ́ mi sì ni mo dúró sí ní gbogbo òru.+  Kíyè sí i, kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun ti àwọn ọkùnrin rèé tí ń bọ̀, pẹ̀lú àdìpọ̀ méjì-méjì ẹṣin ogun!”+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sókè, ó sì wí pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú,+ gbogbo ère fífín ti àwọn ọlọ́run rẹ̀ ni òun ti wó mọ́lẹ̀!”+ 10  Ẹ̀yin ènìyàn mi tí a ti pa bí ọkà àti ọmọ ilẹ̀ ìpakà mi,+ ohun tí mo gbọ́ láti ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ni mo ti ròyìn fún yín. 11  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Dúmà: Ẹnì kan ń ké jáde sí mi láti Séírì+ wá pé: “Olùṣọ́, òru ti rí? Olùṣọ́, òru ti rí?”+ 12  Olùṣọ́ wí pé: “Òwúrọ̀ ní láti dé, àti òru pẹ̀lú. Bí ẹ bá fẹ́ wádìí, ẹ wádìí. Ẹ tún padà wá!” 13  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀: Inú igbó ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ni ẹ ó sùn mọ́jú, ẹ̀yin ọ̀wọ́ èrò Dédánì.+ 14  Ẹ gbé omi wá pàdé ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ. Ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ Témà,+ ẹ fi oúnjẹ tí ẹni tí ń sá lọ yóò jẹ pàdé rẹ̀. 15  Nítorí pé idà ni ó mú kí wọ́n sá lọ, nítorí idà tí a fà yọ, àti nítorí ọrun tí a fà àti nítorí kíkira ogun náà. 16  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: “Láàárín ọdún kan sí i, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọdún lébìrà tí a háyà,+ àní gbogbo ògo Kídárì+ yóò wá sí òpin rẹ̀. 17  Àwọn tí ó sì ṣẹ́ kù lára iye àwọn tí ń lo ọrun, àwọn ọkùnrin alágbára ńlá nínú àwọn ọmọ Kídárì, yóò di èyí tí ó kéré níye,+ nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ni ó sọ ọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé