Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 2:1-22

2  Ohun tí Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì rí ní ìran nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù:+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́+ pé òkè ńlá ilé+ Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá,+ dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké;+ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀.+  Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: “Ẹ wá,+ ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.”+ Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde lọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù.+  Dájúdájú, òun yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́+ ní ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.+ Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.+ Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+  Ẹ̀yin ará ilé Jékọ́bù, ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.+  Nítorí ìwọ ti ṣá àwọn ènìyàn rẹ, ilé Jékọ́bù+ tì. Nítorí wọ́n ti kún fún ohun tí ó ti Ìlà-Oòrùn wá,+ wọ́n sì jẹ́ pidánpidán+ bí àwọn Filísínì, àwọn ọmọ ará ilẹ̀ òkèèrè sì pọ̀ gidigidi nínú wọn.+  Ilẹ̀ wọn sì kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì lópin.+ Ilẹ̀ wọn sì kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn kò sì lópin.+  Ilẹ̀ wọn sì kún fún àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí.+ Iṣẹ́ ọwọ́ ara ẹni sì ni wọ́n ń tẹrí ba fún, èyí tí ìka ara ẹni ṣe.+  Ará ayé sì tẹrí ba, ènìyàn sì di rírẹ̀sílẹ̀, ìwọ kò sì lè dárí jì wọ́n rárá.+ 10  Wọ inú àpáta, kí o sì fi ara rẹ pa mọ́ sínú ekuru nítorí ìbẹ̀rùbojo fún Jèhófà, àti kúrò lójú ìlọ́lájù rẹ̀ gígọntíọ.+ 11  Ojú ìrera ará ayé yóò di rírẹ̀sílẹ̀, ìgafíofío àwọn ènìyàn yóò sì tẹrí ba;+ Jèhófà nìkan ṣoṣo sì ni a óò gbé ga ní ọjọ́ yẹn.+ 12  Nítorí ọjọ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni.+ Ó ń bẹ lórí olúkúlùkù ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga àti ẹni gíga fíofío àti lórí olúkúlùkù ẹni tí a gbé ga tàbí tí a rẹ̀ sílẹ̀;+ 13  àti lórí gbogbo kédárì ti Lẹ́bánónì+ tí ó ga fíofío, tí a sì gbé ga àti lórí gbogbo igi ràgàjì Báṣánì;+ 14  àti lórí gbogbo òkè ńlá gíga fíofío àti lórí gbogbo òkè kéékèèké tí a gbé ga;+ 15  àti lórí gbogbo ilé gogoro tí ó ga àti lórí gbogbo ògiri olódi;+ 16  àti lórí gbogbo ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ àti lórí gbogbo ọkọ̀ ojú omi fífani-lọ́kàn-mọ́ra. 17  Ìrera ará ayé yóò sì tẹrí ba, ìgafíofío àwọn ènìyàn yóò sì di rírẹ̀sílẹ̀;+ Jèhófà nìkan ṣoṣo sì ni a óò gbé ga ní ọjọ́ yẹn.+ 18  Àní àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí yóò kọjá lọ pátápátá.+ 19  Àwọn ènìyàn yóò sì wọ inú hòrò àpáta àti inú ihò ekuru nítorí ìbẹ̀rùbojo fún Jèhófà àti kúrò nínú ìlọ́lájù rẹ̀ gígọntíọ,+ nígbà tí ó bá dìde kí ilẹ̀ ayé lè gbọ̀n rìrì.+ 20  Ní ọjọ́ yẹn, ará ayé yóò ju àwọn ọlọ́run fàdákà tí kò ní láárí àti àwọn ọlọ́run wúrà tí kò ní láárí tí wọ́n ṣe, kí ó lè máa tẹrí ba níwájú rẹ̀, sí asín àti sí àdán,+ 21  kí ó lè wọ inú ihò àwọn àpáta àti pàlàpálá àwọn àpáta gàǹgà, nítorí ìbẹ̀rùbojo fún Jèhófà àti kúrò nínú ìlọ́lájù rẹ̀ gígọntíọ,+ nígbà tí ó bá dìde kí ilẹ̀ ayé lè gbọ̀n rìrì. 22  Fún ire ara yín, ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ará ayé, ẹni tí èémí rẹ̀ wà ní ihò imú rẹ̀,+ nítorí ìdí wo ni a ó fi ka òun fúnra rẹ̀ sí?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé