Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Aísáyà 19:1-25

19  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Íjíbítì:+ Wò ó! Jèhófà gun àwọsánmà yíyára,+ ó sì ń bọ̀ wá sí Íjíbítì. Ó dájú pé àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí ti Íjíbítì yóò gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nítorí rẹ̀,+ ọkàn-àyà Íjíbítì gan-an yóò sì domi ní àárín rẹ̀.+  “Ṣe ni èmi yóò gún àwọn ọmọ Íjíbítì ní kẹ́sẹ́ lòdì sí àwọn ọmọ Íjíbítì, olúkúlùkù wọn yóò sì bá arákùnrin rẹ̀ jagun dájúdájú, olúkúlùkù yóò sì bá alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ jagun, ìlú ńlá lòdì sí ìlú ńlá, ìjọba lòdì sí ìjọba.+  Ìdàrúdàpọ̀ yóò sì dé bá ẹ̀mí Íjíbítì ní àárín rẹ̀,+ èmi yóò sì da ìmọ̀ràn rẹ̀ rú.+ Ó sì dájú pé wọn yóò yíjú sí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí+ àti sí àwọn atujú àti sí àwọn abẹ́mìílò àti sí àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀.+  Ṣe ni èmi yóò fa Íjíbítì lé ọ̀gá líle lọ́wọ́, alágbára sì ni ọba tí yóò ṣàkóso lé wọn lórí,”+ ni àsọjáde Olúwa tòótọ́, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.  Dájúdájú, omi yóò sì gbẹ nínú òkun, odò pàápàá yóò sì di ìyàngbẹ, yóò sì gbẹ pátápátá.+  Àwọn odò yóò sì máa ṣíyàn-án; àwọn ipa odò Náílì ti Íjíbítì yóò sì lọ sílẹ̀, yóò sì di ìyàngbẹ.+ Esùsú+ àti koríko etídò pàápàá yóò sì rà dànù.  Àwọn ibi dídán borokoto lẹ́bàá Odò Náílì, ní ẹnu Odò Náílì, àti gbogbo ilẹ̀ irúgbìn Odò Náílì yóò gbẹ táútáú.+ Dájúdájú, a óò gbá a lọ, kì yóò sì sí mọ́.  Àwọn apẹja yóò sì ní láti ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí ń ju ìwọ̀ ẹja sínú Odò Náílì yóò sì kárí sọ, okun àwọn tí ń na àwọ̀n ìpẹja sí ojú omi pàápàá yóò tán ní ti tòótọ́.+  Ojú yóò sì ti àwọn oníṣẹ́ ọ̀gbọ̀ gbígbọ̀n;+ àti àwọn olófì tí ń hun aṣọ funfun pẹ̀lú. 10  Àwọn ahunṣọ+ rẹ̀ ni a ó sì tẹ̀ rẹ́, gbogbo òṣìṣẹ́ agbowó ọ̀yà ni a óò mú kẹ́dùn nínú ọkàn. 11  Àwọn ọmọ aládé Sóánì+ ya òmùgọ̀ ní tòótọ́. Ní ti àwọn ọlọ́gbọ́n lára àwọn agbani-nímọ̀ràn Fáráò, ìmọ̀ràn wọ́n jẹ́ ohun tí kò lọ́gbọ́n nínú.+ Báwo ni ẹ ṣe lè sọ fún Fáráò pé: “Ọmọ àwọn ọlọ́gbọ́n ni mí, ọmọ àwọn ọba ìgbàanì”? 12  Àwọn wá dà—àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ+—kí wọ́n sọ fún ọ wàyí, kí wọ́n sì mọ ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti pinnu nípa Íjíbítì?+ 13  Àwọn ọmọ aládé Sóánì ti hùwà òmùgọ̀,+ a ti tan àwọn ọmọ aládé Nófì+ jẹ, àwọn gíríkì ọkùnrin+ inú ẹ̀yà rẹ̀ ti mú kí Íjíbítì rìn gbéregbère. 14  Jèhófà tìkára rẹ̀ ti mú ẹ̀mí àìbalẹ̀ ara wọ àárín rẹ̀;+ wọ́n sì ti mú kí Íjíbítì rìn gbéregbère nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti mú kí ẹni tí ó ti mutí para rìn gbéregbère nínú èébì rẹ̀.+ 15  Íjíbítì kì yóò sì wá ní iṣẹ́ kankan tí orí tàbí ìrù, tí ọ̀mùnú tàbí koríko etídò, lè ṣe.+ 16  Ní ọjọ́ yẹn, Íjíbítì yóò dà bí obìnrin, dájúdájú, yóò wárìrì,+ ìbẹ̀rùbojo yóò sì bá a nítorí fífì ọwọ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, èyí tí òun ń fì lòdì sí i.+ 17  Ilẹ̀ Júdà yóò sì di okùnfà fún títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́ fún Íjíbítì.+ Gbogbo ẹni tí ènìyàn bá mẹ́nu kàn án fún ni ìbẹ̀rùbojo yóò mú nítorí ìpinnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, èyí tí ó ti pinnu lòdì sí i.+ 18  Ní ọjọ́ yẹn, ìlú ńlá márùn-ún ni yóò wà ní ilẹ̀ Íjíbítì+ tí ń sọ èdè Kénáánì,+ tí ó sì ń búra+ fún Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ìlú Ńlá Ìyalulẹ̀ ni a óò máa pe ìlú ńlá kan. 19  Ní ọjọ́ yẹn, pẹpẹ kan yóò wà fún Jèhófà ní àárín ilẹ̀ Íjíbítì,+ àti ọwọ̀n kan fún Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà rẹ̀. 20  Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní ilẹ̀ Íjíbítì;+ nítorí pé wọn yóò ké jáde sí Jèhófà nítorí àwọn aninilára,+ òun yóò sì rán olùgbàlà kan sí wọn, àní ẹni títóbilọ́lá, ẹni tí yóò dá wọn nídè ní tòótọ́.+ 21  Dájúdájú, Jèhófà yóò sì di mímọ̀ fún àwọn ọmọ Íjíbítì;+ àwọn ọmọ Íjíbítì yóò sì mọ Jèhófà ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò sì rú ẹbọ, wọn yóò sì mú ẹ̀bùn+ wá, wọn yóò sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà, wọn yóò sì san án.+ 22  Ṣe ni Jèhófà yóò sì fi ìyọnu àgbálù kọlu Íjíbítì.+ Fífi ìyọnu àgbálù kọlù àti ìmúniláradá yóò sì ṣẹlẹ̀;+ wọn yóò sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà,+ òun yóò sì jẹ́ kí wọ́n pàrọwà sí òun, yóò sì mú wọn lára dá.+ 23  Ní ọjọ́ yẹn, òpópó+ kan yóò wá wà láti inú Íjíbítì sí Ásíríà, Ásíríà yóò sì wá sí Íjíbítì ní tòótọ́, àti Íjíbítì sí Ásíríà; dájúdájú, wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, Íjíbítì pẹ̀lú Ásíríà. 24  Ní ọjọ́ yẹn, Ísírẹ́lì yóò wá jẹ́ ìkẹta pẹ̀lú Íjíbítì àti Ásíríà,+ èyíinì ni, ìbùkún ní àárín ilẹ̀ ayé,+ 25  nítorí pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ti bù kún un,+ pé: “Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn mi, Íjíbítì, àti iṣẹ́ ọwọ́ mi, Ásíríà,+ àti ogún mi, Ísírẹ́lì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé