Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Aísáyà 15:1-9

15  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Móábù:+ Nítorí òru ni a fi í ṣe ìjẹ, Árì+ ti Móábù pàápàá ni a ti pa lẹ́nu mọ́. Nítorí òru ni a fi í ṣe ìjẹ, Kírì+ ti Móábù pàápàá ni a ti pa lẹ́nu mọ́.  Ó ti gòkè lọ sí Ilé Náà àti sí Díbónì,+ sí àwọn ibi gíga, fún ẹkún sísun. Móábù alára ń hu lórí Nébò+ àti lórí Médébà.+ Gbogbo orí tí ó wà nínú rẹ̀ pá;+ gbogbo irùngbọ̀n ni a gé mọ́lẹ̀.  Ní àwọn ojú pópó rẹ̀, wọ́n sán aṣọ àpò ìdọ̀họ.+ Lórí òrùlé+ rẹ̀ àti ní àwọn ojúde ìlú rẹ̀, gbogbo wọn ń hu, wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú ẹkún sísun.+  Hẹ́ṣíbónì àti Éléálè+ sì ké jáde. Títí dé Jáhásì+ ni a gbọ́ ohùn wọn. Ìdí nìyẹn tí àwọn ọkùnrin Móábù tí ó dìhámọ́ra fi ń kígbe. Àní ọkàn rẹ̀ ti gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nínú rẹ̀.  Ọkàn-àyà mi ké jáde lórí Móábù alára.+ Àwọn olùfẹsẹ̀fẹ kúrò nínú rẹ̀ ti lọ jìnnà dé Sóárì+ àti Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà.+ Nítorí pé ní ìgòkè Lúhítì+—pẹ̀lú ẹkún sísun ni olúkúlùkù fi ń gòkè lọ sórí rẹ̀; nítorí pé lójú ọ̀nà tí ó lọ sí Hórónáímù+ ni wọ́n ti gbé igbe ẹkún dìde nípa àjálù ibi náà.  Nítorí pé omi Nímúrímù+ gan-an ti di ahoro pátápátá. Nítorí pé koríko tútù ti gbẹ dànù, koríko ti wá sí òpin; nǹkan kan kò di tútù yọ̀yọ̀.+  Ìdí nìyẹn tí àwọn àṣẹ́kùsílẹ̀ àti àwọn ẹrù wọn tí wọ́n ti tò jọ pa mọ́, wọ́n ń kó wọn lọ tààrà gba àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní àwọn igi pọ́pílà.  Nítorí pé igbe ẹkún ti lọ yí ká ìpínlẹ̀ Móábù.+ Híhu láti inú rẹ̀ lọ títí dé Égíláímù; híhu láti inú rẹ̀ lọ títí dé Bia-élímù,  nítorí pé omi Dímónì gan-an ti kún fún ẹ̀jẹ̀. Nítorí pé èmi yóò gbé àwọn nǹkan púpọ̀ sí i lé Dímónì, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún fún àwọn olùsálà Móábù tí ó sálà àti fún àwọn tí ó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé