Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 17:1-14

17  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Damásíkù:+ “Wò ó! A mú Damásíkù kúrò kí ó má ṣe jẹ́ ìlú ńlá mọ́, ó sì ti di òkìtì, àwókù tí ń dómùkẹ̀.+  Àwọn ìlú ńlá Áróérì+ tí a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn ti di àyè fún àwọn agbo ẹran ọ̀sìn, ibi tí wọ́n ń dùbúlẹ̀ sí ní tòótọ́, láìsí ẹnikẹ́ni tí ń mú wọn wárìrì.+  A ti mú kí ìlú ńlá olódi kásẹ̀ nílẹ̀ ní Éfúráímù,+ a sì ti mú kí ìjọba kásẹ̀ nílẹ̀ ní Damásíkù;+ àwọn tí ó sì ṣẹ́ kù lára Síríà yóò dà bí ògo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,” ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé ògo Jékọ́bù yóò di rírẹ̀sílẹ̀,+ ìsanra rẹ̀ pàápàá ni a ó sọ di rírù.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí olùkórè bá ń kó ọkà tí ó wà ní ìdúró jọ, tí apá rẹ̀ sì ń kórè ṣírí ọkà,+ àní yóò dà bí ẹni tí ń pèéṣẹ́ ṣírí ọkà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Réfáímù.+  Èéṣẹ́ yóò sì ṣẹ́ kù sínú rẹ̀ bí ìgbà tí a bá ń lu igi ólífì: ólífì méjì tàbí mẹ́ta tí ó pọ́n ní orí ẹ̀ka; mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí àwọn ẹ̀tun rẹ̀ tí ń so èso,” ni àsọjáde Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+  Ní ọjọ́ yẹn, ará ayé yóò gbé ojú sókè sí Olùṣẹ̀dá rẹ̀, ojú rẹ̀ yóò sì tẹ̀ mọ́ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì pàápàá.+  Kì yóò sì wo àwọn pẹpẹ,+ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+ kì yóò sì tẹjú mọ́ ohun tí ìka rẹ̀ ṣe, yálà àwọn òpó ọlọ́wọ̀ tàbí àwọn pẹpẹ tùràrí.+  Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ìlú ńlá odi agbára rẹ̀ yóò dà bí ibi tí a fi sílẹ̀ pátápátá nínú igbó tí ó kún fún igi, àní ẹ̀ka tí wọ́n ti fi sílẹ̀ pátápátá ní tìtorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; yóò sì di ahoro.+ 10  Nítorí ìwọ ti gbàgbé+ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;+ Àpáta+ odi agbára rẹ ni ìwọ kò sì rántí. Ìdí nìyẹn tí o fi gbin àwọn oko ọ̀gbìn tí ó wuni, o sì fi ọ̀mùnú àjèjì gbìn ín. 11  Ní ọ̀sán, ìwọ lè rọra ṣe ọgbà yí oko ọ̀gbìn rẹ ká, ní òwúrọ̀, ìwọ sì lè mú kí irúgbìn rẹ rú jáde, ṣùgbọ́n ìkórè yóò sá lọ ní ọjọ́ òkùnrùn àti ìrora tí kò ṣeé wòsàn.+ 12  Háà, nítorí arukutu ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn tí ó jẹ́ aláriwo líle gẹ́gẹ́ bí ariwo líle òkun! Àti nítorí ariwo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, àwọn tí ń pa ariwo adún-lọ-rére gẹ́gẹ́ bí ariwo omi púpọ̀ jọjọ!+ 13  Àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè+ pàápàá yóò pa ariwo adún-lọ-rére gẹ́gẹ́ bí ariwo omi púpọ̀. Dájúdájú, Òun yóò bá a wí lọ́nà mímúná,+ yóò sì sá lọ sí ibi jíjìnnàréré, a ó sì lé e gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò àwọn òkè ńlá níwájú ẹ̀fúùfù àti gẹ́gẹ́ bí òṣùṣú tí ààjà ń gbé kiri níwájú ẹ̀fúùfù oníjì.+ 14  Ní àkókò ìrọ̀lẹ́, họ́wù, wò ó! ìpayà òjijì ń bẹ. Kí ó tó di òwúrọ̀—kò sí mọ́.+ Èyí ni ìpín àwọn tí ń kó wa ní ìkógun, àti ipa tí ó jẹ́ ti àwọn tí ń piyẹ́ wa.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé